Kò sí olóṣèlú tó máa sọ pé òun kò yí ìwé ẹ̀rí – Amaechi

Minisita fọrọ eto irinna tẹlẹri lorileede yii, Rotimi Amaechi ti sọ pe ko si oloṣelu kankan ni Naijiria to maa sọ pe oun ko ṣe ayederu iwe ẹri ri.

Amaechi sọrọ naa nibi idanilẹkọọ ọlọdọọdun ''TheNiche'' ti wọn pe akori rẹ ni “Why We Stride and Slip: Leadership, Nationalism, and the Nigerian Condition,” to waye niluu Ekoo lỌjọbọ.

Nibẹ ni Amaechi ti ṣalaye wi pe oun ko ṣetan lati bu ẹnu atẹ lu ijọba Muhammadu Buhari toun ba ṣiṣẹ papọ, ati ijọba Bọla Tinubu to n lọ lọwọ yii.

O ni latigba ti oṣelu ti bẹrẹ titi di asiko yii, ko si oloṣelu kankan to le fi ọwọ sọya wi pe oun ko yi iwe ẹri oun, tabi ṣe magomago ninu awọn iwe ẹri to fi gbe apoti.

Ẹ darukọ oloṣelu kan ṣoṣo to ti sọ fun un yin ri wi pe oun kii ṣe ole

Amaechi sọ pe awọn ọmọ Naijiria mọ otitọ nipa awọn oloṣelu, ṣugbọn ti wọn ko ri nnkan ṣe sii, to si jẹ pe awọn naa ni wọn n dibo yan awọn oloṣelu ti wọn mọ pe iwa ọwọ wọn ko mọ.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Bi awọn ọmọ Naijiria kan ba n sọ fun un yin pe ko yẹ ki ẹ fun mi ni anfaani lati sọrọ, ẹ sọ fun wọn pe ọpọ ileeṣẹ tẹlifiṣan ati awọn ileeṣẹ iwe iroyin ni wọn n pe mi ki n wa sọrọ lori oriṣiriṣi ohun to n ṣẹlẹ latigba ti mo ti kuro n’ijọba, ṣugbọn ti mi o da wọn lohun.''

“Idi pataki meji ti mi o fi dahun ni pe awọn ileri mi n fọhun fun mi, idi keji ni pe awọn ọmọ Naijiria kii sọrọ lori ohun to ba n ṣẹlẹ.

O ni “Njẹ oloṣelu kankan ti sọ fun un yin pe oun kii ṣe ole?

“Emi ko mọ idi ti awọn eeyan fi n pariwo wi pe wọn yi iwe, wọn ko yi iwe. Oloṣelu wo lo sọ fun un yin ri wi pe oun lọ si fasiti? Oloṣelu wo lo sọ pe oun ni iwe ẹri agunbanirọ?

“Oloṣelu wo lo sọ pe oun ni iwe ẹri? Awọn ọmọ Naijiria mọ nnkan to n ṣẹlẹ, sibẹ wọn ṣi tun n dibo fun wọn, ki wa ni iṣoro yin?

“Mo sọ fun wọn pe ki ni iṣoro wọn, ti wọn fi fẹ ki n sọrọ lori ẹ, nitori pe kii ṣe nnkan tuntun mọ.

“Ẹ ri nnkan to ṣẹlẹ lasiko Buhari. Maa fi Port Harcourt silẹ lọ si Abuja ni aago kan oru, maa de Abuja ni aago mẹta oru, awọn nnkan sọrọ nipa Buhari.

“Njẹ ẹ gbọ ki n sọ ohunkohun? Mi o sọ nnkankan nitori pe ko ṣe pataki.

Asiko aini ireti la wa yii.

“Awọn ọmọ Naijiria ni wọn n dibo yan awọn ti wọn ba fẹẹ gbagbọ, awọn ti wọn ba fẹẹ dibo fun.

“Koda bi ẹ ba lọ sile eeyan, ti ẹ pa iya ẹ, baba yoo ṣi tun maa gbe igbesi aye rẹ lọ.

“Ko si nnkan to n jẹ yin lọkan, ki wa ni idi ti mo ṣe maa maa fi asiko mi ṣofo lori nnkan ti ẹ ko le ṣe ohunkohun si...

“Fun idi eyi, mo pinnu lati ma ṣe sọ ohunkohun nitori pe awọn ọmọ Naijiria ko le ṣe nnkankan si, bi mo ba sọrọ. Ẹ jẹ ki wọn pa awọn ọmọ Naijiria mẹwaa lonii, ẹ maa rii pe ko si nnkan to maa ṣẹlẹ sii.

“Eyi to tiẹ tun wa bajẹ ju nipa Naijiria ni pe bi ẹ ba n duro lori ẹtọ yin wi pe ẹ ko daran, ti wọn si gbe e yin, awọn eeyan a bẹrẹ sii sọ pe awọn ti sọ bẹẹ tẹlẹ wi pe ole ni.

“Awọn ọmọ Naijiria lo maa da si, ti wọn fi maa ran onitọhun lọ sẹwọn lori ẹsun ti ko mọ nnkan nipa ẹ.

“Ohun kan ṣoṣo to n ba mi lẹru julọ ni ki wọn ri mi lẹwọn lori ẹsun ti mi o mọ nipa ẹ.

O fi kun ọrọ rẹ pe ''Mi o nii sọrọ lori ijọba Buhari fun idi pataki meji, bẹẹ si ni mi o ni sọrọ lori ijọba Tinubu.

“Idi ni pe mo pẹlu ijọba Buhari, koda wọn ṣi beere ibeere naa lọwọ mi wi pe ki ni awọn amuyẹ ti mo ni lati bu ẹnu atẹ lu ijọba Buhari pẹlu pe mo wa ninu ijọba naa.

“Mo maa n sọ fun wọn pe mi o ni sọrọ nipa ijọba Buhari, idi naa si ree ti mi o fi sọrọ lori ijọba Tinubu, nitori pe mo mọ ibi ti iṣoro naa wa.

“Kaka ki awọn ọmọ Naijiria maa wa ibi ti iṣoro wọn wa, niṣe ni wọn n gba ẹmi ara wọn. Maa si maa gbadura lojoojumọ wi pe ki ẹ maa tẹsiwaju lati gba ẹmi ara yin.

“Idi ni pe nigba ti mo ba fi maa ji lọjọ kan, gbogbo yin a ti ku tan, maa wa le ni anfaani iku yin lati loogun.

“Ohun ti awọn eeyan nkọ gẹgẹ bo ṣe n ṣẹlẹ ni Ghana, Kenya ati awọn orileede miran ni awọn ọmọ Naijiria maa n fi ọwọ yọbọkẹ mu wi pe ṣe bi ọdun mẹrin pere ni.

“Sibẹsibẹ, ẹni ti wọn n sọ yii yoo tun wọle ibo ẹlẹẹkeji, boya nipa idan tabi ọna miran. Ṣe bi Jonathan ti lọ, Buhari naa ti lọ, ohun naa yoo to lọ.

“Ẹlo miran ṣi n bọ to maa tun ṣe nnkan ti ẹ ko fẹ. Nnkan ti ẹ si ma maa tẹnumọ niyẹn titi Ọlọrun yoo fi de, iyẹn fun awa ti a jẹ Kristẹni.

“Emi naa ti darapọ mọ yin nipa wi pe ki n ma sọrọ, ki n ma ṣe gbọ ohunkohun, ki n si ma ṣe ohunkohun.”