Ṣé lóòótọ́ ni ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fún ọkùnrin kan fẹ́sùn pé ó ra jẹnẹrétọ̀ tí wọ́n jí gbé? Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun ṣàlàyé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Agbẹjọ́rò àgbà ní ìpínlẹ̀ Ogun tó tún jẹ́ Kọmíṣánnà fétò ìdájọ́, Oluwasina Ogungbade ti sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn kan tó gbóde nípa ọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Abia, Ogbonna Ogbojionu tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ìtúsílẹ̀ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn ọdún méjìlélógún.

Ogungbade sọ pé ohun tó gbé Ogbonna dẹ́wọ̀n ni ìdigunjalè kìí ṣe pé nítorí pé ó ra ẹ̀rọ amúnáwá jẹnẹrétọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìròyìn ṣe ń gbé lórí ayélujára.

Ṣáájú ni ìròyìn Ogbonna gbá orí ayélujára lẹ́yìn tó rí ìtúsílẹ̀ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn ọdún méjìlélógún pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Abia, Alex Otti.

Ohun táwọn èèyàn ń sọ lórí ayélujára ni pé ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun rán Ogbonna lẹ́wọ̀n nítorí ẹ̀sùn pé ó ra ẹ̀rọ jẹnẹrétọ̀ tí wọ́n jí gbé.

Èyí ti mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn máa bu ẹnu àtẹ́ lu ètò ìdájọ́ Nàìjíríà wí pé wọ́n máa ń fi ẹ̀tẹ̀ sílẹ̀ láti rán làpálàpá.

Ogbonna nínú àtẹ̀jáde orí ayélujára kan sọ pé nígbà tí wọ́n mú òun lọ́dún 1999, wọ́n fi tipátipá mú òun láti kọ àkọ́ọ́lẹ̀ tí kò yé òun, tí wọ́n sì dájọ́ ikú fún òun.

'Ogbonna wà lára àwọn adigunjalè tó ṣekúpa ẹ̀ṣọ́ ààbò níbi tí wọ́n ti lọ jí ẹ̀rọ jẹnẹrétọ̀'

Ẹ̀wẹ̀, Ogungbade nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́rú sọ pé irọ́ tí jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn tó gba orí ayélujára náà àti pé Ogbonna wà lára àwọn adigunjalè tó ṣekúpa ẹ̀ṣọ́ ààbò níbi tí wọ́n ti lọ jí ẹ̀rọ jẹnẹrétọ̀ lọ́jọ́ Kẹta, ọdún 2000.

Ó ní ètò ìdájọ́ tó yẹ ló wáyé lórí ọ̀rọ̀ Ogbonna nítorí ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ló jẹ.

Nígbà tó ń ṣẹlẹ̀ bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé, Ogungbade ní nǹkan bíi aago mẹ́wàá alẹ́ lọ́jọ́ Kẹta, oṣù Kẹwàá ọdún 2000 ni àwọn adigunjalè kan lọ ṣọṣẹ́ ní ilé epo ELF tó wà ní òpópónà Abeokuta sí Eko tí wọ́n sì jí ẹ̀rọ jẹnẹrétọ̀ 10 KVA Lister gbé.

Ó ṣàlàyé pé àwọn adigunjalè náà bá ẹ̀ṣọ́ ààbò ní ilé epo náà tí wọ́n sì so wọ́n mọ́lẹ̀.

"Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ náà ni Yusuf Akanni, àwọn adigunjalè náà la irin mọ lórí, ọwọ́ àti ẹsẹ̀ èyí tó ṣokùnfà bí egungun itan rẹ̀ ṣe kán.

"Orí ni wọ́n ti la irin mọ́ Moses Bankole tó jẹ́ ẹ̀ṣọ́ ilé epo náà kejì tó sì gba ibẹ̀ jáde láyé lójú ẹsẹ̀.

"Ogbonna àtàwọn yòókù rẹ̀ tí wọ́n jọ lọ ṣiṣẹ́ náà sì tú ẹ̀rọ jẹnẹrétọ̀ náà lọ."

Ogungbade sọ pé iṣẹ́ jẹnẹrétọ̀ ṣíṣe ni Ogbonna kọ́ tó sì ń ṣe tó sì jẹ́ pé oòun gangan ló tú jẹnẹrétọ̀ náà níbi tí ilé epo ELF dè é mọ́.

Ó fi kun pé lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí ìdigunjalè náà wáyé, ní nǹkan bíi aago méjì àbọ̀ òru ni ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá, ní agbègbè Toll Gate tẹ ọkọ̀ kan, tó kó igi àti omo inú ọ̀rá ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n tú ọkọ̀ náà, wọ́n ri pé wọ́n fi àwọn igi àti omi náà bo jẹnẹrétọ̀ tí wọ́n jí gbé ní ilé epo ELF.

'Ogbonna kò pe ẹlẹ́rìí kankan nílé ẹjọ́ láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ra jẹnẹrétọ̀ náà'

Ó ní àwọn ọlọ́pàá náà bèèrè lọ́wọ́ Ogbonna, awakọ̀ àti Kolawole Oladeji kan tó wà nínú ọkọ̀ náà láti pèsè ìwé ẹ̀rí tí wọ́n fi ra ẹ̀rọ náà ṣùgbọ́n wọn kò ri pèsè.

Kọmíṣánnà náà ṣàlàyé pé bí àwọn ọlọ́pàá ṣe ń gbìyànjú láti mú ọkọ̀ náà sílẹ̀ ni Oladeji àti awakọ̀ náà sálọ tí wọ́n sì fi Ogbonna sílẹ̀.

Ó sọ pé wọ́n fi Ogbonna sí àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá tó wà ní Toll Gate ṣùgbọ́n tó sálọ mọ́ àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ kí ilẹ̀ tó mọ́.

Ogungbade ṣàlàyé pé àwọn ọlọ́pàá ti kọ nọ́mbà ìdánimọ̀ ọkọ̀ náà sílẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

"Ìwádìí ní iléeṣẹ́ tó ń ṣe àgbékalẹ̀ nọ́mbà ìdánimọ̀ ọkọ̀ ṣàfihàn ẹni tó ni ọkọ̀ náà tó sì pèsè àwọn awakọ̀ mẹ́rin tó ń wa ọkọ̀ ọ̀hún fún àwọn ọlọ́pàá.

"Níbẹ̀ ni ọwọ́ ti tẹ Sunday Oloyede èyí tó ṣokùnfà bí wọ́n ṣe mú Kolawole Oladeji, Segun Ajibade àti Ogbonna.

"Nígbà tí wọ́n fi máa mú Ogbonna, ó ti ta jẹnẹrétọ̀ náà, tó sì mú àwọn ọlọ́pàá lọ sí ọ̀dọ̀ Ali Rihan tó ta jẹnẹrétọ̀ náà fún, ẹni tó gbé jẹnẹrétọ̀ náà padà fún àwọn ọlọ́pàá, tó sì tún jẹ́rìí tako Ogbonna nílé ẹjọ́.

Ó tẹ̀síwájú pé nígbà tí ọ̀rọ̀ náà dé ilé ẹjọ́, Ogbonna jẹ́wọ́ pé òun lọ́wọ́ nínú ìwà ọ̀daràn náà tí kò sì pe ẹlẹ́rìí kankan tako gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án nílé ẹjọ́.

"Yusuf Akanni, ẹ̀ṣọ́ ààbò tó móríbọ́ nílé epo náà jẹ́rìí tako Ogbonna àtàwọn yòó kù rẹ̀."

Ogungbade ní títí di àsìkò yìí kò sí ẹ̀rí kankan pé Ogbonna ra jẹnẹrétọ̀ náà rárá àti pé tó bá jẹ́ pé òun ló ni í ó yẹ kó fi ẹ̀rí kalẹ̀ nígba tí àwọn ọlọ́pàá dáwọn dúró àyi nílé ẹjọ́ nígbà tí ìgbẹ́jọ́ náà ń wáyé.

"Kí ló dé tí Ogbonna kò pe ẹlẹ́rìí kankan nílé ẹjọ́ láti ṣe àfọ̀mọ́ ara rẹ̀ tàbí ẹni tó mọ̀ nípa bó ṣe ni jẹnẹrétọ̀ ṣáájú àkókó náà."

Kọmíṣánnà náà wá rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti má jẹ̀ ẹ́ kí wọ́n fi ìròyìn tí kìí ṣe òótọ́ dè wọ́n mọ́lẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

"Ẹ má jẹ̀ ẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ pé nítorí pé òun ra jẹnẹrétọ̀ tí wọ́n jí ni òun fi lọ sẹ́wọ̀n ṣùgbọ́n kí ẹ ro ẹni tó pàdánù nínú ìdigunjalè wọn."

Ó ní òótọ́ tí Ogbonna ní òun ń sọ ní àwọn irọ́ nínú nítorí kò ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan.

Ó fi kun pé ní ọdún 2021 ni gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun, Dapo Abiodun ṣe àyípadà ìdájọ́ ikú tí wọ́n fún Ogbonna sí ẹ̀wọ̀n gbére kó tó di pé ó wá rí ìtúsílẹ̀ báyìí.