You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Zulum kéde gbígba àwẹ̀ ọjọ́ kan láti gbàdúrà fún Nàìjíríà
Gomina ipinlẹ Borno, Umara Zulum ti kesi awọn araalu Borno lati gba awẹ ọjọ kan lori bi ọrọ aje le koko ati bi eto abo se mẹyẹ nipinlẹ naa.
Zulum sọrọ yii nigba to ba awọn araalu sọrọ lọjọ Ẹti nibi to ti salaye pe inu oun ko dun rara ssi bi inira se pọ ti awọn araalu n lakọja ati bi ọwọngogo ounjẹ se gbode.
“Ẹyi araalu bi temi, gẹgẹ bii eeyan oni gbagbọ ti a jẹ ati awọn nnkan mii ti a ti lakọja tẹlẹ ri, mo rọ ọlọlajulọ, Shehu ti Borno, awọn Imamu agba ati awọn ọmọ iya ninu ẹsin Kristẹni lati gba awẹ lọjọ Aje, kọkandinlogun oṣu keji ọdun 2024.”
Bakan naa lo fi da awọn araalu loju pe ijọba rẹ n sa gbogbo akitiyan lati ri pe ara tu awọn araalu.
“Ijọba wa ti n ri daju pe eto ọgbin wa pada sipo, ti a si n lepa lati ri pe a pese ounjẹ si. A ti n ra awọn ẹrọ igbalode ti yoo se iranlọwọ fun awọn agbẹ wa .
“Eyi lo jẹ ki fọwọsowọpọ awọn onisowo lati ri pe a sisẹ papọ lati wa ojutu si awọn iṣoro yii.
Bakan naa ni Zulum kan sara si awọn ẹsọ alabo fun igbiyanju wọn lori didabobo ẹmi ati dukia awọn araalu.
O ni iṣejọba oun ti n fọwọsowọpọ pẹlu onisowo lati ri pe adikun wa lori iye ti awọn n taja wọn fun araalu.