You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹnu àwọn èèyàn tó fara gbá ìbúgbàmù Bodija kò kò, báwọn kan ṣe ń bú Seyi Makinde, làwọn kan ń kan sáárá si
Lẹyin ibugbamu to waye ni Adeyi, lagbegbe Bodija, niluu Ibadan ninu oṣu kin-in-ni ọdun yii, lara awọn iroyin to jade ni pe ijọba ipinlẹ Ọyọ gba ile itura meji fawọn ti dukia wọn bajẹ nipasẹ ibugbamu naa.
Erongba ijọba ni lati ṣewadii awọn ile to ṣẹku nibi ti igbugbamu naa ti waye, ki wọn le mọ awọn to nilo atunṣe ati eyi ti yoo di wiwo palẹ.
BBC Yoruba ṣabẹwo si agbegbe ti ibugbamu naa ti waye l’owurọ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejila oṣu kẹta ọdun 2024.
Akọroyin wa jabọ pe awọn ile kan ti di titunṣe.
Bẹẹ ni awọn olugbe kọọkan ti pade sile wọn, iṣẹ si n tẹsiwaju lara awọn ile mi-in.
"Awọn alakoso ọkan ninu awọn ile itura n halẹ mọ wa pe asiko ti to lati kuro nile itura naa"
Saaju ni awọn kan lara awọn tijọba gba ile itura fun yii ti ba ileeṣẹ iroyin kan sọrọ, wọn fi ẹjọ sun pe itọju tijọba ipinlẹ Ọyọ fun awọn ko to.
Lara wọn ni Ọgbẹni Ayọ Ogunlọla to ni oun dupẹ lọwọ Gomina Ṣeyi Makinde fun oore to ṣe.
Sugbọn lọjọ kẹrindinlogun oṣu keji ọdun yii, awọn alakoso ọkan ninu awọn ile itura naa n halẹ mawọn pe asiko ti to fawọn lati kuro nile itura naa.
O ni ounjẹ ti wọn n fun awọn ko ṣe deede mọ, ko to di pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ko gbogbo awọn kuro nibẹ lọ sile itura mi-in lagbegbegbe Onireke.
Ibrahim Adekunlẹ ni tiẹ sọ pe nnkan nira gan-an nibi ti wọn fi awọn si, ṣugbọn awọn n reti esi iwe ti ẹgbẹ awọn onile lagbegbe Bodija kọ si Gomina Ṣeyi Makinde.
Ijọba Ọyọ fesi: Miliọnu mẹẹẹdogun si ogun miliọnu la n n na lọsẹ fun ile gbigbe ati ounjẹ wọn
"Ọtọ ni ile itura ta wa tẹlẹ, àmọ́ wọ́n ti ko wa lọ si ile itura miran"
Kọmiṣanna fun eto Iroyin ati Ilanilọyẹ n'ipinlẹ Ọyọ, Dọtun Oyelade, ṣalaye pe irọ ni pe ijọba ko bikita nipa itọju awọn eeyan ti ọrọ igbugbamu Bodija kan.
Oyelade ninu atẹjade to fi sita, sọ pe ko din ni miliọnu mẹẹẹdogun si ogun miliọnu naira tijọba Ọyọ n na lọsẹ lori ile gbigbe ati ounjẹ awọn eeyan ti ajalu naa kan.
O ni o kere tan, eeyan mejidinlogoji ti iṣẹlẹ naa kan ṣi wa nile itura ti ijọba gba fun wọn.
BBC Yoruba ba eeyan meji mi-in sọrọ lara awọn ti ibugbamu naa kan, ohun ti wọn sọ tun yatọ si tawọn ti wọn ni ijọba ko tọju awọn.
Arakunrin Fẹmi Ojo ti iya rẹ fi ara pa nibi ibugbamu naa sọ pe, irọ to jinna si ootọ ni awọn eeyan naa n pa.
O ni ọtọ ni otẹẹli tawọn wa tẹlẹ, wọn si ti ko awọn lọ si ile itura miran bayii, eyi to wa l’Onireke, niluu Ibadan.
Èrò àwọn tíṣẹ̀lẹ̀ kan ṣòtọ̀ọ̀tọ̀, àwọn kan gbè lẹ́yìn ìjọba
Bukata ijọba apapọ ni wa, Makinde kan n ṣaanu wa ni, aimọkan lo n ṣe awọn eeyan wa - Niyi Akintola
Ẹlomi-ni ti a ba sọrọ nipa iroyin naa ni oludije sipo Gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ ri ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Amofin Niyi Akintọla, ti dukia rẹ naa bajẹ nibi ibugbamu Bodija.
Akintọla sọ pe aimọkan lo mu kawọn eeyan maa fẹjọ sun pe Gomina Makinde ko tọju awọn bo ṣe yẹ.
O ni ojuṣe ijọba apapọ ni lati wa ọna abayọ si iṣoro awọn eeyan ti iru ibugbamu naa ba ṣẹlẹ si, ṣugbọn ijọba apapọ ko ti i ṣe ohunkohun titi di asiko yii.
Amofin Akintọla sọ pe iyalẹnu lo jẹ pe awọn eeyan ti wọn rowo kọ ile, gba ile si Bodija wa n rojọ kiri pe ounjẹ ti wọn n fun awọn ko to.
O ni ṣe wọn ki i jẹun nilee wọn tẹlẹ ni.
Akintọla ni, "O yẹ ki wọn mọ pe bukata ijọba apapọ ni wa, aimọkan lo n ṣe ọpọlọpọ awọn eeyan wa.
Makinde kan n ṣaanu wa ni.
‘’Alakọwe ati ọlaju ni awa ti a wa ni Bodija, ko si talaka lara awọn to n gbe ninu Bodija.
Ibi ti ẹlomi-in ti n san milliọnu meje si mẹwaa naira lọdun, ṣe talaka ni iru ẹni yẹn?
"Nigba ti wọn wa ninu ile wọn tẹlẹ ṣe wọn ko jẹun ni? Ṣe wọn wa fẹẹ sọ bukata wọn di tijọba nisinyi ni?"
BBC ṣakiyesi pe wọn ti n tun awọn ile kan ṣe lagbegbe naa, wọn si ti so ina adugbo naa pada.