You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kokoko bí ọta lara Olubadan le – Aṣípa ilẹ̀ Ibadan
Agba oye ti ipo Olubadan ti ilẹ Ibadan sun kan, Ọba Olakulehin Owolabi lonii ṣe ipade pọ pẹlu diẹ lara awọn Ọba ilu Ibadan .
Lara awọn Ọba to sepade pọ pẹlu Ọba Olakulehin Owolabi nii Osi Olubadan, Ọba Eddy Oyewole, Osi Balogun Olubadan, Ọba Lateef Adebimpe, Ashipa Olubadan, Abiodun Kola-Daisi; Asipa Balogun Olubadan ati Ọba Kola Adegbola.
Nigba ti o n ba awọn akọroyin sọrọ Osi Balogun Olubadan, Ọba lateef Adebimpe ni, “o ti pe to ti rẹ baba wa nipa ọrọ ogbo, iyẹn ni ko jẹ ki wọn le ba wa ṣe ipade pọ.”
Oba lateef tẹsiwaju pe “igba ti ati ri wọn ti pẹ, o si di dandan ka ṣe gbogbo ipalẹmọ iwuye wọn, ẹni ti a o ṣe iwuye fun gbọdọ rii, iyẹn lo gbe wa wa.
“A si ri pe ara Ọba Owolabi Olakulehin da perepere.”
Osi Balogun Olubadan tẹsiwaju pe ti to lati gba ilu ki eto iwuye Olubadan titun si bẹrẹ.
Ipade yii ni yoo jẹ ipade ẹẹkeji ti Ọba Owolabi Olakulehin yoo ṣe pẹlu awọn igbimọ Olubadan ti ilẹ Ibadan lẹyin ti Ọba Mahood Lekan Balogun papoda.
Owolabi Olakuleyin, ẹni tí ipò Olubadan kàn yóò yọjú sí aráàlú lónìí
Agba oye ti ipo Olubadan ti ilẹ Ibadan kan, Oba Owolabi Olakulehin, lo ṣeeṣe ko ṣe ipade pọ pẹlu awọn oloye agba ati awọn afobajẹ nílẹ̀ Ibadan lọ́sàn oni.
Akọroyin BBC Yoruba ri aridaju wi pe, Oba Owolabi Olakulehin wa ninu ile rẹ, eyi ti o wa ni opopona Cassia, adugbo Alubosa to wa ni ẹba ọja Aleshinloye nilu Ibadan.
Ọkan lara mọ̀lẹ́bí Ọba Owolabi Olakulehin ṣalaye fun Akọroyin BBC Yoruba labẹ aṣọ wi pe,
"Baba wa ninu ile laipẹ yii, awọn afọbajẹ́ ilẹ̀ Ibadan nbọ laipẹ lati se ipade pọ pẹlu Ọba Owolabi Olakulehin.
Bẹ́ẹ̀ gbàgbé, Ọba Olakulehin ko ti foju kan ẹnikan kan lati igba ti Ọba Mahood Lekan Balogun, to tun jẹ Olubadan kejilelogoji papoda.
Ọ̀pọ̀ eeyan si lo n foju sọ́nà lati ri Ọba Owolabi Olakulehin nita gbangba.
Igbesẹ yii si ni yoo fopin si ọpọ ahesọ ọrọ to ti n waye lori iyansipo agba oye naa si ipo Olubadan tilẹ Ibadan.
Bi gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá ṣe ń lọ ni BBC Yoruba yoo maa mu wa fun yin laipẹ̀.