You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ pàdé Manuella, ọmọ ọdún méje tó ń ṣe àkàrà òyìnbó 'cake'
Ọmọ ọdun meje ni Manuella Oluwapamilẹrin Rowland, iṣẹ akara oyinbo ṣiṣe ati irin ṣiṣe lọṣọ lo yan laayo.
Fun ọmọ to wa ni ọjọ ori rẹ, ere ọmọde lọpọ yoo maa reti ki mọdebinrin yii maa ṣe lasiko yii ṣugbọn fun Rowland Manuella, iṣẹ akara oyinbo ti oyinbo n pe ni ‘cake’ ati irun ṣiṣe lọjọ.
Iya Manuella, arabinrin Rowland Ọmọtokẹ ṣalaye pe Manuella funra rẹ lo fi ifẹ han fun iṣẹ ọwọ yii ati pe ko di eto ẹkọ rẹ lọwọ.
Manuella funra rẹ ṣalaye pe ifẹ oun si iṣẹ ọwọ lo mu ki oun maa ṣe keeki bayii ati wi pe kii ṣe ohun kan lati di eto ẹkọ oun lọwọ.
Awọn obi rẹ sọ pe ba meji lawọn eeyan to n ri ẹbun ọmọ naa fi n wo o.
Bi awọn kan ba rii wn a kan sara si ẹbun rẹ ati bi o ṣe n jara mọ iṣẹ ọwọ lati igba ewe rẹ lawọn miran n sọ pe eyi ku diẹ kaato paapaajulọ pẹlu bi wọn ṣe ni yoo maa di eto ẹkọ lọwọ, ati pe ninu iwoye wọn nṣe lawọn obi rẹ nm fi tipa mu u.
Iya rẹ ṣalaye pe, ko si ọrọ a n fi ipa muni fun Manuella lori ọr naa. O ni ohun ti Manuella nifẹ si ni ati wi pe, lasiko isinmi nikan lo maa n ṣe e.
O ni awọn ni lati fi atilẹyin wọn han fun ọmọ awọn ni gẹgẹ bi obi nitori pe awọn rii pe o ni ẹbun rẹ.