Ẹ̀yin tẹ́ẹ fẹ́ máa ṣe "prank" pa owó bíi tèmí, ẹ má dán an wòo torí adúrú ìyà tó ń jẹ mi yìí - Trinity guy

Ẹ̀yin tẹ́ẹ fẹ́ máa ṣe "prank" pa owó bíi tèmí, ẹ má dán an wòo torí adúrú ìyà tó ń jẹ mi yìí - Trinity guy

"Awọn "prank" kan wa ti mo ṣe to jẹ wipe ko dẹrun rara, koda ohun ti oju mi ri ko le jẹ ki n fi si ori ayelujara".

Ọpọlọpọ eeyan lo mọ Moruf gẹgẹ bii Trinity Guy lori ayelujara fun iṣẹ ko maa tan eeyan jẹ fi ṣe fidio sori ayelujara.

Awọn itanjẹ kan wa ti Moruf ti ṣe to ni agbara gan to jẹ wipe o ti ko o si wahala.

Koda, o ti jẹ igbati, ifọti, ifọmu, igbaju. Wọn ti lu u bii bara to ba ara rẹ nileewosan ri.

Ọpọlọpọ eeyan to maa n wo fidio rẹ lo ti woye pe boya o ti kọ iwe rẹ tẹlẹ ni ti wọn si fẹrẹẹ ma gbagbọ pẹlu bi awada rẹ ṣe le to to si maa n ko o jiya lọpọ igba tabi ti ẹru yoo tilẹ maa ba awọn eeyan fun un.

Amọ Trinity Guy ninu ifọrọwanilẹnuwo yii pẹlu BBC Yoruba ṣalaye bo ṣe n ṣe awọn fidio rẹ ati paapaa awọn eyi to ti pa a lara.