“O wù mí kí arọ dìde, kí afọ́jú ríran ní gbogbo ìgbà tí mo bá ń sọ̀rọ̀ bíi bàbá Adeboye – Oreoluwa Simeon Oluwade

Pasitọ Oreoluwa Simeon Oluwade, to maa n ṣe bii alufaa agba ijọ Redeemed Christian Church of God, RCCG, Enoch Adejare Adeboye, ti sọ pe afojusun oun ni ki iyanu maa ṣẹlẹ ni gbogbo igba ti oun ba n ṣe bii alufaa agba ọhun.

Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba, Oreoluwa sọ pe inu ijọ RCCG ni wọn bi oun si, ilẹ si ti ta si i ti oun ti maa n woye bi alufaa agba naa ṣe maa n ṣe.

Yatọ si baba Adeboye, o sọ pe oun tun maa ṣe bii awọn alufaa mii to lamilaka lagbaye.

O ni “Awọn agba lo sọ pe ọmọ ko le jọ baba ki a wa maa binu ọmọ.”

“Mo ti n wo Baba Adeboye lati kekere, kii ṣe baba Adeboye nikan ni mo maa n ṣe bii ti wọn... mo ti ṣe bii baba Kumuyi ri... mo ti ṣe Biṣọọbu TD Jakes to wa niluu Amẹrika naa ri, ṣugbọn baba Adeboye to jẹ baba temi gangan ni mo mọọ ṣe ju.”

Bi Oreoluwa ṣe bẹrẹ si n ṣe bii baba Adeboye

O ni “Mo ṣi ranti igba ti mo wa ni kere niluu Akure, ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ OSRC maa n gbe iwaasu wọn jade lori tẹlifiṣọn ni ọjọ Isinmi ti a ba ti de lati ile ijọsin.

“Mo maa n wọn, ibẹ yẹn gangan ni mo ti bẹrẹ si n kọ bi baba Adeboye ṣe n sọrọ.”

Pasitọ naa sọ siwaju si pe o rọrun fun oun lati sọrọ bii alufa agba naa, kii ṣe pe oun fi taratara kọ bii alufa naa ṣe n ṣe.

“Ibaṣepo emi atibaba Adeboye”

Nipa ibaṣepọ to wa laarin Oreoluwa ati pasitọ E.A. Adeboye, o ni bab oun ninu Oluwa ni o jẹ.

“Baba mi ninu Oluwa ni wọn jẹ, baba mi ninu ẹmi... inu imọlẹ wọn ni awa naa ti ri imọlẹ.”

Bo tilẹ jẹ pe ọdun 2013 ni Oreoluwa kọkọ sọrọ bi alufa Adeboye, inu ipade kan lọdun 2019 lawọn eeyan ṣẹṣẹ mọ nipa rẹ daadaa.

O fi kun pe oun kii ṣe alawada, oun kii si fi awada sọrọ bii baba Adeboye nitori iranṣẹ Ọlọrun ni oun naa jẹ.

O pari ọrọ rẹ pe yoo wu ohun ki iyanu maa ṣẹlẹ ni gbogbo igab ti oun ba ti sọrọ bii alufaa agba naa.

Ẹkunrẹrẹ ohun ti pasitọ Oreoluwa sọ wa ninu fidio oke yii.