'Oṣù mẹ́ta-mẹ́ta ni mo máa ń ga si'

Ní ọdún 2015 ni Sulemana Abdul Samed ni ṣàdédé ni òun jí tí òun sì ri wí pé ahọ́n òun tóbi púpọ̀ lẹ́nu òun, tí òun kò sì ríbi mí dada mọ́.

Sulemana ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti yí ìgbé ayé òun padà tí àyípadà ńlá sì dé bá ìṣẹ̀mí òun.

Ó ní láti ìgbà náà ni òun ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ga tí òun ti ga tó ẹsẹ̀ bàtà mẹ́sàn-án báyìí tí òun kò sì tíì dáwọ́ gíga dúró.

"Láàárín oṣù mẹ́ta sí mẹ́rin ni mo máa ń ga si. Tí ènìyàn bá rí mi lónìí tó bá tún ma fi rími lẹ́yìn oṣù mẹ́ta míì, onítọ̀hún á ti ri pé mo tún ti ga si."

Sulemana tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Awuche ní gíga òun ti sọ òun di ìlúmọ̀ọ́ká ní ìlú àwọn, Gambana, to wa ní orílẹ̀ èdè Ghana.

Ó fi kun pé gbogbo àwọn ènìyàn tó bá rí òun ni wọ́n máa ń ṣe kàyéfì nítorí bí òun ṣe ga tó.

Bákan náà ló ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń fẹ́ bá òun ya àwòrán tí wọ́n bá ti rí òun

O ni "Nígbà kan rí ni Ọlọ́pàá kan dámi dúró láti bá mi yàwòrán nítorí ó ní òun kò rí ẹni tó ga bíi tèmi rí."

"Tí mo bá lọ sí ibi ayẹyẹ ni àwọn ènìyàn máa ń wá láti bámi yà àwòrán, inú mi sì máa ń dùn tí àwọn ènìyàn bá ń wá láti ṣe èyí."

Àwọn dókítà ní àìsàn "gigatism" ló ń bámi jà

Awuche ní gíga tí òun ń ga ní ojoojúmọ́ kìí se lásán nítorí àwọn dókítà àìsàn kan tí àwọn òyìnbó ń pè ní gigatism ló ń bá òun fínra.

Ó ní àìsàn yìí ló ma ń mú ènìyàn ga ju bó ṣe yẹ lọ.

Sulemana ṣàlàyé pé àwọn dókítà ní àìsàn náà máa ń fa kí egungun ènìyàn máa gùn ju ti ẹgbẹ́ lọ àti pé inú ọpọlọ ni àwọn ti lè ṣe iṣẹ́ abẹ fún òun láti tọ́jú àìsàn náà.

Ó tẹ̀síwájú pé àwọn dókítà sọ fún òun pé tí àwọn bá ti yọ òun tó wà ní orí òun náà ni nǹkan tó ṣokùnfà bí òun ṣe ń ga yóò dáwọ́ dúró.

"Tí wọn kò bá yọ nǹkan náà, àwọn dókítà ní mo ṣì ma ma ga si tó sì ń ṣe àkóbá fún ìlera mi".

Pẹ̀lú àìsàn tó ń bá Awuche fínra yìí, ó ní òun ni èròńgbà láti fẹ́ ìyàwó kí òun sì bímọ nítorí òun fẹ́ mọ bí àwọn ọmọ òun yóò ṣe rí.

Ó ní nǹkan tó ń ṣe òun yìí kìí bá òun ní ọkàn jẹ́ nítorí òun ní ìgbàgbọ́ pé àmúwá Ọlọ́run ni.

Bákan náà ló sọ fún BBC pé nígbà tí òun ṣe àyẹ̀wò bí òun ṣe ga tó kẹ́yìn, òun ga tó 9.6ft bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé BBC kò le fìdí èyí múlẹ̀.