You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
"Ìgbà kéje rèé tí a ní láti kúrò níbi tí a wà, ikú sàn ju èyí lọ"
Ikọlu Israel si Gaza tun ti sọ ọpọ idile lorilẹede Palestine di ai ni ile lori, oṣojumikoro ṣalaye.
Awọn olugbe Gaza ni ọpọ ado oloro Israel lo balẹ si awọn agbegbe bi Shujaiya, Tuffah, ati Zeitoun, ti ọpọ ẹmi si sofo lasiko ikọlu.
Ọpọ fọnran lo jade lori ayelujara, ṣafihan bi ado oloro ṣe n fo loju ofurufu niluu Gaza.
Ọkan ninu ado oloro ọhun kọlu ile ẹkọ ni Zeitoun, ti si sọ ọpọ idile di ẹni to n sun si titi.
Ọkan ninu awọn araalu to ba awọn akọroyin sọrọ ni iku san ju gbogbo eyi ti awọn n la kọja lasiko yii niluu Gaza.
"Ko si nnkan ti a fẹ ṣe ju pe ka fi gbogbo nnkan silẹ," Abeer Talba, iya ọlọmọ meje to ṣa kuro ni Zeitoun pẹlu idile rẹ ṣalaye.
"A gba ipe pe ibi ti a wa jẹ ibudo ikọlu ogun, ti a si lati kuro ni ile ti a wa.
"Igba keje ree ti a ni lati kuro nibi ti a n gbe," o fikun.
"A ti wa ori titi pada. Ebi n pa awọn ọmọ mi. Iku san ju eyi lọ."
Ajọ to n dola eeyan ni awọn ṣawari oku eeyan marun un, ti ọpọ eeyan si farapa yanayana lasiko ikọlu ibigbamu ado oloro.
Ọpọ eeyan to farapa lo ti w ani ile iwosan Al- Ahli niluu Gaza nibi ti wọn ti n gba itọju.
Ibugbamu ii lo jẹ eyi to ni agbara ju lati igba ti ogun ọhun ti bẹrẹ pada ni oṣu kẹta ọdun 2025.
Àdó olóró Israel pa èèyàn 81 ní Gaza, 400 míì farapa
O kere tan, eeyan mọkanlelọgọrin lo ti jade laye ti awọn irinwo mii si farapa lẹyin ti Israel ju ado oloro lemọ-lemọ si Gaza.
Ileeṣẹ eto ilera Gaza ti Hamas n dari sọ pe nnkan bii wakati mẹrinlelogun ni awọn ado oloro naa fi n dun leralera.
Ninu ọkan lara awọn iṣẹlẹ naa, ko din ni eeyan mọkanla to ku, ninu eyii ti ọmọde wa lara wọn lẹyin ti ado oloro balẹ si papa iṣere kan ni Gaza City gẹgẹ bi awọn oṣiṣẹ ile iwosan Al-Shifa ṣe sọ.
Fidio lati agbegbe naa ti BBC foju ri ṣafihan bi awọn eeyan ṣe n fi ọwọ wu inu iyẹpẹ lati yọ oku eeyan jade.
Atẹjade lati ọdọ ijọba ilẹ Israel ni oun ko mọ boya ẹnikẹni farapa yatọ si awọn ọta Israel ti ado oloro naa dojukọ.
Amọ ṣa, arẹ Amẹrika, Donald Trump ti ni oun gbagbọ pe awọn ikọ mejeji yoo tọwọ bọwe adehun alaafia titi ọṣẹ to n bọ.
Awọn to n jiroro lori ogun naa ni Qatar sọ pe igbagbọ wa pe akitiyan ilẹ Amẹrika yoo so eso ree lati fopin si ogun Israel ati Gaza lẹyin ti wọn dẹwọ ogun Israel ati Iran.
Ṣaaju ni Israel ati Gaza ti kọkọ dẹwọ ogun wọn ki Israel to ju ado oloro si Gaza.
Adehun naa lo wa ni ipele-ipele amọ wọn ko pari ipele akọkọ ki wọn to tun bẹrẹ si n ju ado oloro si ara wọn.
Awọn alaṣẹ Hamas sọ fun BBC pe awọn n tiraka lati fi opin si ogun naa amọ o da bii pe bakan naa ni ọmọ ṣe ori ni iha Israel.
Awọn araalu kan ṣe iwọde lalẹ ọjọ Abamẹta lati pe fun itusilẹ awọn ọmọ Israel to wa lakata Hamas ni Gaza.
Awọn to ṣagbatẹru iwọde naa sọ pe asiko ti to fun igun mejeji lati pari ija ki awọn to wa ni igbekun ọta le pada sile wọn layọ ati alaafia.
Amọ ṣa, Israel ko dẹkun ati maa ṣe ikọlu si Gaza.
Awọn oṣiṣẹ ile iwosan atawọn oṣoju mi koro sọ pe ko din ni eeyan mọkanla to ku lẹyin ado oloro Israel si papa iṣere Gaza City lalẹ ọjọ Ẹti.
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, Mohammed Haboub sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe awọn ibatan oun, to fi mọ baba atawọn ọmọ alabagbe oun lo ba iṣẹlẹ naa lọ.