Ìgbẹ́jọ́ Timilẹyin, akọrin ẹ̀mí tí wọ́n ló ṣá Salome, ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ pa bẹ̀rẹ̀, ohun tó wáyé nílé ẹjọ́ rèé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Wọn ti fi oju afurasi akọrin ẹmi, Timileyin Ajayi, ti wọn lo ṣa Salome Adaidu, agunbanirọ pa han ni kootu, ọkunrin naa si ti loun ko jẹbi.

Ile ẹjọ giga to wa ni Lafia, ipinlẹ Nasarawa, ni igbẹjọ naa ti bẹrẹ lanaa, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025.

Nigba to n dahun ibeere kootu lori iku Salome Adaidu, Timileyin sọ pe oun ko jẹbi.

Adajọ Simon Aboki lo gbọ ẹjọ naa, o si sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlogun si ogunjọ, oṣu Kẹta ọdun 2025.

Báwo ni ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ?

Agbẹnusọ ijọba lori ẹjọ naa, Stanley Nwaforagwu, ṣalaye fun awọn akọroyin lẹyin igbẹjọ, pe ẹsun ipaniyan ti idajọ rẹ jẹ iku ni wọn fi kan olujẹjọ.

"Ileẹjọ fẹ ki igbẹjọ naa waye kiakia, a ti ri ẹri to daju lati gbe ẹjọ naa lẹsẹ, a si ni ireti pe idajọ ododo yoo waye."

Agbẹjọrọ fun Timilẹyin, Joseph Tukur, sọ ni tiẹ pe, " A kan ṣi waa foju han ni kootu lonii ni bi ofin ṣe fẹ ni.

O ti dahun ibeere, a si ti mu ọjọ igbẹjọ.

Emi kọ ni mo maa jẹri ọrọ, iṣẹ temi ni lati gbeja onibaara mi, ki kootu naa si ṣe tiẹ, ohun ti mo wa fun naa ni pe ki ofin ṣiṣẹ rẹ bo ṣe yẹ."

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 yii ni igbẹjọ kọkọ waye, Adajọ Aboki si sun un si ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlọgbọn.

Nigba to n sun igbẹjọ siwaju lọjọ Aje naa, Adajọ Aboki paṣẹ pe ki wọn ṣi fi Timileyin Ajayi si ahamọ na, titi di oṣu kẹta ti igbẹjọ yoo yun waye.

Ohun tó kọ́kọ́ wáyé

Ibẹrẹ oṣu Kin-in-ni ọdun yii ni iroyin gbode, pe Timileyin Ajayi, ṣa Salome Adaidu, agunbanirọ ti wọn ni ọrẹbinrin rẹ ni pa.

A gbọ pe afurasi yii pa Salome Adaidu lasiko ti ọmọbirin naa wa a lọ sile rẹ to wa ni Papalana, nipinlẹ Nasarawa.

Bo ti pa a tan ni iroyin sọ pe o tun kun ẹran ara agunbanirọ naa wẹlẹwẹlẹ, to si di i sinu apo.

Awọn ọlọpaa mu afurasi naa pẹlu ori Salome to ge sinu apo, lasiko to n lọ si agbegbe Uke, nipinlẹ Nasarawa.

Eyi lo gbe afuraasi naa de kootu, nibi ti wọn ti fẹsun ipaniyan kan an.

To ba jẹbi ẹsun yii, iku ni ijiya rẹ labẹ ofin ilẹ wa.

Awọn ọlọpaa ṣafihan ọbẹ ati ada ti wọn ni Timileyin fi pa Salome lasiko ti wọn n ṣafihan afurasi naa.