Àwọn onímọ̀ sọ̀rọ̀ lórí ilé-iṣẹ́ nǹkan ọ̀sìn tí ìjọba àpapọ̀ dá sílẹ̀

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti orileede Naijiria ti da ẹka ileeṣẹ ijọba ti yoo maa ri sọrọ awọn nnkan ọsin, eyi ti wọn n pe ni ‘Livestock’ silẹ.

Lara awọn ojuṣe ti ileeṣẹ yii yoo maa bojuto ni bi alaafia ati ilera pipe yoo ṣe tubọ wa fun awọn ohun ọsin, paapaa julọ lati pana aawọ to n ṣẹlẹ laarin awọn darandaran ati awọn agbẹ nilẹ Naijiria.

Ọpọ igba ti ko lo n ka ni aawọ ti bẹ silẹ laarin awọn darandaran, paapaa awọn Fulani darandaran ati agbẹ, to si ti mu ẹmi dani nipa fifi ẹran jẹko.

Idasilẹ ileeṣẹ yii ni ijọba apapọ nigbagbọ pe yoo fi opin si gbogbo wahala ati idunkooko naa.

Latigba ti ijọba apapọ ti kede idasilẹ ẹka ileeṣẹ yii ni oriṣiriṣi awuyewuye ti n lọ kaakiri igboro. Bi awọn kan ṣe n sọ pe igbesẹ to dara ni, bẹẹ lawọn miran n sọ pe ohun to kan kọ leyi.

Sibẹ, BBC YORUBA ti wa kan si awọn ọjọgbọn ati awọn onimọ ijinlẹ nipa iṣẹ agbẹ ati ọgbin, paapaa nipa ohun ọsin nilẹ Afrika lati sọrọ, onikaluku wọn si sọ erongba wọn.

Wọn ni igbesẹ to dara ni ijọba gbe, ati pe yoo mu idagbasoke ba eto iṣẹ agbẹ ati ọgbin, to fi mọ ohun ọsin.

Igbesẹ to dara ni, ṣugbọn...

Ọmọwe Samson Adeọla Ọdẹdina to jẹ ogbontarigi nidi iṣẹ agbẹ ati ọgbin lorileede Naijiria nigba to n ṣalaye fun BBC YORUBA laipẹ yii, o ni igbesẹ to dara ni ijọba apapọ gbe lati mu idagbasoke ba ẹka naa.

Ọmọwe Ọdẹdina to jẹ kọmiṣanna ana fọrọ eto iṣẹ agbẹ ati ọgbin nipinlẹ Ogun sọ pe iṣẹ agbẹ pin soriṣiriṣi ẹka, gẹgẹ bi iṣẹ dokita naa ṣe pin soriṣiriṣi ẹka.

“Ti ẹ ba wo o, iṣẹ agbẹ gbooro gidi, bi iṣẹ dọkita naa ni. Nidi iṣẹ dọkita, ẹ maa ṣakiyesi pe awọn dokita to n wo oju wa, awọn ti imu wa lọtọ, awọn to n ṣe ẹsẹ naa wa lọtọ, ati bẹẹbẹẹlọ. Bakan naa lo ri nidi iṣẹ agbẹ.

“A ti fi oju tẹmbẹlu iṣẹ agbẹ ni a ko ṣe mọ pe bo ṣe ṣe pataki to niyẹn, nitori pe ohun nikan la le ṣe lai gba iwe aṣẹ nidi ẹ.

“Akọṣẹmọṣẹ ni iṣẹ agbẹ jẹ kaakiri agbaye. Ni iṣẹ agbẹ yii, ohun ti ẹlomiran gbajumọ ni ọrọ adiẹ; ẹlomiran wa to jẹ pe tolotolo, awọn miran gbajumọ ẹran ati awọn nnkan miran bẹẹ.

“Awọn miran wa to jẹ pe inu ilẹ ni wọn n ba dowo pọ. A ri awọn ọjọgbọn to jẹ pe afẹfẹ inu ilẹ ti a mọ si ‘nitrogen’ ni wọn n ṣiṣẹ pẹlu.

“Igbesẹ gidi ni ohun ti ijọba apapọ ṣe yii, nitori pe o maa jẹ ki ikọṣẹmọṣẹ tubọ wọnu iṣẹ agbẹ ni. Ti a ba wo dadaa, ohun ọsin ṣe pataki gidi ni igbesi aye ẹda.

“Idi ni pe ohun ọsin dun lẹnu, bẹẹ lo tun kun fun ọpọlọpọ aṣaraloore ti puroteeni, lati ori ẹja, igbin, adiẹ, ehoro ati bẹẹbẹẹlọ.

“Ohun ti a n pe ni Livestock kii ṣe nipa ohun ọsin nikan, ounjẹ wọn naa n kọ, awọn ounjẹ aṣaraloore ti awọn ohun ọsin yii n jẹ. Ninu gbogbo nnkan ti a n gbin patapata, eyi ti ẹranko n jẹ nibẹ lo pọ ju.

“Bi ẹ ba wo agbado ti a n gbin, ẹranko ati ẹran ọsin lo n jẹ eyi to pọ ju, bẹẹ naa ni Soya. Gbogbo awọn ilana nipa ohun ọsin ni awọn ọmọ wa n kọ nile ẹkọ giga kaakiri lorileede Naijiria.

“Ohun ọsin ko ṣee fọwọ rọ sẹyin ninu iṣẹ agbẹ lagbaye.”

Bakan naa, Ọmọwe Adeọla Ọdẹdina to ti figba kan ri jẹ ọga agba pata nile ẹkọ gbogboniṣe ti Moshood Abiọla, iyẹn MAPOLY to wa niluu Abẹokuta fi kun ọrọ rẹ pe ko le si wahala kankan laarin ileeṣẹ tuntun yii ati ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ agbẹ ati ọgbin.

O ni “Ti a ba wo o nigba kan, abẹ ileeṣẹ to n ri sọrọ agbẹ ati ọgbin ni gbogbo ileeṣẹ yii wa tẹlẹ, ṣugbọn ti ijọba sọ pe ki wọn da duro bayii.

“Nigba ti a gba ominira, ileeṣẹ agbẹ ati ọgbin nikan ni oyinbo fi silẹ fun wa. Lara awọn ileṣẹ to si wa labẹ rẹ ni ileeṣẹ to n ri sọrọ igbo, eto ayika, okoowo ati idaṣẹsilẹ ati awọn miran ko to di pe ijọba pin wọn sọtọọtọ.

“Ti ileeṣẹ to n sọrọ ohun ọsin naa ba da duro, o maa tun jẹ ki iṣẹ pọ ni, oju a si le ka wọn.”

Siwaju sii nigba to n sọrọ nipa bi wahala awọn agbẹ ati darandaran yoo ṣe dinku, Ọmọwe Adeọla jẹ ko di mimọ pe ipade alaafia laarin awọn mejeeji yii lo le mu ki wahala naa dopin.

“Bi a ba yọwọ ti oṣelu kuro, ki awọn darandaran ati agbẹ joko ipade lati ba ara wọn sọrọ gẹgẹ bi oniṣowo ti wọn ko gbọdọ pa ara wọn lara.

“Igba miran wa to jẹ pe oṣelu lo maa n da wahala yii silẹ. Koda, laarin inu ile wa gan-an, aawọ maa n wa, ṣugbọn a maa n yanju ẹ ni, ko sibi ti ko si aawọ ni. A ni lati yanju rẹ gẹgẹ bi awọn to n ṣe owo ni, kii ṣe gẹgẹ bi awọn to n ṣe oṣelu.”

Ọrọ oṣelu ni wọn fi da ileeṣẹ yii silẹ - Ọjọgbọn Oluṣẹgun

Nigba toun naa n sọrọ, ọjọgbọn nipa nnkan ọsin lorileede Naijiria, Ọlọruntobi Oluṣẹgun

“Bi a ba ni ka wo daadaa, a le ni nnkan ti Naijiria nilo lasiko yii ni. Ọna meji lo pin si, bo tilẹ jẹ pe lara awọn idi ti ijọba apapọ sọi pe o fa idasilẹ ileeṣẹ yii, gẹgẹ bi mo ṣe wo, ọrọ oṣelu lasan ni mo ka a si.

“Nibi ti Naijiria de duro yii, a ti nilo lati ni ileeṣẹ to jẹ pe nnkan ọsin nikan ni wọn maa gbajumọ. Idi ni pe bi ẹ ba lọ si awọn orileede bii Kenya tabi Uganda, ti ẹ ba n ba awọn eeyan sọrọ, ti ẹ si mẹnuba iṣẹ agbẹ igbalode, ti ẹ ko ba tete sọrọ pe lori oko ẹgẹ lẹ n sọ nipa ẹ, ibi maluu ni ọkan ti wọn maa lọ.

“Ohun to gbajumọ lọdọ ti wọn niyẹn, ṣugbọn ti a ba n sọrọ nipa iṣẹ agbẹ igbalode, ninu ọkan ti wa, a ti n ri aworan katakata ninu oko agbado ati ẹgẹ, ohun to si wa lọkan pupọ ọmọ Naijiria niyẹn.

“Lati ọdun pipẹ lati gbagbẹ nipa ọhun ọsin patapata. Laipẹ yii ni emi ati ọrẹ kan jọ n sọrọ nipa ibi ti wọn ti n pa ẹran, to si lo n jẹ iyalẹnu foun pe ko si akọṣẹmọṣẹ oniṣegun nipa ẹran ọsin nibi ti wọn ti n pa ẹran ni Naijiria.

“Ẹni naa sọ pe oniṣẹgun mẹta pere lo wa ni ibi ti wọn ti n pa ẹran ni ipinlẹ Ọṣun nibi toun ti lọ ṣe agunbanirọ, eyi ti ko si yẹ ko ri bẹẹ. Gbobo ibi ti wọn ti n pa ẹran lo yẹ ki awọn dokita ẹranko lo maa bojuto, ṣugbọn ko ri bẹẹ.

“Awọn agbẹ ohun ọsin nilo iranlọwọ, nitori pe oriṣiriṣi iroyin lo ti n lọ wi pe awọn agbẹ ohun ọsin ti n ko igba wọle. Bi ẹ ba si gbe ọrọ yii de ileeṣẹ agbẹ ati ọgbin, wọn maa sọ pe wọn ṣi n ṣagbeyẹwo rẹ lọwọ ni, ti ko si le pari.

“Ni bayii ti ileeṣẹ to n bojuto ohun ọsin ti wa, o tumọ si pe gbogbo awọn ti yoo maa ṣakoso ileeṣẹ yii ni wọn a jẹ awọn ti oye iṣẹ naa ye, ati nipa bi nnkan ṣe yẹ ko lọ lori ọrọ ohun ọsin.

“Eyi yoo jẹ ki eto iṣuna wa fun ohunkohun ti ileeṣẹ naa ba fẹẹ ṣe. Mo mọ pe ayipada rere maa wa nipa awọn nnkan ọsin lorileede Naijiria laipẹ, iyẹn bi wọn ba ṣe ojuṣe wọn daadaa.

“Mo ṣẹṣẹ de lati ibi ipade apero lorileede Japan ni, lara awọn ti a jọ pade nibẹ jẹ ko ye wa pe o ni iye ti ijọba maa n fun awọn lori wi pe wọn n pese miliiki lasan, o si niye ti wọn n ṣe jade. Ṣugbọn eyi ko ṣẹlẹ bẹẹ ni Naijiria.

“Bi maluu kan ba ku lonii, ko si owo ti agbẹ yoo gba lori rẹ, agbẹ naa lo padanu. Ti mo ba gba miliiki, ti ko ba dara, ipadanu agbẹ lo jẹ, ko si nnkan ti ijọba fẹ ṣe sii.

“Ṣugbọn ti ileeṣẹ yii ba wa, gbogbo awọn nnkan wọnyi ni mo lero wi pe wọn maa mojuto, ti ilana yoo si wa. Ṣugbọn sibẹ, ọrọ oṣelu ni mo ka a si lati mu ọkan apa kan ni Naijiria bablẹ fungba diẹ. Eyi si jẹ ọkan lara ẹgbẹẹgbẹrun wahala to n ṣẹlẹ lasiko yii.

Nipa fifi opin si wahala agbẹ ati darandaran

Ọjọgbọn Oluṣẹgun tẹsiwaju pe “Njẹ a ri ileeṣẹ to ti yanju ọrọ ti wọn gbe le wọn lọwọ ri, ibeere akọkọ niyẹn. Ileeṣẹ to n bojuto eto ilera ni Naijiria, ṣe wọn ti bojuto gbogbo eto ilera tan nilẹ wa? Rara! Wọn kan maa ṣe iwọnba ti wọn le ṣe ni.

“Ṣugbọn lori eyi ti a n sọ yii, o maa rọrun diẹ lati ṣe odiwọn ohun ti wọn n ṣe ni. Ipa ti wọn n ko la maa mọ bi iṣẹ ba ṣe n lọ lọdọọdun. Kaakiri agbaye, ko si ileeṣẹ to le yanu iṣoro patapata, ṣugbọn to kan maa mu adinku ba iṣoro ọhun lasan ni.

“To ba jẹ ileeṣẹ yii ni wọn maa ni ko ṣakoso lori wahala to n ṣẹlẹ laarin agbẹ ati darandaran, o ma rọrun lati tete beere lọwọ wọn nipa ipa ti wọn ti ko laarin ọdun kan, ọdun meji, ati bẹẹbẹẹlọ.

“Ẹ ma gbagbe pe ileeṣẹ yii ko nii jokoo siluu Abuja nikan, wọn maa ni ẹka ileeṣẹ kaakiri ipinlẹ kọọkan. Ohun to jẹ emi logun julọ ni ipa rere ti wọn maa ko lẹka eto ohun ọsin ati agbẹ ni Naijiria nigba ti iṣẹ ba bẹrẹ ni pẹrẹu.”

Ààrẹ Tinubu dá ẹ̀ka ìjọba tó ń rí sí ìdàgbàsókè ètò nǹkan ọ̀sìn sílẹ̀

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti kede idasilẹ ẹka ijọba ti yoo ma risi nnkan ọsin lorilẹede Naijiria lati le fopin awọ to ma n waye laarin awọn agbẹ ati darandaran nnkan ọsin lorilẹede Naijira.

Aarẹ buwọlu idasilẹ lọjọ Isẹgun nigba to n se ifilọlẹ awọn igbimọ to n risi nnkan ọsin ni ile ijọba niluu Abuja.

Ọpọ igba ni awọ ti bẹ silẹ laarin awọn agbẹ ati darandaran sugbọn Aarẹ ni oun gbagbọ pe idasilẹ ẹka yii yoo yanju gbogbo iṣoro naa.

“Ta lo ni ọna abayọ jina? Mo ni, rara, ọna abayọ ti de. Ọpọ yin ni ẹ ni iriri to dara, ti ẹ si fẹ ki orilẹede gboro si,” Aarẹ sọ.

“Lati jẹ ki Naijiria jẹ anfani eto ọsin, a ti ri ọna abayọ ti yoo se anfani lati tan gbogbo iṣoro ti a n dojukọ lati ọpọ ọdun sẹyin, ti mo si gbagbọ pe idagbasoke ti de sọwọ wa bayii.”

Pẹlu igbesẹ yii, Aarẹ ni Naijiria yoo tẹsiwaju lati se ohun to tọ lati ri pe aabo wa fun nnkan ọgbin to n wa lati oko.

Bakan naa ni Aarẹ ni oun setan lati pese owo fun rira ilẹ lati ri pe ibagbepọ alaafia wa laarin agbẹ ati agbẹ nnkan ọsin.

Aarẹ Bola Tinubu ni yoo jẹ alaga igbimọ naa, ti alaga ajọ eleto idibo tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Attahiru Jega yoo jẹ igbakeji.

Igbimọ yii ni yoo pese ọna abayọ si bi ibagbepọ alaafia yoo se wa laarin awọn agbẹ ati darandaran, riri daju pe eto aabo naa wa, anfani fun eto ọrọ aje ati fun gbogbo ọmọ Naijiria.

Ikede yii n waye lẹyin oṣu mẹwaa ti Aarẹ buwọlu idasilẹ igbimọ ileesẹ Aarẹ to tan iṣoro awọn agbẹ ati darandaran, ti bi eto ọsin yoo gboro si.

Aarẹ da igbimọ naa silẹ lẹyin to abọ iwadii lati bi apero eto ọsin , ti alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Abdullahi Ganduje jẹ alaga fun, ti wọn si pe ọna abayọ mọkanlelogun, paapa dida ẹka eto ọsin silẹ fun Aarẹ Bola Tinubu.