You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Pásítọ̀ tí wọ́n fi sí àhámọ́ fún pípe Ààrẹ ni ‘ẹ̀mí èṣù’ gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yin ọdún méjì
Pasitọ kan to ti figba kan ri jẹ minisita fọrọ eto idajọ lorileede Equatorial Guinea, Rubén Maye Nsue Mague ti wọn fi si ahamọ lọdun meji sẹyin ti gba itusilẹ.
Aarẹ Teodoro Obiang Nguema ti orileede ọhun lo paṣẹ pe ki wọn fi Nsue Mague silẹ.
Ọdun 2022 ni wọn fi kele ofin gbe Mangue pẹlu bo ṣe sọrọ abuku si Aarẹ Obiang ninu ohun akasilẹ to fi ranṣẹ kaakiri orileede naa, nibi to ti sọ pe ‘eṣu...to de awọn eeyan rẹ mọlẹ gẹgẹ bi ẹlẹwọn’ ni aarẹ wọn.
Ọdun 1979 ni Obiang, ẹni ọdun mejilelọgọrin di aarẹ lẹyin iditẹ-gbajọba to waye lọdun naa lọhun, oun si ni aarẹ to pẹ ju lori ipo nilẹ Afrika.
Lẹyin to ṣe eyi ni Mangue kọ lati tọrọa aforiji lori iwa to hu naa. Eyi lo si mu ki wọn fi ẹsun kan an wi pe o n dunkooko laarin ilu, ti ileeṣẹ eto idajọ naa si tun fi ofin de e lati ma ṣe waasu mọ.
Ọpọ awọn ajọ ajafẹtọ ọmọniyan ni wọn ti ṣapejuwe Obiang gẹgẹ bi oludari to n pa aṣẹ, to si n fẹ ki aṣẹ rẹ fẹsẹ mulẹ.
Lọdun 2022 ni Obiang tun jawe olubori ninu eto idibo aarẹ fun igbakẹfa, pẹlu bo ṣe mu ida marundinlọgọrun-un ibo to fi bori.
Awọn oloṣelu alatako ti wọn wa nidi epo rọbii ilẹ naa ni wọn ko fi bẹẹ faaye gba, ati pe ko tun si anfaani fun awọn akọroyin lati ṣiṣẹ wọn bo ti tọ.
Lọjọ Aje, ọsẹ yii, Mangue sọ pe iroyin AFP pe oun ko tii gba iwe kankan lati ọdọ agbẹjọro lasiko to fi wa lahamọ, bẹẹ si ni wọn ko tii fi oju rẹ ba ile-ẹjọ kankan.
“Mo wa ni ahamọ ti wọn ko ti gba mi laaye kankan,” wọnyi lohun ti wọn lo sọ.
Aṣẹ to wa lọjọ Ẹti to kọja la gbọ pe o tu Mangue ati awọn mọkandinlogun miran silẹ lahamọ ati ẹwọn ti wọn wa.
Pasitọ ti wọn ta ami ororo le lori ni Ọgbẹni Mangue ninu ijọ Prophetic Ministry Church of the Shadow of Christ.
Aarin ọdun 1998 si 2004 ni Mangue fi jẹ minisita fọrọ eto idajọ ko to di pe Aarẹ juwe ọna ile fun un.
Lọdun 2007 ni wọn sọ Mangue di aṣoju orileede Equatorial Guinea nibi ajọ iṣọkan ilẹ Afrika, bẹẹ ni wọn sọ ọ di aṣoju orileede naa si ilẹ Amẹrika lọdun 2013.
Ni ọdun to tẹle ni wọn fura sii pe o n fiya jẹ ọmọdebinrin kan nile rẹ to wa l’Amẹrika, ṣugbọn ti wọn ko fi kele ofin gbe e nitori to ni anfaani ofin ti ko le gbe e.
Nigba naa, Mangue ko sọ ohunkohun lori ẹsun ti wọn fi kan an yii.