Ọmọ Baba Suwe fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i ní àjùlé ọ̀run

Baa ku laa dere, eeyan ko sunwọn laaye ni Yoruba maa n wi.

Ọpọ eeyan ni kii mọ riri awọn ẹni wọn nigba ti wọn wa loke eepẹ amọ ti wọn ba gbesẹ tan, ni wọn yoo to mọ riri wọn.

Amọ fun ọpọ awọn eeyan kan, bi onirese wọn ko ba fin igba mọ, awọn eyi ti wọn ti fin silẹ, ko le parun laelae.

Idi si ree ti Adesola Omidina, tii se ọmọ adẹrinposonu nni, Babatunde Omidina, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Suwe, tun fi n ranti baba rẹ loni.

Ohun to faa ni pe oni ọjọ kejilelogun osu kẹjọ ni ayajọ ọjọ ibi Baba Suwe, tii se gbajumọ alawada ti aye n fẹ amọ to ti ki aye pe o digbose.

Baba Suwe ni aburada daradara to bo wa lori – Adesola Omidina

Nigba to n seranti ọjọ ibi baba rẹ to ko loni, Adesola Omidina sọrọ ilẹkun loju opo ayelujara Instagram rẹ.

Ọmọ baba Suwe ni oun ko le salai ma mọ riri baba oun ni oni tii se ayajọ ọjọ ibi rẹ.

O lo akoko naa lati dupẹ lọwọ rẹ fun ọpọ atilẹyin nla to ti se fun.

Adesola ni “Baba mi tootọ, n ko le salai mọ mọ riri yin lojoojumọ, paapaa loni ọjọ ibi yin.

Ẹ seun, mo dupẹ fun bẹ se kọ mi lati niwa irẹlẹ, ti mo si jẹ alabukun fun, ti mo jẹ lonii.

Amọ, baba mi, ibanujẹ ni aisi laye yin loni jẹ nitori ẹyin ni aburada nla daradara to bo wa lori.

Ẹ seun fun gbogbo awọn akoko tẹ mu ki awa ọmọ, ololufẹ ati gbogbo agbaye rẹrin.

Bi o tilẹ jẹ pe ẹ ko le fun wa ni awọn ohun meremere aye yii amọ ẹ fun wa ni ifẹ pipe.”

Adesola wa n dupẹ lọwọ baba rẹ, to si ni oun le fi yangan pe Baba Suwe ni baba oun.

Aile ri ọ mọ jẹ irora ti ko se fi ara da – Ọmọ Omidina

Bakan naa ni ọmọ Baba Suwe tun tẹsiwaju pe oun n saaro baba oun ati gbogbo awọn akoko ti awọn dijọ lo papọ.

Adesola ni irora nla ni aile ri baba oun mọ jẹ fun oun, ti ko si se fi ara da.

O wa n ki baba rẹ ku ọjọ ibi rẹ to ko loni, eyi to ba ni ajule ọrun.

Ta ni Babatunde Omidina, Baba Suwe?

Adesola I. Morenikeji Omidina OMO_OMIDINA Adẹrinposonu tabi alawada nla ni Babatunde Omidina, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Suwe.

Ọjọ kejilelogun osu kẹjọ ọdun 1958 lo dele aye, ti ko ba si pe ẹni ọdun mẹrinlelọgọta loke eepẹ loni, tii se ayajọ ọjọ ibi rẹ.

Ọdun 1971 lo bẹrẹ si ni kopa ninu ere tiata amọ ọdun 1997 ni okiki rẹ wa to kan lati ipasẹ awọn sinima kan to kopa ninu wọn.

Lara awọn sinima to gbe Baba Suwa han faraye ni Baba Jayejaye, Oluweri Magboojo, Ba o ku, Oju Oloju, Baba Londoner, Ko tan si be, Aso Ibora, Obelomo, Elebolo, Larinloodu ati Omo Lasan.

 Baba Suwe maa n kopa ninu ere tiata pẹlu ọkan lara awọn aya rẹ, to n jẹ Moladun lagbo tiata.

Amọ iji aye de ba lọdun 2001, nigba ti ajọ to n dena gbigbe oogun oloro ni Naijiria, NDLEA mu pe o gbe eroja Cocaine.

Ọrọ naa dele ẹjọ amọ ti adajọ da Baba Suwe lare pe ko jẹbi ẹsun naa nitori NDLEA ko ri ẹri kankan fi silẹ.

Sugbọn lati akoko naa ni Alawada naa ti bẹrẹ aisan nitori o ni wọn ki awọn irin kan bọ oun nidi ati ninu pẹlu ipa, pe ki oun le ya awọn idi oogun oloro jade.

Bi o tilẹ jẹ pe o du ẹmi rẹ amọ aisan lo se wo, a ko ri ti ọlọjọ se.

Babatunde Omidina dagbere faye nile iwosan kan nilu Ikorodu, nipinlẹ Eko to n gbe ni ọjọ kejilelogun osu Kọkanla ọdun 2021.