‘Gbogbo mọ́lẹ́bí mi ni wọ́n pa, tó fi mọ́ àwọn ọmọ ìyàwó mi mẹ́rin’

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Nọọsi kan ni Gaza sọ fun BBC pe iyawo ati ọmọ oun mẹfa, to fi mọ awọn ọmọ mẹrin to tun bi, ni wọn pa danu niu ikọlu to waye ni aringbungbun ilu Gaza.

“Gbogbo mọlẹbi mi ni wọn pa danu ninu ikọlu ọhun”, Ashraf El Attar lo sọ eyi, to si tun jẹ ko di mimọ pe “ni bayii, nko ni ohunkohun to ṣẹku mọ.”

Nọọsi ọhun to n ṣiṣẹ ni ile iwosan to wa niluu Gaza – sọ pe ile ti oun n gbe pẹlu iyawo oun ni Deir-al-Balah ni wọn ṣe ikọlu si laarọ kutu ọjọ Aiku, nibi to ti jẹ pe oun nikan lẹni ti ori ko yọ pẹlu ọgbẹ diẹ lara.

Nigba to n ba ẹka BBC ti Arabic sọrọ, nọọsi naa jẹ ko di mimọ pe nnkan bi agogo mẹfa kuru owurọ, iyẹn lasiko to n mura lati lọ si ibiṣẹ ni wọn ṣe ikọlu naa, o loun deedee gbọ pe aago wọn n dun.

O sọ pe loju ẹsẹ loun ti jade sita, nibi ti ko ti rọrun lati jade sita, ati pe niṣe ni wọn ba gbogbo ile oun jẹ patapata.

Awọn Israel ko sọ ohunkohun lori ikọlu yii, ṣugbọn o sọ pe awọn ikọ ologun ohun n ṣe ikọlu si ilu naa. Bakan naa lo tun sọ pe ikọlu si awọn ọmọ ogun ilu naa loun n ṣe.

Lara awọn to ku nibi ikọlu ọhun ni iyawo rẹ - Hala Khattab, to jẹ olukọ ile ẹkọ, ati awọn ọmọ wọn mẹfa - ọmọ ọdun mẹẹdogun ati awọn ọmọ mẹrin ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun kan si ọdun mẹwaa.

“Mo bẹrẹ sii pe orukọ iyawo ati awọn ọmọ mi, ṣugbọn ko sẹni to da mi lohun, nitori pe gbogbo wọn lo ti ku,” o fi kun ọrọ rẹ.

“Awọn ọmọ mi mẹfẹẹfa, to fi mọ awọn mẹrin, ati iyawo mi ni wọn ku loju ẹsẹ,” Ọgbẹni El Attar fidi rẹ mulẹ.

O fi kun ọrọ rẹ pe oun ko reti ikọlu naa lasiko to wye. Ni alẹ to ṣaaju iku wọn, awọn mọlẹbi naa ni aṣalẹ to dara nipa ijiroro loriṣiriṣi, ti wọn si n reti opin ogun to n ṣẹlẹ ni Gaza.

Mama El Attar – to jẹ iya agba fun awọn ọmọ rẹ mẹfa – sọ pe oun ko le ṣalaye bi ikọlu ọhun ṣe ṣẹlẹ nile wọn.

“Ọmọ mi Ashraf jẹ nọọsi ni European hospital to wa ni Gaza, nibi to ti fi ara rẹ jin lati maa doola ẹmi awọn eeyan, to si n ṣe itọju fun awọn alaisan.

“A ko ni ibaṣepọ pẹlu ikọ kankan,” ohun iya agba naa sọ ree.

Mama naa tun tẹsiwaju pe “Oun pẹlu iyawo rẹ lo asiko to pọ lati tọ awọn ọmọ wọn dagba, paapaa awọn mẹrin ti wọn ni.”

“Awọn ọmọ naa ni wọn la itọju ara ọtọ kọja nigba ti wọn bi wọn.”

“Titi digba ti a fi ra ikoko afẹfẹ igbalode (oxygen) ti a si tọju rẹ sile, nitori pe wọn nilo rẹ gidi nigba naa, ọkan lara wọn, ti a n pe ni Hamman, iṣẹ abẹ ni wọn ṣe fun un,” o sọ eyi.

Ọgbẹni El Attar sọ pe iyawo oun - Hala - ti fi ara rẹ jin lati ran awọn ti ori ko yọ lọwọ ogun lọwọ.

Obinrin naa n ṣiṣẹ pẹ ajọ agbaye ti United Nations Relief and Works Agency (UNRWA), nibi ti wọn ti n ṣe itọju awọn ti ara Palestine fi silẹ lahamọ.

Nọọsi naa sọ pe ohun to ṣẹlẹ soun yii, ti fa koun maa da gbe.

“Mo n ṣiṣẹ takuntakun lati ṣe itọju mọlẹbi mi, inu mi si maa n dun lati ri bi awọn ọmọ mi ṣe n dagba. Mo fẹẹ fun wọn ni igbe aye to dara – lati kọ ile nla, ra ọkọ nla, ki n si ra foonu olowo nla fun wọn,” o sọ bẹẹ.

Ṣugbọn ni bayii “gbogbo erongba ati afojusun mi ni wọn ti ge danu.”

“Mo nilo lati gba idajọ ododo lori iku mọlẹbi mi”, eyi ni ireti rẹ pẹlu bo ṣe fẹẹ pe ẹjọ si “ile ẹjọ agbaye”.

“Ẹṣẹ nla ni awọn ara Israel ṣẹ yii. Gbogbo mọlẹbi mi patapata ni wọn mu kuro lẹẹkannaa, ti wọn si fi mi silẹ sinu korofo.”

Ileeṣẹ ologun Israel ko sọ ohunkohun nipa ikọlu yii, ṣugbọn wọn sọ pe awọn ṣe ikọlu ogun nitosi Deir al-Balah lopin ọsẹ.

Ninu atẹjade ti wọn gbe jade lọjọ Aje, ikọ ologun sọ pe awọn gbe ikọlu dide lẹyin Deir al-Balah “Nibi ti wọn ti pa awọn araalu, ti wọn si ba awọn ile ologun lori oke ati lori ilẹ.”

O ni awọn n ṣe ikọlu si awọn ẹgbẹ ọmọ ogun ni, to si sọ pe awọn Hamas lo ṣe ikọlu ọhun, ti wọn pa awọn araalu – to ni ohun ti gbe awọn ajagun, nnkan ija ogun ori ofurufu ati abẹ ilẹ, to fi mọ ile dide lawọn agbegbe naa.

Hamas, to lewaju ikọlu lọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023, pa ẹgbẹrun kan ati igba eeyan, ti wọn si ji eeyan 251 gbe ni Gaza.

Ikọlu yii lo bi Israel ninu ti awọn naa fi dide ogun, nibi ti ikọ ologun wọn ti ṣe ikọlu si Gaza, to si fa iku awọn to le ni ẹgbẹrun ogoji (40,170) ni Gaza, gẹgẹ bi ileeṣẹ eleto ilera Hamas to wa ni Gaza ṣe sọ.