Ìṣẹ̀lẹ̀ omiyalé kọlu Czech Republic, Poland àti Austria, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò

Flooding

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iye eeyan to ti ku ni aringbungbun ilẹ Europe ti pọ si bayii latari iṣẹlẹ omiyale to n waye nibẹ.

Awọn orilẹede ti iṣẹlẹ naa ti milẹ titi julọ ni Czech Republic, Poland ati Austria.

Lọwọ yii, eyan kan ti ku ni Poland, ni Austria, eeyan meji mii ti jade laye.

Ileeṣẹ iroyin Austria kan sọ pe ọkan ninu awọn eeyan naa jade laye lẹyin to bẹ sinu omi naa lati oju ferese ile rẹ to si ri.

Ni Poland, Romania ati Austria, eeyan mẹjọ ti ku.

Iroyin ni lara awọn to ku ni oṣiṣẹ panapana to n gbiyanju lati doola awọn eeyan mii.

Bo tilẹ jẹ pe nnkan ti n pada bọ sipo ni aringbungbun Europe, awọn orilẹede mii nibẹ ti n gbaradi fun iṣẹlẹ mii to ṣeeṣe ko waye.

Ni Slovakia, odo Danube to kun akunfara ti fa omiyale lagbegbe Old Town ni ilu Bratislava to jẹ olu ilu ilẹ orilẹede naa

Ni Hungary, awọn araalu ti n gbaradi fun omiyale ti yoo de awọn naa lalejo.

A gbọ pe iwọn mita kan ni omi Danube yi n ga si laarin wakati mẹrinlelogun.

Ni bayii, wọn ti wọgile irinajo ọko oju irin laarin Budapest ati Vienna.

Olootu ijọba Viktor Orban sọ loju opo X rẹ pe oun ti wọgile gbogbo irinajo ilkẹ okeere to yẹ ki oun lọ latari iṣẹlẹ omiyale ọhun.