You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn ibùdó ìgbafẹ́ nílẹ̀ Yorùbá tí o lè lọ fún ìsinmi
Bí a bá ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ láàárín ọdún kan, kò sì ohun tó burú bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá pinnu láti gbádùn ẹ̀mí rẹ̀ fún ọjọ́ díẹ̀.
Lára àwọn ọ̀nà tí èèyàn lè gbà sinmi ni ṣíṣe àbẹ̀wò sáwọn ibùdó ìnàjú tó wà káàkiri àyíká rẹ.
Ṣíṣe ìnàjú túmọ̀ sí pé kí èèyàn kúrò ní ilé rẹ̀ lọ sí ibùdó pẹ̀lú èrò láti lọ fún ìsinmi, gbafẹ́ tàbí lọ mọ̀ nípa nǹkan.
Ṣíṣe ìnàjú dára púpọ̀ fún àgọ́ ara èyí tó mú kí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, United Nations (UN), ṣe ya gbogbo ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án, ọdọọdún láti máa fi ṣe àyájọ́ ọjọ́ ìnàjú ní àgbáyé.
Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn èèyàn máa ń rò ó pé ó di dandan kí àwọn kúrò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ sí ilẹ̀ òkèrè kí àwọn tó lè rí ibi ìnàjú tó gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀.
Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ nítorí àwọn ibi ìnàjú tó yááyì wà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ́pọ̀ yanturu kódà ọ̀pọ̀ wọn ló wà ní ilẹ̀ Yorùbá.
Èyí ló mú BBC News Yoruba, bí a ṣe ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìnàjú lónìí, ṣe àkójọ àwọn ibi ìnàjú tó wà káàkiri ilẹ̀ Yorùbá tí ẹ lè ṣe àbẹ̀wò sí láti rí àwọn ohun mèremère tó wà níbẹ̀.
Osun
Odò Ọ̀ṣun Osogbo ní ìlú Osogbo
Erin Ijesha waterfall ní ìlú Erin Ìjẹ̀sà
Ojúbọ Odùduwà
Nike Art Centre ní ìlú Osogbo
Ààfin Ọọ̀ni Ilé Ifẹ̀
Obalata Centre for Creative Arts ìlú Osogbo
Ibodi Monkey Reserve ní ìjọba ìbílẹ̀ Atakumosa
Ibùdó ọ̀pá Oranmiyan tó gùn tó ìwọ̀n bàtà méjìdínlógún ní Ilé Ifẹ̀
Ère Moremi Ajasoro ní Ilé Ifẹ̀
Ère Ọwá Obokun ní Ilesha
National Museum Ilé Ifẹ̀
Omi Oyi Ayikunnugba ní Oke-Ila
Ayẹyẹ Ọdún Ọlọ́jọ́ ní Ilé Ifẹ̀
Oyo
Ado Awaye mountain and suspended lake
Oke Agbede ní Igbeti
Oke Iya Mapo ní Igbeti
Captain Bower’s tower ní ìlú Ibadan
Cultural Centre ní Ibadan
Odo Akeu Natural Spring water ní Ibadan
Oke Ibadan
Ojúbọ Osanyin ní Ijaye, ìjọba ìbílẹ̀ Akinyele
National Museum of Unity
Oke Idan
Ondo
Oke Idanre
Araromi White Sand Beach
Ebomi Lake
Igbo Olodumare
Isarun Cave of Ashes
Igbokoda Waterfront
Owo Museum
Ekiti
Ikogosi Warm Spring
Arinta Waterfall
Fajuyi Memorial park
Esa Cave
Eko Olosunta
Ipole-iloro Waterfall
Ero Water Dam
Odò Oni Efon Alaaye
Eko
Lekki Conservation Centre
Nike Centre for Arts and Culture
Nature and Wildlife
Freedom Park
Ogun
Òkúta Olumo Rock
OOPL Wildlife Park
Centenary Hall
Abeokuta Museum
Yàrá ìkàwé Olusegun Obasanjo
Kwara
Owu falls ní Owu-Isin
Ero-Omola ní Oke-Ero
Esie Museum
Oke Sobi
Káàkiri àgbáyé ni àwọn èèyàn ti máa ń ṣe àbẹ̀wò sáwọn ibi ìnàjú yìí, ìwọ náà lè ṣàbẹ̀wò síbẹ̀ fún ìsinmi àti ìmọ̀ kíkún nípa wọn.