You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ìgbésẹ̀ pàjáwìrì méje fún ìdóòlà ẹ̀mí fún ẹní tó n pọ̀kàkà ikú
Ojumọ kan ko ni mọ ti ewu ko ni ṣẹlẹ lorilẹ aye.
Ninu ki ewu naa fo wa ru tabi ka faragba, ọkan yoo ṣẹlẹ si ẹdamọniyan.
Lọpọ igba ni eeyan a si maa nilo itọju ti o ba farakasa iṣẹlẹ to mu ipalara wa tabi eyi to fẹ mu ẹmi ẹda pin.
Igbakigba ti iṣẹlẹ pajawiri ba ṣẹlẹ, iru itọju ti eeyan ba ri ni kete ti o ṣẹlẹ le jẹ atọna idoola ẹmi onitọun tabi ko si mu ẹmi rẹ lọ.
Itọju pajawiri ti oloyinbo n pe ni First Aid jẹ eleyi to ṣe pataki lati fi doola ẹmi.
Eeyan si le ṣe itọju yi lẹyin iṣẹlẹ to ba fẹ mu ẹmi lọ tabi ipalara ṣaaju ki awọn oṣiṣẹ pajawiri to de.
Bawo wa lo ṣe yẹ ki a ṣe itọju pajawiri yi ati pe ki lawọn igbesẹ idoola ẹmi taa le gbe ti eeyan kan ba wa ninu ewu tabi to n pọkaka iku.
Atupalẹ ree lori awọn ohun taa le ṣe kawọn akọṣẹmọṣe to de tabi ki a to ri ẹni naa gbe lọ si ile iwosan fun itọju to peye.
Ki ni a n pe ni itọju pajawiri ''First Aid''
Itọju pajawiri ni eyikeyi igbesẹ pajawiri to fi mọ awọn igbesẹ kekeeke ti o le doola ẹmi.
Awọn to n pese itọju pajawiri yi kii saba jẹ awọn to kẹkọ tabi to ni imọ nipa ilera.
Imọ nipa itọju pajawiri ti wọn ni yi jẹ eleyi ti wọn kẹkọ nipa rẹ
A maa n lo ''First Aid'' lati juwe irufẹ itọju taa n ṣe fun eeyan amọ nigba miran a maa nilo lati ṣe iru itọju yi fawọn ẹranko naa.
O yatọ si itọju tawọn akọṣẹmọṣẹ onimọ ilera maa n ṣe wọn o si ṣe agbekalẹ rẹ lati rọpo itọju tawọn oṣiṣẹ ilera a maa pese.
Lọpọ igba ọgbọn ori ati awọn igbesẹ diẹ diẹ la maa n lo lati fi ṣe itọju pajawiri yi.
Idi ta fi n ṣe itọju pajawiri First Aid
Lara eredi itọju pajawiri ni awọn wọnyi wa:
- Lati doola ẹmi.Siṣe idoola ẹmi ni akọkọ idi ta fi n ṣe itọju pajawiri.Eeyan a maa nilo itọju lẹsẹkẹsẹ eyi to ṣe ṣe ko yọ ẹni naa kuro ninu ewu pipadanu ẹmi rẹ.
- Lati yọ ẹni to n gba iru itọju yi kuro lọwọ ewu.Ibi ti ẹni naa wa le jẹ aaye to lewu boya ibi ti ina ti n jo tabi to ṣe pe ile ti wo.Itọju pajawiri wa ninu pe ki a gbe iru eeyan bẹẹ kuro nibi ti ewu wa si aaye ibomiran ti ko si ewu.Bi ko ba si iru itọju bayii, iru eeyan naa le tun wa ninu ewu to ju eyi to deba tẹlẹ lọ.
- Itẹsiwaju ki ara ẹni naa ya. Bo ṣe le wu ko kere mọ,itọju pajawiri a maa jẹ atọna ki ara eeyan tete ya ju ti ẹni ti ko ri itọju kankan gba.
Awọn Igbesẹ meje to ṣe kókó ti o ba fẹ ṣe itọju pajawiri
Lẹyin alaye taa ṣe ṣaaju yii, awọn igbesẹ meje to yẹ ka tẹle ree taa ba fẹ ṣe itọju pajawiri .
- Akọkọ ni pe ka ri pe awa taa fẹ ṣe itọju yi ko si ninu ewu.Bi apẹrẹ ti a ba ri eeyan to daku lọ lẹyin ti ina mọnamọ gbe, o ṣe pataki ki a kọkọ ṣe agbeyẹwo ayika ibi ti ẹniyi wa ka si ri pe awa gaan ko si ninu ewu waya ina to le gbe wa. Lẹyin taa ba ri pe ko si ewu, igba naa lo yẹ ki a gbe igbesẹ lati ṣe itọju pajawiri fun irufẹ eeyan bẹẹ. Ma ṣe fi ara rẹ sinu ewu tori pe o fẹ doola tabi ṣe itọju fun ẹni to wa ninu ewu.
- Igbesẹ keji ni pe ki a kesi ẹni naa wo boya o le gbọ ohun wa.O ṣe pataki ki a mọ boya ẹni naa n gbọ nkan taa n sọ tabi o le da wa lohun pada. Eyi ni yoo jẹ ki a le tẹsiwajupẹlu awọn itọju tabi ibeere taa ba ni lati beere lọwọ ẹni naa. Bi eeyan ba wa labẹ ọkọ ti o danu, a gbọdọ kesi wo lati mọ ibi to fi ara pa bi apẹrẹ tabi iru ailera to ni eleyi ti yoo wulo ti a ba fẹ ṣe itọju fun ẹni naa.
- Beere tabi kesi awọn oṣiṣẹ ilera fun iranwọ. Awọn to n ṣe tọju pajawiri jẹ akọṣẹmọṣẹ. Lẹyin ti a ri pe a o si ninu ewu ati pe ẹni naa si ti da wa lohun,o ṣe pataki lati pe nọmba awọn oṣiṣẹ pajawiri pe ki wọn ṣe iranwọ fun wa. Nipa ṣiṣe bayii, wọn yoo le mọ pe eeyan kan wa to n gba itọju pajawiri to si nilo iranwọ wọn.
- Bẹrẹ si ni ṣe itọju pajawiri bayii ni iwọn bo ṣe mọọ ṣe.Ri wi pe o ṣe ayẹwo ẹni naa daada. Fọwọ pa lara lati le mọ boya ara rẹ n ṣẹjẹ. Ya ẹnu iru ẹni naa ko si gbe ori rẹ soke to ba ri wi pe ko da ọ lohun.Bi nkankan ba di wọn lọna ọfun, da wọn dubulẹ lẹgbẹ wọn ko si yọ eyikeyi nkan to ba n di wọn lọna ọfun ti ko jẹ ki wọn ribi mi daada.
- Bi wọn baa n mi daada. Ma fi akoko ṣofo pẹlu awọn igbesẹ tokan lẹyin eleyi. Ri wi pe o yi wọn sẹgbẹ kan to ba ṣe pe wọn n mi daada. Duro ti iru eeyan bẹẹ, ko si maa reti awọn oṣiṣẹ pajawiri lati wa ṣe ẹkunrẹrẹ itọju.
- CPR: Eyi jẹ ilana kan gboogi ti o fi le ran ẹni ti ko mi lọwọ lati le bẹrẹ si ni mi pada. Yoo gba pe ki o tẹ ni aya ko si fi ẹnu rẹ fẹ atẹgun sinu igba aaya ẹni naa. Bi eeyan ba ṣe eleyi ni kiakia to ko firi pe ẹni naa ko mi mọ, eleyi le ṣe iranwọ fun iru ẹni naa ki ẹmi ma ba bọ lọrun rẹ. Ẹkọ nipa CPR taa mọ si Cardiopulmonary resuscitation ṣe pataki ki eeyan to le gba iwe moyege lati le ṣe iranwọ itọju pajawiri fun eeyan.
- Lakotan ni lilo ẹrọ ita ọkan ẹni ji pada taa mọ si Defibrillator. Ẹrọ yi maa n sọ ọkan ji pada ni paapa fun awọn ti ko mi mọ. Bi a ba ni ẹrọ yi lọwọ, wọn gba wa niyanju lati maa ṣe amulo rẹ lati fi sọ ọkan ẹni ti ko mi mọ ji pada titi ti awọn oṣiṣẹ ilera tabi pajawiri yoo fi de.
Ni ipari, awọn ilana taa la kalẹ wọnyi le yatọ bi irufẹ itọju ti onitọhun ba ni lo ba ti ṣe ri. Eleyi taa kọkọ mẹnuba le ma wulo to ba ṣe pe ẹni naa n mi daada ti a si ri wi pe ko si ewu kankan to le ṣakoba nibẹ.
Ka ranti pe yiyara ṣe itọju ṣe pataki amọ ka ri wi pe awa naa ṣọ ara wa daada kuro nibi ewu.
Ajinde ara yoo maa jẹ gbogbo wa.