Ikoyi Collapsed Building: Òṣìṣẹ́ pajawiri ti bẹ̀rẹ̀ sí ní tú ilé tó wó lulẹ̀ láti dóòlà àwọn tó wà níbẹ

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti sọ pe awọn ti ri oku eeyan mẹrin gbe jade labẹ ile to wo ni Ikoyi nilu Eko.

Kọmisana ọlọpaa Hakeem Odumosu lo sọ bẹ fawọn akọroyin lasiko to ṣe abẹwo si ibi ti ile ọhun ti wo lọjọ Aje.

O ni wn si tun ribi doola ẹmi eeyan mẹta kan ninu iṣẹlẹ naa.

Amọ akọroyin BBC kan to wa nibẹ sọ pe ọkan lara awọn oṣiṣẹ alagbelebu pupa Red Cross sọ pe oku eeyan marun un lawọn toi gbe jade.

Lọwọlọwọ bayi awọn alaṣẹ ti gbegi di ibi ti ile yi ti wo tawọn ọmọ ogun ilẹ Naijiria kan si ti duro wamu nibẹ.

Titi di asiko taa n ko iroyin yi jọ, ko si ẹni to le sọ pato nkan to mu ki ile naa wo.

Igbakeji Gomina ipinlẹ Eko Femi Hamzat to fi mọ awọn alaga ijọba ibilẹ kọọkan lerekusu Eko ti yọju sibi iṣẹlẹ yi.

Ohun ta jabọ tẹlẹ

Eeyan kan ti ku ti eeyan kan mii si farapa ninu iṣẹlẹ ile alaja mọkanlelogun kan to wo lulẹ nilu Eko.

Adugbo Gerard ni Ikoyi ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Awọn eeyan tọrọ naa ṣoju wọn lasiko ti ile naa wo sọ fun akọroyin BBC pe, iye eeyan to wa labẹ ile naa nigba to wo fẹrẹ to ọgọrun tabi ju bẹẹ lọ.

Titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ko ti de ibi lati wa gbe awọn eeyan kuro labẹ ile naa.

Oṣiṣẹ kan to wa nibẹ sọ pe nkan bi ago kan ọsan ni ile naa wo ṣugbọn awọn ko ti ribi gbe ju eeyan meji jade.

''Wọn ti kọ ile naa lọ si oke. Awa fẹ ṣe iṣẹ soakaway ati digester ni ile naa ṣadede wo.

''Eeyan meji ni wọn ri yọ.Ọkan ku ninu wọn ẹnikeji wọn ti gbe lọ si ile iwosan''

Ni ọsan ọjọ Aje ti ṣe ọjọ Kini oṣu Kọkanla ni awọn eeyan bẹrẹ si ni fi fọnran fidio ati aworan ile to wo lulẹ naa sori ayelujara.

Ninu awọn fọnran fidio ta a ri, n ṣe ni eruku n sọ laala ti a si tun ri ti awọn eeyan n sa kuro nibi ile to wo yii.

Ko ti daju iye eeyan to padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ yi ati boya wọn n kọ ile naa lọwọ ni tabi o si jẹ ilegbe tawọn eeyan wa ninu rẹ.