You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Mo lè kú nítorí àpò ìyẹ̀fun kan ṣoṣo': Àwọn olùgbé Gaza sọ̀rọ̀ lórí ebi tó ń pa wọ́n, àjọ UN ní ẹgbẹ̀rún kan èèyàn lebí ti lù pa
- Author, Swaminathan Natarajan and Gaza Lifeline programme
- Role, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9
Ara n kan Gaza ni wọn fi maa n daṣa lawọn ibi ti iroyin ohun to n ṣẹlẹ niluu naa de, ṣugbọn ni bayii, ebi n pa Gaza kọja afẹnusọ, to bẹẹ ti awọn eeyan ti n ku iku ebi bayii, ati ọmọde ati agba si ni.
"Awọn ọmọ mi mejeeji lo n sunkun nitori wọn ko ti i jẹun fun ọjọ mẹrin."
Ọkunrin kan lo sọ bẹẹ ni Gaza.
"Mo kọri sibi ti wọn ti n pin ounjẹ, pẹlu ireti pe ma a ri apo iyẹfun fulawa kan gba bọ. Ṣugbọn nigba ti mo debẹ, mi o tiẹ mọ ohun ti mo le ṣe."
Baba naa lo tẹsiwaju pẹlu alaye rẹ bẹẹfun BBC News Arabic.
"Ṣe ki n maa doola awọn to fara ṣeṣe ni, abi ki n maa gbe awọn to ti ku kalẹ, tabi ki n maa ja du apo fulawa?
Mo f'Ọlọun bura, to ba jẹ ẹmi mi ni yoo gba ti maa fi ri apo fulawa kan ṣoṣo gbe lọ sile fun awọn ọmọ mi ki wọn le jẹun, maa kuku ku."
Bẹẹ ni ọkunrin naa wi.
''Ebi ọ̀pàpàǹlà àti ìpànìyàn lagbegbe ibudo ti wọn ti n pin nnkan n gbilẹ si i''
Awọn eeyan ti ebi ti fi ọwọ ba ti wọn si ti ru hangogo ti pọ, airi ounjẹ naa n gbilẹ si i, bẹẹ ni awọn eeyan n ku pupọ nitosi awọn agbegbe ti wọn ti n lọ gba ounjẹ iranlọwọ ti ajọ alaanu n pin.
Ohun to fa eyi ni pe ounjẹ ati iranwọ to n wa lati America ti ẹnu n kun lori ogun Gaza yii naa ni awọn eeyan naa gbojule.
Bakan naa ni wọn n gba ounjẹ lọwọ Gaza Humanitarian Foundation, (GHF) eyi ti wọn ni Isreali lo n ro wọn lagbara.
"O ti le ẹgbẹrun kan ọmọ Palestine ti wọn ti ku latọwọ awọn ọmọ ogun Isreali bayii, lasiko ti wọn n gbiyanju lati gba ounjẹ ni Gaza, lati ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Karun-un ni ajọ GHF ti bẹrẹ iranwọ naa."
Thameen Al-Kheetan, agbẹnusọ ajọ ẹka to n ri si ẹtọ ọmọniyan ni UN lo sọ bẹẹ.
"Nigba ti yoo fi di ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keje yii, a ti ni akọsilẹ eeyan 1,054 ti wọn pade iku nibi ti wọn ti n gbiyanju lati gba ounjẹ ni Gaza.
Wọn pa 766 ninu wọn si itosi ibi ti GHF ti n pin ounjẹ naa, ati sitosi ibi ti mọto ajọ UN ati awọn ajọ oluranlọwọ mi-in wa."
Thameen Al-Kheetan lo ṣalaye bẹẹ fun BBC World Service.
Ikú ń pọ̀ sí
Ajọ GHF bẹrẹ iranwọ rẹ nipari oṣu Karun-un, iranlọwọ ọhun ko kari ni awọn agbegbe Guusu ati Aarin Gbungbun Gaza ti wọn ti n pin in.
Ṣugbọn o ya ju rara lọ, ọsẹ mọkanla ni awọn eeyan fi wa ni Gaza ti ounjẹ kankan ko wọle, eyi waye latari Israel to tilẹkun ounjẹ mọ Gaza, ti wọn ko si ko o wọle si ilu naa.
Dokita Mohammed Abu Salmiya, Oludari ileewosan Shifa, ni Gaza City, ṣalaye pe ọmọde mọkanlelogun ( 21) lo ti ku iku ebi nigba ti wọn ko ri ounjẹ jẹ kaakiri ilu naa laaarin ọjọ mẹta.
Awọn ọmọ to din diẹ ni miliọnu kan, (900,000) ni wọn n koju ebi buruku bayii ni Gaza. Ẹgbẹrun lọna aaadọrin ninu wọn ( 70,000) lo ti ru kan eegun, bẹẹ ni Dokita naa ṣalaye fun BBC.
Bi wọn ṣe ku n lagbara si i ni, awọn to ba si ni aisan kindinrin ati awọn to ni itọ ṣuga lo tun wa ninu ewu iku naa ju bi Dokita Mohammed Abu Salmiya ṣe ṣalaye.
Apapọ iye eeyan to ti ku latari ebi bayii jẹ 101, ọgọrun-un kan ati ẹyọ kan, ọgọrin nini wọn (80) lo si jẹ ọmọde latigba ti ogun ti bẹrẹ ni 2023.
Bì wọ́n ṣe ń kojú ebi
Gbogbo eeyan pata ni Gaza lo n koju ebi lọwọ, gẹgẹ bi ajọ World Food Programme (WFP) ṣe sọ.
" Iyan ati bi awọn eeyan ṣe n ru ku eegun n le si i, ẹgbẹrun lọna aadọrun-un (90,000) awọn obinrin ati awọn ọmọde lo nilo itọju pajawiri bayii. Bi wọn ba ko eeyan mẹta jọ, ẹnikan ninu wọn ko jẹun fun ọpọ ọjọ."
Bẹẹ ni ajọ olounjẹ WFP kede ninu atẹjade ti wọn fi sita lọjọ Aiku.
"Ọna iranlọwọ ounjẹ ọfẹ yii naa ni ọpọ eeyan fi le ri ounjẹ jẹ bayii, nitori iye ti wọn n ta apo iyẹfun fulawa onikilo kan bayii ti gunke si i, o ti kọja $100 ninu awọn ọja ibilẹ paapaa."
Wọ́n tilẹ̀kùn ilé oúnjẹ pa
Loṣu Kẹta, Israel ti gbogbo ọna abawọ Gaza pa, wọn ko jẹ ki gbogbo nnkan wọle mọ, titi kan ounjẹ.
Epo rọbi, oogun ati awọn nnkan mi-in ti awọn eeyan nilo ko wọle mọ pẹlu, oṣe keji lẹyin rẹ ni wọn si bẹrẹ ikọlu ologun.
Ilẹkun ti wọn ti naa tun 'sakoba fun eto ilera awọn eeyan Gaza.
Ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ni Israeli, sọ lọjọ Aiku pe, tirela 4,400 lo ko nnkan iranwọ wọ Gaza lati Israel, bẹrẹ lati ipari oṣu Karun-un.
Wọn ni tirela 700 mi-in tun n duro, ti UN yoo gbe wọle.
Israel ni ko si ohun to n jẹ aito ounjẹ ni Gaza, o ni Hamas lo n ji awọn ounjẹ naa to si tọju wọn lati fun awọn eeyan rẹ to n jagun, tabi ki wọn ta a .
Lọjọ Aje, orilẹede mejidinlọgbọn (28 countries) titi to fi mọ United Kingdom, Canada ati France, pe fun opin ogun Gaza yii kia, pẹlu bi ijiya ṣe ti de gongo ẹ fun awọn eeyan ibẹ.
Atẹjade kan ti wọn jọ pawọpọ kọ, ṣalaye pe oore to lewu ni Israel n ṣe pẹlu iranwọ ounjẹ rẹ to n pin, wọn koro oju si bi awọn eeyan ṣe n ku si oko iwa-nnkan-jẹ.
Ṣugbọn ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ni Israel tako eyi, wọn ni ohun ti ko ri bẹẹ to si le jẹ ki Hamas maa fi oju mi-in wo awọn ni awọn orilẹede naa n sọ.
Ohun to foju han ni pe awọn akọsilẹ to n kede iku awọn eeyan to n wa ounjẹ kiri yii ko yee jade, paapaa nigba ti wọn ba wa ounjẹ ọhun lọ sibi ti GHF ti America ati Gaza n ti lẹyin ti n pin ounjẹ lati oṣu Karun-un.
Èyí tó ń ṣẹlẹ lọwọ
Lọsẹ yii, ọkọ ado oloro Israeli ti lọ si Deir al-Balah, ni Aarin Gbungbun Gaza, fun igba akọkọ, eyi to mu ibẹru ba awọn araalu.
Ni ọjọ Aiku, awọn ọmọ ogun Israeli paṣẹ kawọn eeyan kuro ni Deir al-Balah's ni Guusu ẹkun naa, ọpọ eeyan lo file wọn silẹ lọ.
Awọn araalu naa sọ fun BBC pe ko sibi ti awọn le lọ.
Ibi ti a mọ si Deir al-Balah naa lo jẹ ọkan lara awọn agbegbe diẹ ti Isreali ko ti i fọwọ ba latigba ti wọn ti bẹrẹ ogun pẹlu Hamas lati oṣu mọkalelogun ṣeyin.
Ajọ World Health Organization (WHO) to n ri si ilera lagbaaye, sọ pe Isreali kọlu awọn dukia oun ni Deir al-Balah, wọn sọ awọn eeyan si idaamu, ati pe ẹẹmẹta ni wọn kọlu ile awọn eeyan oun .
Ajọ UN sọ pe awọn ologun Israeli wọ inu ibẹ, wọn bẹrẹ si i fi ṣẹkẹsẹkẹ si awọn eeyan lọwọ, wọn bẹrẹ si i fi ọrọ wa awọn oṣiṣẹ awọn to jẹ ọkunrin lẹnu wo.
Wọn ni wọn fi awọn mẹrin si ahamọ ki wọn too pada fi mẹta silẹ .
Ileeṣẹ ologun Israeli ko ti i sọ ohunkohun lori eyi.
'Èèyàn ló wà nídìí ìsòro Gaza'
Gẹgẹ bi ajọ UN ṣe wi, awọn eeyan rẹ yoo duro ni Gaza lati da aabo bo awọn nnkan amayedẹrun pataki, titi kan ibudo kan ti wọn ti n pese omi to mọ.
"Eeyan lo wa nidii iṣoro Gaza."
Juliette Touma, Adari eto ikansiraẹni UN( Palestinian Refugee Agency) lo sọ bẹẹ.
Touma ṣalaye fun BBC pe bi wọn ṣe dina mọ UNRWA lati ma ṣiṣẹ ni Gaza mọ ko jẹ ki won le pin nnkan iranwọ to kun tirela mẹfa ti wọn fẹẹ pin.
"Laaarin ọjọ kan, awọn oṣiṣẹ wa sọ fun wa pe awọn kan daku ninu wọn nigba ti ebi n pa wọn."
O ni iya naa n jẹ awọn pẹlu.
Loṣu Kọkanla ọdun 2024, igbimọ awọn adajọ ilẹ okeere kan sọ pe òye foju han pe Olootu ijọba Isreli, Benjamin Netanyahu ati minisita eto aabo rẹ tẹlẹ, Yoav Gallant , ni ẹbọ lẹru.
Wọn ni wọn fi aisi ounje ṣe nnkan ija ogun tiwọn.
Ṣugbọn Isreli ni ko ri bẹẹ, o ni irọ gbuu ati ohun ti ko ṣee ronu ẹ ni.
Ileeṣẹ ilera Gaza sọ pe eeyan to ti ku bayii ninu ogun Gaza/Isreali yii ti ju 59,000 lọ latigba to ti bẹrẹ loṣu Kẹwaa ọdun 2023.
Awọn ilu bii UK, US ati Isreal si ti fi ontẹ agbesunmọmi lu Hamas .