Ariwo gbòde pé Sweden tí sọ ìbálòpọ̀ dì eré ìdárayá; Èsì ìjọba rèé lórí European Championship in Sex

Ijọba orileede Sweden ti fesi lori iroyin to gbode kan pe wọn ti kede ibalopọ gẹgẹ bi ere idaraya lorileede wọn.

Ninu idahun si ibeere ti BBC fi ṣọwọ si wọn, ileeṣẹ aṣoju orileede naa ni Naijiria to wa ni ilu Abuja sọ pe awọn ko fi igba kankan buwọlu tabi f'aṣẹ sii pe ki wọn ka ibalopọ gẹgẹ bi ere idaraya.

Anna Edoh to jẹ akọwe kẹta ileeṣẹ aṣoju Sweden ni Naijiria sọ pe ''a ko ka ibalopọ gẹgẹ bi ere idaraya ni Sweden ati pe ko si ileeṣẹ ijọba kankan to ni nkan ṣe pẹlu ẹka ileeṣẹ to n mojuto ere idaraya''.

O tẹsiwaju pe laipẹ yii ni ileeṣẹ kan ti orukọ rẹ n jẹ Swedish Sex Federation kọ iwe pe ka faaye gba awọn sinu ileeṣẹ to n mojuto ọrọ ere idaraya ni Sweden.

''A wọgile iwe ti wọn kọ yi nitori pe ko kaju oṣuwọn taa le fi ka wọn si ajọ ere idaraya''.

O fi kun un pe oju opo Swedishh Sex Federation tawọn eeyan ti ri iroyin nipa pe wọn sọ ibalopọ di ere idaraya yii ko ni nkankan ṣe pẹlu ijọba tabi eyikeyi ninu ajọ ere idaraya orileede naa.

Lakotan Anna ni awọn ko mọ nipa akojọpọ ibalopọ gẹgẹ bi ere idaraya.

Ohun táa ṣe ìwádìí rèé lórí ìdíje ìbálòpọ̀ "Sweden European Championship in Sex" tí wọn ni yóò wáyé lónìí

''Orilẹede Sweden ti di orileede akọkọ lagbaye ti yoo kede ibalopọ gẹgẹ bi ere idaraya.''

Akọle iroyin yii lawọn ọmọ Naijiria n mu bẹnu to si ti n ja rainrain kaakiri loju opo ayelujara.

Koda, o gbalẹ debi pe awọn ileeṣẹ iroyin abẹle mii naa ti gbe iroyin yii ti wọn si tun ti ṣalabapin rẹ gẹgẹ bi iroyin to fẹsẹ mulẹ.

BBC Yoruba foju ba iroyin yii amọ ka to le sọ boya iroyin ootọ tabi ofege ni, a ṣe awọn iwadii kan eleyi to mu awọn alaye kan lọwọ.

Ati pe, nigba ti a kan si ijọba orilẹede Sweden, wọn fesi wipe awn ko mọ nipa idije to fẹ waye ọhun.

Bakan naa wọn ni ijọba Sweden ko ni ifọwọsowọpọ pẹlu ẹnikẹnẹni lati sọ ere ibalopọ di idije.

Ẹ ba wa fọkan maa ba awọn alaye yii bọ lati le mọ boya lootọ ni idije yii yoo waye ati pe ṣe orileede Sweden naa fi aṣẹ si iru idije ibalopọ yii.

Nigba wo ni iroyin idije ibalopọ yii kọkọ lu sita?

Ẹka iwadii BBC ṣe amulo awọn irinṣẹ kọọkan lati mọ pato igba ti iroyin yii kọkọ jade sita loju opo ayelujara.

Iwadii wa si fi han pe o ti kọkọ lu sita loju opo ayelujara tudurudu.com lati nkan bi ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu kaarun.

Oju opo yii wa lara awọn oju opo ti wọn a maa pe ni "blog" ti a ko si le sọ pato awọn to n ṣe akoso rẹ.

Pupọ awọn iroyin apanilẹrin tabi eleyi to jọ mọ ẹfẹ lo maa n wa loju opo yi.

Ninu iroyin idije ibalopọ yi, oju opo naa sọ pe Sweden ni orileede akọkọ ti yoo sọ ibalopọ di ere idaraya.

O tun ni wọn sọ ọrọ yi si oju opo ajọ naa.

Wọn ko sọ boya ajọ yii ni ibaṣepọ pẹlu ijọba orileede Sweden tabi ko ni.

Nigba taa tẹsiwaju ninu apilẹkọ yi, a ri wi pe wọn sọ pe Yuroopu ni idije ibalopọ yi yoo ti waye fun ọsẹ meloo kan.

Oju opo ayelujara nikan ni wọn fi sibẹ wipe yoo ti waye ati ọjọ ti awọn eeyan le wo ni pasẹ ''Livestreaming''

Ninu iwadii wa orukọ eeyan kan ti wọn pe ni Dragan Bratych to jẹ aarẹ ẹgbẹ Swedish Federation of Sex jẹyọ.

Dragan Bratych ko ni ipasẹ kankan taa le fi ṣawari rẹ kaakiri oju opo ayelujara.

Swedish Federation of Sex ti wọn si sọ pe o jẹ aarẹ rẹ ko fi aworan rẹ kankan si oju opo wọn tabi ko tiẹ kọ ọrọ kankan sibẹ lorukọ ara rẹ.

Eyi lo mu wa kan si oju opo Swedish Federation of Sex.

Swedish Federation of Sex

Aworan taa fi ṣaaju yi ni yoo ki eeyan kaabo si oju opo Swedish Federation of Sex.

Nipasẹ iwadii wa, a ri wi pe ọdun 2022 ni wọn ṣe idasilẹ oju opo yi loṣu Kẹjọ.

Ko si ti pe ọdun kan ti wọn da silẹ ti yoo si jọba ni oṣu Kẹjọ ọdun yi.

Gbogbo alaye ti wọn kọ si oju opo yi nii ṣe pẹlu ibalopọ amọ ko si ibi kankan ti a ti ri aridaju pe ijọba Sweden tabi awọn alaṣẹ ere idaraya lọwọ si oju opo yi.

Ni iwoye wa, oju opo yi jọ bi igba pe wọn gbe kalẹ lati maa fi ṣe itankalẹ ọrọ ibalopọ ti ko bojumu taa mọ si 'Porn''.

Adirẹsi wọn ni Twitter naa n kede pe afihan ibalopọ loju opo ayelujara yoo waye ni ọjọ Kẹjọ oṣu yii.

Wọn ko fi orukọ awọn to n ṣe agbatẹru eto yi sibẹ tabi boya ijọba fọwọ si.

Ki lo de ti awọn ọmọ Naijiria fi jẹ dodo iroyin idaraya ibalopọ yii?

Ninu awọn oju opo to gbe iroyin yi taa ri ni awọn oju opo iroyin lati orileede India ati Naijiria.

Iroyin yi gbalẹ pupọ ni Naijiria tawọn eeyan si bẹrẹ si nibeere pe bawo lawọn ṣe le ribi de Sweden lati lọ kopa ninu idije ibalopọ yi.

Yala ni Twitter,Facebook tabi ni oju opo Whatsapp, awọn eeyan ṣa n ṣe alabapin iroyin yi ni ti orisi iriwisi si n jẹyọ lori iroyin kayeefi yi.

Koda awọn to fẹ japa naa n wo boya wọn le lo ọna ẹburu idije ibalopọ yi sa lọ si ilẹ okere.

Ibi ti iwadii wa fẹnu ko si

Awọn eeyan kan ti ko foju han ni wọn kan n polongo European Championship in Sex yi.

Ko ni nkankan ṣe pọ pẹlu ajọ ere idaraya ni Sweden tabi ijọba ilẹ naa.

Pẹlu ohun taa ri ni oju opo Swedish Federation of Sex ati awọn oju opo to n polongo ibalopọ to jọ mọ eyi ti ko bojumu taa mọ si ''Porn'' o ṣeeṣe ki iroyin yi jẹ eleyi ti awọn kan fẹ fi ṣe gbajuẹ tabi fi ko iroyin nipa awọn eeyan.

Idi ni pe bi eeyan ba fi le kan si oju opo yi lọjọ ti wọn lawọn yoo ṣe idije yi, o ṣeeṣe ki wọn niko san owo lati le fi wo ibalopọ alufansa tabi ki wọn si fi ọna ẹburu ko iroyin rẹ ki wọn baa le fi lu ni jibiti.

Lakotan, ikilọ ti awa ni si ẹyin ti ẹ ba fẹ ṣe ojumi yoo to lati ṣọra lori iroyin yi.

Oju wa ko ni ri ibi. Ire la o maa ri.