Sex Addiction: Mò ń ba obìnrin mẹ́fà dọ́rẹ̀ ìbálopọ̀ lẹ́ẹ̀kàn ṣoṣo pẹ̀lú aṣẹ́wó mẹ́ta láàrìn ọ̀ṣẹ̀ kan

Awọn eniyan kan ti sọ iriri wọn fun BBC lori bi awọn ko ṣe le ṣe lai ni ibalopọ ati ohun to faa.

Arabinrin Neila to sọ iriri rẹ ni Ilẹ Gẹẹsi ni oun ṣiṣẹ ni ileeṣẹ to jẹ kiki da ọkunrin ti oun si rii ti awọn eniyan yoo ṣi ẹrọ wọn lati maa wo fiimu ibalopọ (pornography) lori ẹrọ kọmputa laibikita ẹni to n wo o.

Neila ni o kọkọ dabi irira loju oun pẹlu bi awọn ọkunrin wọnyii ṣe n ṣe, ti ko si ba oun lara mu amọ oun ko fẹ fi iṣẹ naa silẹ nitori owo ti oun mu wọle ni abẹle.

Nitori naa ni oun ṣe bẹrẹ si ni wo fiimu agbelewo ibalopo nitori ki oun ma baa sọrọ lori awọn to n wo o ni ọfiisi.

Amọ ki o to pẹ, o ti di baraku fun Neila ti ko si lee sọ fun mọlẹbi rẹ kankan nitori idile to ti jade wa.

''Ojoojumọ ero ọkan mi ni bi maa ṣe de ile lati lọ wo fiimu ibalopo ti yoo mumi bẹrẹ si ni fi ọwọ kan ara mi titi ara mi yoo fi walẹ'.'

Bi o ṣe n ṣẹlẹ niyii...

Diẹdiẹ ni o ma n kọkọ bẹrẹ. Ara rẹ yoo wa lọna fun ibalopọ, nigba naa ni ẹni naa yo ṣi ẹrọ rẹ ti gbogbo ẹya ara rẹ yoo si wa lati wo o.

Gbogbo ọkan rẹ yoo wa nibẹ ki ẹni naa to bẹrẹ si ni fi ọwọ kan ara rẹ, titi ti yoo fi de opin ibalopọ naa.

''Gbogbo akoko ti yoo gba lati ṣe eyi ko ju iṣẹju marun un si mẹwaa lọ, ti ẹni naa yoo si bẹrẹ si ni wa ọna lati jẹ ki oun pẹ nidi fifi ọwọ kan ara rẹ naa''.

''Eyi tun mọ si pe oun wo fiimu ibalọpọ yii bi wakati meji si mẹta ni ojojumọ laarin ọṣẹ kan.''

''O ṣe ni laanu pe ko lee ṣe laini ibalopọ, ti ẹni naa yoo si maa wo orisirisi amọ ko ni to fun un mọ.''

''Nitori naa ẹni naa yoo bẹrẹ si ni wo eleyii to wu u, to fi mọ ibalopọ laarin akọ si abo, abo si abo, ibalopọ pẹlu ọpọlọpọ eniyan''.

''Ibẹru de fun mi nigba ti mo bẹrẹ si ni wo fiimu ibalopọ ti wọn ti n fi iya jẹ obinrin lasiko ibalopọ''.

Neila ni eleyii ko jẹ ki oun dọrẹ pẹlu ẹnikẹni nitori ko si ẹni to lee tẹ oun lọrun, gbogbo eniyan ni ko mọ ọ ṣe tabi pe ni oju rẹ.

Lẹyin naa ni Neila kuro ni ilu ibẹ ti o si kẹkọ lati maa danilẹkọ lọna ati ran awọn miran lọwọ.

Ṣe lootọ ni ibalopọ ti da baraku (Sex Addiction) fun awọn miran?

Ajọ Iṣọkan Agbaye (WHO) ti sọ di mimọ pe awọn kan wa ti wọn ko lee da ara wọn duro lai ni ibalopọ (Compulsive Sexual Behaviour Disorder).

Ajọ to n risi ọrọ eto ilera ni Ilẹ Gẹẹsi (NHS) ko ri ibalopọ to ti di baraku gẹgẹ bi aisan.

O ni aisan baraku nii se pẹlu tita ayo, oogun oloro, oti mimu (gambling, drugs, alcohol) ati oogun to n jẹ Nicotine.

Awọn ileewosan ni Ilẹ Gẹẹsi ni ẹgbẹgbẹrun awọn eniyan lo n wa si ọdọ wọn fun iranwọ ni ọdọọdun.

Ọgbọn ọdun sẹyin ni aisan aileṣe lai ni ibalopọ bẹrẹ...

Ọkunrin miran to sọ iriri rẹ, Paul ni ọgbọn ọdun ṣẹyin nigba to wa ni fasiti ni oun ti bẹrẹ.

O ni ọrẹbinrin ti wọn ni ifẹ ara wọn amọ sadede ni ifẹ rẹ ko to oun mọ ti o si bẹrẹ si ni lọ si ile asẹwo.

Lẹyin ọṣẹ diẹ ni o di baraku to si bẹrẹ si ni dọrẹ ibalopọ pẹlu bii obinrin mẹfa lẹẹkan naa, ti a si tun lọ si ọdọ awọn oni owo nọọbi bi mẹta laarin ọṣẹ.

Lasiko to n gbiyanju lati