Goodluck Jonathan: Ẹ̀ṣọ́ Ààrẹ Nàìjíría tẹ́lẹ̀ rí méjì pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe ọkọ aarẹ Naijiria tẹlẹ Goodluck Jonathan ti kagbako ijamba loju popo ni olu ilu Naijiria Abuja.

Awọn ẹsọ ọlọpaa rẹ meji ni wọn ba iṣẹlẹ naa lọ.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹwa lọwọ aarẹ ana naa n dari bọ lati papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe ni nigba ti awọn ọkọ rẹ kagbako ijamaba oju ọna.

A ko ri aridaju boya aarẹ naa wa ninu awọn ọkọ wọnyi ṣugbọn awọn ọlọpaa meji ni atẹjade lati ọdọ agbẹnusọ aarẹ fidi rẹ mulẹ pe wọn ku niu ijamba naa.

A gbọ pe awọn ọlọpaa meji miran farapa ninu ijamba yi ati pe wọn ti gbe wọn lọ si ile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.

Ẹwẹ aarẹ tẹlẹ naa ti ba mọlẹbi awọn ọlọpaa meji yi kẹdun lori iku wọn.Orukọ awọn ọlọpaa meji naa ni Ibrahim Abazi ati Yakubu Toma.

O ṣapejuwe wọn gẹgẹ bi ọlọpaa to gbajumọ iṣẹ wọn.

Ko daju boya ọkọ miran farakasa ninu ijamba ọkọ yi.