You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Suicide in Lagos: Bí iléeṣẹ́ pàjáwìrì RSS dènà ọkùnrin tó fẹ́ kó sí ''lagoon'' ní Eko ní ọjọ́ ìbí rẹ̀
Ilẹẹṣẹ pajawiri nipinlẹ Eko, Rapid Response Squad (RRS) ni awọn ti dena arakunrin ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin to fẹ ko si inu alagbalugbu omi nipinlẹ Eko.
Agbalagba ọkunrin naa ni o pe orukọ ara rẹ ni Oluwatoye Bamgboye lati ilu Oju-Ore nipinlẹ Ogun.
Awọn oṣiṣẹ RRS ni ọkunrin naa ti ṣetan lati ko si inu omi nla tan ki wọn to dena rẹ .
- Èmi "Osokomole" fúnra mi, mo ṣetán láti díje dupò Ààrẹ ní 2023 - Ayo Fayose
- Wo ohun tí Arike ṣe nínú ìjà yìí tí Màmá ESABOD ń wọ́ ọ nílẹ̀ tuurutu tèpètèpè?
- BBC ṣé ìwádìí lórí fídíò ajínigbé nínú igbó tó gbòde, àbọ̀ wà rèé lórí rẹ̀
- NIMC mú ìlérí ìjọba Nàìjíría ṣẹ, àwọn nọ́mbà fóònù tí kò so mọ́ NIN kò lè pè síta
- Láyé! Ẹ ò lè rí mi mọ́ nínú fíìmù Yorùbá bí ìgbà ayé Saworoide - Araparegangan
Arakunrin Bamgboye ni idojukọ ti oun koju lo mu ki oun ta ile, ilẹ ati ọkọ ti oun ni.
''Pẹlu rẹ naa ko si ọna abayọ si ipenija ton doju kọ naa.
Bakan naa lo gba owo ẹyawo, ti iṣoro naa ko si dopin lẹyin gbogbo igbiyanju naa.
O tun ṣalaye wipe oun ri iṣẹ ti oun si ti ṣetan lati lọ bẹrẹ iṣẹ ni ọjọ iwọle, ki wọn to pe oun ni ọjọ to yẹ ko bẹrẹ pe wọn ti fun ẹlomiran ni iṣẹ naa.
''Nitori oni jẹ ọjọ ibi mi, mo ti ṣetan lati pari aye mi loni, eru yii ti wuwo ju lọ, to si n da ọgbẹ ọkan fun ni lapọju''.
''Iyawo mi ti kọ mi silẹ nitori ipenija ti mo n koju ati gbogbo ohun ti mo ṣe alaini.
Nibayii, ileeṣẹ pajawiri naa ti gbe e lọ si agọ ọlọpaa to wa ni agọ ọlọpaa Adekunle nibi ti igbiyanju ti n lọ lọwọ lati kan si awọn mọlẹbi rẹ.