Ká ní èmi ni ààrẹ, ìgbésẹ̀ tí màá gbé rèé lórí fuel subsidy - Peter Obi

Oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oselu Labour Party, Peter Obi ti sọrọ lori bi ijọba ṣe yọ owo iranwọ epo bẹntiroo.

Eyi n waye lẹyin ọsẹ kan ti aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ burawọle fun, Bola Tinubu sọ wi pe ko si iranwọ epo bẹntiroo mọ.

Peter Obi ni kani oun ni ọna ti yoo gba rọ awọn araalu lọrun ni oun yoo gba lati yọ iranwọ epo bẹntiroo naa.

O ni kaka ki oun gba ọna ti ijọba to wa lode ni gba nipa yiyọ ni tipatipa, ohun ti oun yoo ṣe ni lati fi awọn eto igbayegbadun sibẹ ki oun to gbe iru igbesẹ naa.

''Awọn eniyan kan n lo subsidy ọhun lati ko owo jẹ nitori a ko lo iye jaala epo bẹntiroo ti wọn n sọ pe a n lo ni ojumọ.''

Peter Obi ṣapejuwe ohun ti oun yoo ṣe nipa ṣiṣe akawe ẹni ti oun jẹ irora ẹyin, ti o si lọ ba dokita pe ki wọn ba oun yọ ẹyin to n dun un.

O ni oun ti dokita naa yoo ṣe ni lati fun ẹni naa ni oogun ti ko ni jẹ ki o mọ irora ni agbegbe ti wọn ti fẹ yọ ẹyin naa.

‘’Kii ṣe nkankan naa pẹlu fifi tipatipa yọ ẹyin naa, irora ti awọn eniyan yoo la kọja yoo kọja bi o ṣe yẹ.’’

''Ka ni emi ni, ọna ti dokita yoo gba ni emi naa yoo gba, mi o ni jẹ ki wọn koju irora yiyọ ẹyin naa ni dandan nitori inira ti yoo waye fun awọn araalu.''

''Ẹ ranti pe nigba ti ijọba Jonathan fẹ yọ subsidy, wọn gbe awọn ohun eto iranwọ bii Sure-P lede fun awọn eniyan ati bẹẹ lọ.''

Peter Obi ni iṣoro Naijiria ni pe awọn adari a sọ fun awọn araalu pe ki wọn maa jiya lọ, ki wọn si tun fi ara wọn rubọ fun ọjọ iwaju ti yoo dara, amọ ni ọjọ iwaju naa, nise ni nkan n bajẹ sii.