You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nítorí owó Naira tuntun, gbajúmọ̀ òṣèré, Simisola Gold wọ gbaga ICPC
Ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ ati iwa ibajẹ gbogbo lorilẹede Naijiria, ICPC ti fi panpẹ ofin mu oṣere tiata kan, Ọmọsẹyin Oluwadarasimi Esther ti ọpọ mọ si Simisọla Gold.
Ajọ ICPC ni ọwọ awọn tẹ Simisọla Gold lori bi o ṣe n ta owo Naira tuntun lori ayelujara.
Atẹjade kan ti alukoro ajọ ICPC, Azuka Ogugua fi sita nilu Abuja sọ pe ọwọ tẹ afurasi naa nibi to ti n lo anfani ọwọngogo owo naira tuntun naa ni igboro lati maa fi ṣowo ọja okunkun lori ayelujara.
Atẹjade naa sọ pe ajọ ICPC nigbagbọ pe ohun atawọn oṣiṣẹ kan lẹka banki lorilẹede Naijiria ni wọn jọ n ṣe apade alude rẹ.
Simisọla Gold wa ni ahamọ ajọ ICPC bayii nibi ti wọn ni o ti n ran awọn agbofinro ajọ ọhun lọwọ lọna ati wadi gbogbo awọn to n fi owo tuntun naa ṣe owo