You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé ó yẹ kí ìjọba fi òfin de 'Prank' ṣíṣe?
- Author, Yusuf Akinpelu
- Role, Journalist, West Africa
Bi ọwọ ọlọpaa se tẹ gbajugbaja adẹrinposonu oni 'Prank', Trinity Guy, ẹni ti wọn ni ko wa wi tẹnu rẹ lori fọnran kan to fi sori ayelujara ninu eyi to ti n ni ki ọmọdebinrin kan maa ṣe apejuwe nnkan ọmọkunrin rẹ to ni o ri,
Ọrọ yii lo ti fa ọpọlọpọ awuyewuye pe boye ki ijọba fi ofin le lẹ fun awọn adẹrinposonu paapa awọn onitanjẹ lorilẹede Naijiria.
Trinity, ẹni ti Ile ẹjọ Majistreti to n gbọ ẹsun ti ileeṣẹ ọlọpaa fi kan ni ki wọn fi pamọ sọgba ẹwọn titi di igbẹjọ yoo fi wa sopin.
Tani Trinity Guy?
Abdullahi Maruff Adisa, ẹni ti ọpọ mọ si Trinity Guy lo jẹ adẹrinposonu to ma mu awọn eeyan sere pẹlu itanjẹ, to si tun jẹ osere tiata to n gbe niluu Ibadan, apa guusu iwọ oorun orilẹede Naijira.
Ibẹta ni Maruff Adisa, to si jẹ pe eyi lo mu ko ma jẹ ọrukọ 'Trinity', to tumọ si nnkan mẹta.
Trinity, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, lo kọkọ fi orin kikọ bẹrẹ lọdun 2016 pẹlu ọkan lara awọn ibẹta rẹ to jẹ ọkunrin, ti wọn si n jẹ 'Trinity Guyz'. O ti kopa ninu sinima ati pe sinima meji ni yoo ti ọwọ rẹ jade sita laipẹ yii.
O se awọn isẹ miiran bi ẹsọ oju omi ati olukọ ni ile itura gẹgẹ bi olukọni ere idaraya ni bi to ni oun ti pinnu lati bẹrẹ yiya fọnran lẹyin o to mu ọrẹ sere lasiko itankalẹ Korona lọdun 2020.
Ki ni gan an fọnran itanjẹ Trinity dale lori.?
O bẹrẹ lati maa se fọnran itanjẹ rẹ pẹlu yiyọ irun ori awọn obinrin ni ita gbangba, ti yoo si pada lọ tọrọ aforigin lọwọ, ti yoo si tun fun awọn eeyan yii lowo nigba miiran. Awọn fọnran rẹ lo ti ni ọpọlọpọ milọnu lori ayelujare .
Nigba miiran, ninu asọ funfun rẹ to ma n wọ, yoo dibọ gẹgẹ bi alaganni eeyan tabi ko dibọ gẹgẹ bi adigunjale ti wọn le lọ. O ti dibọ gẹgẹ bi eeyan to fẹran ọkunrin, to si dinju si awọn ọkunrin ẹgbẹ rẹ.
Koda awọn tọkọtaya mii ma n pe lati ba wọn se ayẹwọ fun awọn ololufẹ wọn lati mọ boya o nifẹ wọn.
O sọ fun BBC News Yoruba pe ọpọ igba ni ọwọ iya ti ba oun, ti oun si farapa ni ọpọ igba. O ni oun lo ọjọ mẹta ni ile wosan lẹyin ti ọwọ iya oun. O ni lilu ti wọn n na oun n fun oun ni agbara si ni.
Fọnran Trinity lo jẹ abala meji lọdọ awọn ololufẹ rẹ, bi awọn kan se n sọpe ere egele Trinity ti pọju ati pe o si n sẹrubani pupọ ni awọn miiran ni o jẹ nnkan ti awọn fẹran si pupọ.
Nigba miiran, o ma n fi bi o se n tọrọ asẹ lọwọ awọn eeyan to ba tanjẹ, ko to gbe awọn rẹ sori ayelujara Facebook to ni alatilẹyin to to milọnu mẹta.
Ki lo de to fi dero ahamọ?
Fọnran kan to gbe sori ayelujara, eyi to ti n ni ki ọmọdebinrin kan maa ṣe apejuwe nnkan ọmọkunrin rẹ to ni o ri.
Fọnran ọhun ti ko si lori opo ayelujara rẹ mọ lo safihan bi Trinity se n dunkoko lati na ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹwaa naa to ba kọ lati se apejuwe nnkan ọmọkunrin rẹ.
Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Oyo fi atẹjade sita pe awọn ti bẹrẹ ifọrọwerọ pẹlu Trinity lori fọnran ti wọn sapejuwe gẹgẹ bi ohun to ku diẹ kato. Lẹyin ọjọ meji ni wọn gbe lọ si ile ẹjọ.
Ẹjọ wo lo wa niwaju Trinity?
Ile ẹjọ Majistreti to n gbọ ẹsun ti ileeṣẹ ọlọpaa fi kan alawade ori ayelujara niluu Ibadan gbọ ẹsun lilẹdiapupọ lati wu iwa ika ati awọn ẹsun miiran
Wọn sọ fun ileẹjọ pe fọnran naa, to jade ninu osu kejila ọdun to kọja ni o da le lori fifi ilọkulọ lọ ọmọde,
Trinity lo di ero ahamọ pẹlu awọn obi ọmọ ọdun mẹwaa naa. Igbẹjọ yoo tẹsiwaju lọjo kọkanla oṣu keje.
Awọn obi ni wọn fi si ahamọ lori pe wọn lẹdi apupọ pẹlu Trinity lati gbe fọnran naa jade sori ayelujara.
Njẹ se awọn se awọn oni fọnran itajẹ ko ma se ju arawọn lọ?
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Olumuyiwa Adejobi, loju opo ayelujara rẹ, fi ọrọ sita nipa fidio kan ti Trinity Guy ṣe to si ni o yẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa mu Trinity Guy.
Nigba to ya, o fi atẹjade kan sita lati sọrọ nipa gbogbo fọnran awada lori ayelujara pe pupọ wọn ni ẹnu ko ka mọ, ti wọn fi ẹmi awọn we ewu. O rọ awọn oni alawada lati se awada ni ọna to ba ofin mu tabi ki wọn yago fun.