You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
JAMB kéde ọjọ́ tuntun fun ìdánwò UTME, MOCK
Ajọ to n risi eto idanwo lati wọ fasiti lorilẹede Naijiria JAMB ti kede ọjọ tuntun fun idawo UTME fun ọdun 2023.
Bakan naa ni wọn fikun pe awọn ti kede ọjọ tuntun fun idanwo igbaradi Mock pẹlu.
JAMB kede igbesẹ naa ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi ransẹ sawọn akọroyin pe idanwo ọhun to yẹ ko waye lọjọ kọkandinlọgbọn ni yoo wa waye lọjọ kẹdọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2023
Agbẹnusọ ajọ, Fabian Benjamin lo kede igbesẹ tuntun ọhun lori ayelujara.
Benjamin ni idi ti awọn fi gbe igbesẹ lati sun ọjọ idanwo naa siwaju ni lati ni anfani lati se awọn nnkan to yẹ ko jẹ sise fun idanwo naa.
O fẹkun pe igbesẹ naa yoo fun ọpọlọpọ fasiti ni anfani igbaradi fun awọn akẹkọọ tuntun.
“Igbesẹ yii, gbogbo akẹkọọ ni yoo ni anfani lati kopa ninu eto idanwo naa,”
Benjamin ni idanwo igbaradi yoo waye lọjọ kejidinlogun oṣu kẹrin ọdun 2023.
Saaju ni ajọ Jamb ti kọkọ se igbaradi idanwo fun awọn akẹkọọ kakiri orilẹede ni ọgbọnjọ oṣu to kọja.
“A gbe igbesẹ yii lati fun awọn akẹkọọ ti wọn ko ni anfani lati kopa ninu idanwo ti tẹlẹ lati tun se.
“Idanwo yiii yo wa waye lọjọ kejidinlogun oṣu kẹrin, ọdun 2023.”