You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ gbà wá o! Ìyan, èbi àti ìṣẹ́ ń lù wá pa púpọ̀ ní North Korea
Awọn ara orilẹede North Korea ti ke gbajare jade pe iyan ati iṣẹ ti gbẹmi ọpọ eniyan lorilẹede naa.
Eyi n waye lasiko ti ọwọngogo ati aisi ounjẹ gbode nibẹ.
Eleyii ni wọn lo ti gbẹmi ọpọ eniyan to wa ni igberiko nitori ko si ounjẹ fun wọn lati jẹ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ṣe pẹlu BBC, ni awọn eniyan yii ti sọ iriri wọn.
"A n ri oku awọn onibara ti ebi lu pa loju popo"
Orilẹede North Korea jẹ ọkan lara awọn orilẹede lagbaye ti wọn da wa lati bi ọdun 1990, ti wọn ko si ba ẹnikẹni sẹ.
Awọn araalu ni awọn to n tọrọ bara ni wọn n ri oku wọn ni opopona, ti ko si si ounjẹ ni awọn ile itaja.
Arabinrin kan ni ki awọn ọmọ oun ba le jẹun, niise ni oun ma n fun wọn ni ounjẹ ti o yẹ ki oun jẹ.
Bakan naa ni arakunrin miran to ba BBC sọrọ ni awọn eniyan marun un lo ti ku ni abule wọn nitori iyan to gbode naa.
Ni ile miran, arabinrin to wa nibẹ n ṣe aisan nitori airi ounjẹ jẹ, ti awọn ọmọ rẹ ati awọn mọlẹbi rẹ naa ko si ri ounjẹ jẹ.
Iroyin o ṣeeṣe ko jẹ pe o ti pẹ diẹ ti iyan, iṣẹ ati aisi ounjẹ ti gbode ni orilẹede North -Korea.