You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Male infertility: Àwọn ìdí márùn-ún tó ṣe sọ̀ro fún ọkùnrin láti fún obìnrin lóyún láyé òde òní
Iye atọ to maa n jade lara ọkunrin ti dinkun pẹlu ida mọkanlelaadọta lati nnkan bii aadọta ọdun sẹyin.
Eyii jẹ ọkan lara awọn esi iwadii lati ile ẹkọ Hebrew University of Jerusalem ni Israel ati Mount Sinai School of Medicine, nilẹ Amẹrika.
Awọn onimọ ijinlẹ sayẹnsi naa sọ pe eroja inu atọ awọn ọkunrin ni nnkan bii ọdun 1970 pọ ju iye eroja atọ awọn ọkunrin laye ode oni lọ.
Wọn ni “Ohun to ya wa lẹnu ju ti a ri ni pe bi awọn eroja inu atọ naa ṣe n rin ti dinku si ju ti atijọ lọ, to n tumọ si pe anfani ati fun obinrin loyun ti dinku ju ti atijọ lọ.”
Esi iwadii yii ti n kọ awọn onimọ ijinlẹ lominu.
Eduardo Miranda, to jẹ onimọ ijinlẹ ti ẹka imọ Andrology ni Brazilian Society of Urology sọ pe “Bi ọrọ yii ṣe n lọ n kọ wa lominu nitori a ko mọ ibi ti yoo yọri si.”
Wayii o, awọn onimọ ijinlẹ ti kede awọn nnkan marun un yii gẹgẹ bii eyii to maa n mu ko lera fun ọkunrin lati fun iyawo rẹ loyun.
1. Ara sisan
Miranda sọ pe, awọn ọkunrin to ba sanra ju maa n ni ọra pupọ lagbegbe nnkan ọmọkunrin wọn.
Awọn ọra wọnyii le ṣakoba fun ‘spermatozoa’ eyii to jẹ ara eroja inu atọ to n di ọmọ ninu obinrin.
Wọn ni ti ọkunrin ba sanra ju, o le ṣakoba fun koropọn rẹ, eyii ti yoo maa gbona, o si lewu.
Ajọ WHO ni nnkan bii ida mọkandinlogoji ọkunrin lo sanra, ti ida mọkanla si sanra lasanju, eyii to n ṣakoba fun ‘spermatozoa’ wọn.
2. Lilo egboogi oloro
Cocaine, igbo, siga, ọti atawọn egboogi mii ni awoọn onimọ ti sọ pe o le ṣakoba fun nnkan ọmọkunrin.
Miranda ni awọn nnkan wọnyii maa n ṣakoba fun awọn eroja to n pese atọ ninu agọ ara ọkunrin.
Bẹẹ si ni lara awọn oogun naa maa n ṣakoba fun koropọn ọmọkunrin.
Wọn ni o le jẹ ki koropọn kere, ti awọn eroja inu atọ ko si ni le gbera daadaa, eyii ti wọn n pe “azoospermia.”
3. Arun ibalopọ (STI)
Awọn aisan bii ‘chlamydia’ ati ‘gonorrhoea’ maa n gbogun ti igbiyanju ọkunrin lati fun obinrin loyun.
Ajọ WHO sọ pe lọdun 2020 nikan, miliọnu mọkandinlaadọfa eeyan tuntun lo lugbadi arun chlamydia nigba ti miliọnu mejilelọgọrin eeyan tuntun fara kasa gonorrhoea kaakiri agbaye.
4. Gbigbe ẹrọ kọmputa alagbeka (laptop) sori itan
Wọn ni ṣiṣe eyii le se ewu fun atọ ọmọkunrin, iyẹn ti ẹrọ kọmouta naa ba ti gbona ju ni itan ti eeyan gbe si lati ṣiṣẹ.
Yatọ si kọmputa to n gbona lori itan ọkunrin, awọn onimọ tun sọ pe awọn nnkan mii bii wiwẹ ninu omi to gbona le ṣakoba fun atọ ọmọkunrin.
5. Endocrine disruptors
Laipẹ yii ni iwadii kan ṣẹṣẹ fi han pe awọn nnkan to n fa idọti oju afẹfẹ le ṣakoba fun nnkan ọmọkunrin.
Awọn ọna abayọ
Gbigbe igbe aye ọtun le ran ọmọkunrin lọwọ gẹgẹ bii iwadii ijinlẹ kan ṣe sọ.
Lara awọn igbeaye ọtun naa ni igbiyanju lati di ara sisan ku, yiyago fun awọn nnkan bi siga mimu, ọti mimu ati egboogi oloro lilo.
Ti tọkọ-taya ba gbiyanju lati loyun amọ ti igbiyanju wọn ko so eso rere, wọn ni irufẹ tọkọ-tya bẹẹ le gbiyanjuu awọn ọna mii bii “vitro fertilisation” ati bẹẹ lọ.