Àwọn agbébọn yawọ ilé ìjọ́sìn, palẹ̀mọ́ olùjọ́sìn 25 ni Katsina

Awọn afurasi agbebọn pẹlu orisirisi ìbọn nla ṣe kọlu si ile jọsin New Life For All ni ìjọba ibilẹ Kankara nipinlẹ Katsina, ti wọn si palẹmọ awọn olujọsin mẹdọgbọn.

Osojumikoro to ba ileeṣẹ iroyin ẹsẹ kuku sọrọ ni pẹlu okada ni awọn agbebọn ọhun yawọ agbegbe Dan Tsauni Gidam Haruna lowurọ ọjọ Aiku nigba ti awọn olujọsin pe jọ lati gba adura.

Amugbalẹgbẹ gomina Gomina ipinlẹ Katsina, Aminu Masari lori ọrọ Kristẹni Ishaya Jurau fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Gẹgẹ bii Jurau ṣe sọ, awọn ẹlẹsọ abo ti wa lori ọrọ naa lati dola awọn eeyan lọwọ awọn ajinigbe.

"Wọn ji awọn eeyan wa, ti wọn ṣe Pasitọ ṣe nigba ti wọn ṣe isin lọwọ ni ago mẹwaa arọ."

Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ?

Ileeṣẹ ọlọpaa Katsina naa ti fìdí iṣẹlẹ naa mulẹ sugbọn atẹjade tí wọn fi lede ni eeyan meje ni awọn olujọsin ti awọn agbebọn jigbe.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, SP Gambo Isah ni awọn agbebọn naa ṣe kọlu ti wọn si tun yín ìbọn fun Pasitọ kan ni apa rẹ.

"Kete ti a gbọ sì iṣẹlẹ naa ni ileeṣẹ suure lọ sí agbegbe naa sugbọn awọn agbebọn tí lọ kí wọn to de pẹlu awọn eeyan ìjọ naa 

"Pasitọ to ṣe lese tí wa nile wosan Kankara níbi to tí n gba itọju. Akitiyan ati igbinyanju tí bẹrẹ lati dola ẹmi awọn eniyan naa."