Èmi ni mo gbé Buhari dé ipò Ààrẹ, bí kìí bá ṣe èmi ní... - Tinubu

Oludije s’ipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ti sọ ọ sita gbangba wi pe bi kii ba ṣe oun ni, Aarẹ Mohammadu Buhari ko ba ṣi wa l’ẹni to n gbe apoti ibo kaakiri titi di asiko yii.

Aṣiwaju Bọla Tinubu tun sọ pe nipasẹ oun naa ni Ọmọọba Dapọ Abiọdun fi de ipo gomina, nitori pe oun loun ṣatilẹyin fun un.

Ilu Abẹokuta ni Aṣiwaju Tinubu ti sọrọ naa sita gbangba lakoko to n ṣabẹwo s’awọn aṣoju ẹgbẹ naa ti yoo dibo l’ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to n bọ, iyẹn ọjọ kẹfa, oṣu kẹfa.

Bi mo ṣe mu Osinbajo naa wọle saarin wa ree

Ninu ọrọ Tinubu, o sọ pe “latigba ti a ti bẹrẹ ni AD, ACN, a gbe de ori APC to jẹ oogun ẹfọri. A fẹ ṣe nigba yẹn. Emi ree ti mo n sọ fun un yin laaarin aye mi ati Ọlọrun alagbara, Buhari sọ pe ki n wa ṣe igbakeji oun.

O ni nitori akọkọ toun jade, oun gbe igbakeji fun Okhadigbo, wọn ko dibo f’oun. Ẹlẹẹkeji, oun tun gbe e fun Ibo miran, Umesioke to jẹ abẹnugọn, wọn ko dibo foun.

“O loun wa ri i pe toun ba lọ mu Pope wa, wọn ko ni dibo f’oun, ṣugbọn Bọla Tinubu, o ni gomina mẹfa, o ko ti i padanu ibo kankan ri.

Gbogbo nnkan ti a si n wo gẹgẹ bi odiwọn nigba yẹn, ko ṣ’ẹnu re fun wa. O ni ka jọ gbe apoti, mo wa sọ fun un pe ko tii to asiko, ko jẹ ka to ẹgbẹ yii tan.

“Igba ti a to o tan, ti a mu awọn PDP wọle, Saraki rii pe awọn PDP ko ni ri kankan ti Buhari ba jẹ aarẹ, ti emi jẹ igbakeji rẹ, oun ko le ri aarẹ ile igbimọ aṣofin ṣe, nitori pe awa mẹtẹẹta ko lẹ jẹ musulumi.

“Bi wọn ṣe bẹrẹ si polongo madaru niyẹn. Mo wa pe wọn pe mo ni b'eeyan jẹ Kristẹni, maa fa a kalẹ, tori pe ẹgbẹ yii ko gbọdọ fọ, a ko si gbọdọ kuna, bi mo ṣe mu ẹni to jẹ ọmọ yin (Ọṣinbajo) silẹ niyẹn. Otitọ ọrọ ibẹ lẹ gbọ yẹn.

“Orukọ mẹta ni wọn sọ pe ki n mu wa, orukọ Yẹmi wa lakọkọ, orukọ Wale Ẹdun wa ni ipo keji, orukọ Yẹmi Ọṣinbajo wa ni ipo kẹta. Mo wa sọ pe bi mo ba mu orukọ mẹta wa, mo ti ṣilẹkun fun ole niyẹn, ẹ tun le fi orukọ kẹrin kun un.

Aṣiri pọ ti Tinubu tu sita

“Mo sọ pe orukọ kan ṣoṣo ni maa fun un yin, nitori pe emi ni mo fẹẹ juwọ silẹ. Awọn ogbontagi aafa wa ba mi lati sọrọ, ṣugbọn mo sọ pe orukọ kan ṣoṣo ni maa fi silẹ, Buhari naa tun fi ẹsẹ ara rẹ rin wa, o si loun gba ki n fi orukọ kan silẹ, bi mo ṣe fi orukọ Yẹmi Ọṣinbajo silẹ niyẹn. Otitọ ọrọ ibẹ niyẹn.

“Ẹ ko ti i gbọ ri lẹnu mi lati ibi kankan, akọkọ ree ti maa sọ jade. Wi pe ko ma daru, ko ma bajẹ, ki orileede Yoruba le debẹ, ka gun oke diẹ.

Ọjọ ti a ti n ba a bọ, nitori bẹẹ ni mo ṣe ṣe e, a ko ṣe ọta ara wa di asiko yii. Mo kan sọ pe o ti to asiko.

“To ba jẹ ti iwe, mo kawe, to ba si jẹ ti ọrọ agba ni, emi ni ẹgbọn.

Mo ti n sin yin bọ, ọjọ ti pẹ, ẹ gbe ipo yii wa, emi lo kan. O ti le l’ọdun mẹẹdọgbọn ti mo ti n sin wọn bọ.” “O ti de oju ẹ bayii, a ko nilo lati kọ orin Ogunde mọ. Ọrọ orin kọ, ọrọ ẹtọ ni, o ti to asiko naa ti a maa gba a.

Agbara yii ki i ṣe fun oke ọya nikan, ti ko ba si emi ti mo duro niwaju yin yii, ti mo leri ogun, ti mo sọ pe ki Buhari niṣo ka maa ba a lọ, ko le di aarẹ.

“O ṣe akọkọ, o lulẹ, o ṣe ẹẹkeji, o lulẹ, o tun ṣe ẹẹkẹta, o lulẹ.

O si tun sọ ọ lori tẹlifiṣan wi pe laye, oun ko du ipo kankan mọ. Mo lọ ba a nile ẹ, mo si ni ọrọ ẹkun kọ leleyi, maa duro tiẹ, wa a si wọle.

Ohun kan ni wi pe o ko ni fi ọrọ orileede Yoruba ṣere.

“Bujari gba nigba yẹn, a si ṣe e titi to fi debẹ, latigba to ti debẹ, mi o gba minisita, mi o gba kọntiraati, mi o tọrọ ọbẹ, mi o tọrọ gaari, mi o tọrọ Fura lọwọ ẹ, mi o si ya owo nibẹ. Mo wa ni lọtẹ yi o, Yoruba lo kan.

Ti a ba si wo Yoruba naa, emi lo kan. Apemọra-ẹni la n pe temidire. Emi naa fẹẹ ṣe aarẹ, mi o fẹ ki wọn pa mi mọ itan, mo fẹẹ wa lara itan ni. “Ohun ti mo wa ba a yin fun ni pe emi ni ki ẹ duro ti, ẹyin aṣoju oṣelu to wa ni ibi, Ọlọrun ko ni ṣe ọrọ yin ni ewu o. Ẹ ma fi egbo yii ṣe egbo ile o, gbogbo wa ni ọmọ ile o.” Bakan naa nigba to n sọrọ nipa bi Gomina Abiọdun ṣe wọle, Tinubu sọ pe “Eleyi to jokoo lẹyin mi yii, Dapọ, ṣe o wa le sọ pe oun le jade gomina bi ki i ba a ṣe emi? Ṣebi a jọ wa ni papa iṣere lọjọ yẹn kọ ni?

Wọn ko fẹẹ gbe asia egbẹ fun un, emi ti mo gbe e silẹ ree, ẹ lọ tun fidio naa wo.