You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
''Alárùn ọpọlọ ni mí kódà Aro ni mo ti ń gba ìtọ́jú,'' Portable sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí ọlọ́pàá kéde pé àwọn ń wá a
Akọrin takasufe Abeeb Okikiola Badmus ọmọ Olalomi ti ọpọ mọ si Portable ti sọrọ soke lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun kede wi pe awọn n wa a.
Portbale to sọrọ ninu fọnran kan to fi lede loju opo Instagram rẹ sọ pe alarun ọpọlọ loun.
O sọ ninu fidio naa wi pe oun si n gba itọju nile iwosan ijọba apapọ ti wọn ti n tọju awọn to larun ọpọlọ ni Aro niluu Abeokuta.
Portable ni ki wọn fi oun silẹ tori alarun ọpọlọ loun, atipe ọmọ ijọba loun jẹ gẹgẹ bii alarun ọpọlọ.
Olorin takasufee naa kepe awọn ọmọ Naijiria wi pe ki wọn ran oun lọwọ lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun kede pe awọn n wa a.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn n wa Portable tori oun atawọn ọmọlẹyin rẹ ṣe ikọlu sawọn oṣiṣẹ ajọ ipinlẹ Ogun to n ri si aato ilu nigba ti wọn fẹ ti ile ọti rẹ pa lagbege Oke-Osa, Tigbo Ilu Ota.
Ileeṣẹ ọlọpaa tun sọ pe Portable atawọn ọmọlẹyin lo nnkan ija oloro lati kọlu awọn oṣiṣẹ ijọba naa.
Lẹyin naa lawọn ọlọpaa mu awọn ọmọlẹyin rẹ mẹsan an ti wọn si foju bale ẹjọ, amọ, Portble fun rẹ na papa bora lati igba naa.
Ṣugbọn Portable sọ ninu fidio to ṣe lọjọ Iṣẹgun pe alarun ọpọlọ loun, koda, oun n loogun tawọn to larun ọpọlọ maa n lo.
''Ẹ le lọ beere nipa mi nile iwosan awọn alarun ọlọpọlọ to wa ni Aro, koda, mo ni kaadi ile iwosan naa gẹgẹ bii ọkan lara awọn to n gba itọju nibẹ.
Ọmọ ilu Abeokuta ni mi, mi kii ṣe ole, mo maa n ṣe iranwọ fawọn eeyan to wa layika mi.
Iṣẹ orin kikọ ni mo n ṣe, mi o payan, mi o si da wahala silẹ lawujọ.
Ẹyin ololufẹ mi, mi o foju di ijọba o, mo bẹru ijọba lo jẹ ki n sa tori lẹyin Ọlọrun ijọba lo tun kan,'' Portable lo sọ bẹẹ.
Portable rawọ ẹbẹ sawọn ololufẹ lati ran an lọwọ tori inu inira loun wa bayii, ati pe lati igba ti wọn ti bi oun loun ti wa ninu inira.
Ọlọ́pàá fi àwòrán 'Portable' léde pé àwọn ń wá a, ìdí rèé
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti kéde gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé nnì, Habeeb Okikiola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Portable gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n ń wá.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ọlọ́pàá Ogun, Omolola Odutola fi ojú òpó X iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ogun sọ pé ohun tí àwọn ń wá Portable fún kò ṣẹ̀yìn ìkọlù tó ṣe sáwọn òṣìṣẹ́ ọba kan lásìkò tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ oòjọ́ wọn.
Odutola nínú àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé ní ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kejì, ọdún 2025 ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ àjọ tó ń rí sí ilé kíkọ́ àti ààtò ìlú ní ìpínlẹ̀ Ogun tẹ̀ka ìlú Ota ń ṣiṣẹ́ oòjọ́ wọn.
Ó sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ náà – TPL Onabanjo Abidemi, TPL Raymond Lateef, TPL Ridwan Oyero Akinlesi – lọ ṣiṣẹ́ ní agbègbè Oke-Osa, Tigbo ní ìlú Ota.
Lásìkò náà, àwọn òṣìṣẹ́ náà rí bàbá àgbàlagbà kan, ẹni tí wọ́n padà mọ̀ pé bàbá Portable ni, ní ilé ọtí kan Odogwu Bar, ilé ọtí tí wọ́n ní Portable ló ni.
Nígbà tí àwọn èèyàn náà júwe ara wọn fún bàbá Portable, tí wọ́n sì bèèrè ìwé àṣẹ tí wan fi kọ́ ilé ọtí náà, bàbá Portable sọ fún wọn pé ọmọ òun tó ni ibẹ̀ kò sí nílé.
Àmọ́ kò pẹ́ púpọ̀ ni Portable yọjú pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀ mẹ́sàn-án mìíràn lẹ́yìn pẹ̀lú ohun ìjà olóró lọ́wọ́, tí wọ́n sì ṣe ìkọlù sáwọn òṣìṣẹ́ náà.
Àwọn òṣìṣẹ́ náà farapa yánnayànna ṣùgbọ́n tí wọ́n móríbọ́, tí wọ́n sì sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.
Odutola fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé èyí ló mú àwọn èèyàn lọ fi ẹjọ́ sùn ní àga ọlọ́pàá tó wà ní Ota, ti ẹ̀ka tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn sì ti dá sí ọ̀rọ̀ náà báyìí.
Àwọn ọlọ́pàá rí àwọn èèyàn Portable mẹ́sàn-án mú, tí Portable sì na pápá bora láti ìgbà náà.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá sọ pé ọ̀pọ̀ ìwé ìpè ni àwọn ti fi ránṣẹ́ sí Portable láti yọjú sí oríkò iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó wà ní Eleweran, Abeokuta àmọ́ tó kọ̀ láti yọjú tí kò sì rán agbẹjọ́rò rẹ̀ sí àwọn.
Ó ní ìdí tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi gba ilé ẹjọ́ lọ láti gba àṣẹ láti kéde Portable bí i ẹni tí wọ́n ń wá.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá wá pàrọwà sáwọn èèyàn láti ran àwọn lọ́wọ́ láti ṣe àwárí akọrin náà.
Wọ́n ní ẹnikẹ́ni tó bá ní ìmọ̀ nípa bí àwọn ṣe lè mú Portable kó fi tó àgọ́ ọlọ́pàá tó bá wà ní agbègbè wọn létí.
Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì iléeṣẹ́ ọlọ́pàá wọ́ àwọn èèyàn Portable mẹ́sàn-án lọ sí ilé Májísíréètì tó wà ní agbègbè Isabo, ìlú Abeokuta fún ẹ̀sùn kan náà.