You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọmọ ẹgbẹ́ PDP méjì kú, alága APC kan dèrò ọ̀run níbi aáwọ̀ tó bẹ́ sílẹ̀ l'Osun lórí ọ̀rọ̀ ìjọba ìbílẹ̀
Awuyewuye lori idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lori ọrọ ijọba ibilẹ ti ba ibomiran yọ lẹyin ti ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP meji ni ijọba ibilẹ Boripe niluu Iragbiji ku, nigba ti alaga APC kan naa dero ọrun ni ijọba ibilẹ Ayedire lonii ọjọ Aje ọjọ kétadinlogun nipinlẹ Osun.
Laarọ ọjọ Aje lawọn alaga ijọba Ibilẹ APC ti ile ẹjọ kotẹmilọrun da lare gba awọn ofiisi awọn ìjọba ibilẹ lọ eyi to mu kawọn ọmọ ẹgbẹ PDP tako wọn ti aawọ si bẹ silẹ kaakiri ipinlẹ Osun.
Ohun ti a ri nigba ti a ṣe abẹwo si ìjọba ibilẹ Boripe niluu Iragbiji ni wi pe, awọn ẹgbẹ oselu APC lo gba gbogbo agbegbe naa ti wọn si le awọn ẹgbẹ oselu PDP kuro ni agbegbe ijọba ibilẹ ọhun.
Ọkan lara awọn alaga ijọba Ibilẹ ti ile ẹjọ kotẹmilọrun da lare pe ki wọn ko pada si ofiisi, Adeyemi Fatai, sọ fun BBC Yoruba pe awọn ti gba ẹtọ awọn pada lori bi ile ẹjọ kotẹmilọrun ti da wọn lare.
O ni idibo ijọba ibilẹ ti wọn ṣe ni ọdun 2022 lo gbe gbogbo awọn wọle, ṣugbọn nigba ti Gomina Ademola Adeleke gba ìjọba lo le awọn duro.
Adeyemi tun tesiwaju wi pe, oun ti pada ti ofiisi bayi ti isẹ naa si ti bẹrẹ ati gbogbo awọn alabasisẹpọ oun.
Ni ijọba ibilẹ Ifelodun, ẹkọ ko soju mimu rara, bi awọn jaduku ti awọn ẹgbẹ oselu PDP n lo ṣe ko oun ija oloro lọwọ, ti wọn ko si fi aye gba ọmọ ẹgbẹ oselu APC lati wọle si agbegbe naa, bakan naa ni wọn ko fi aye gba awọn akọroyin lati ya aworan kankan nibẹ rara.
Ayo Toyosi to jẹ Alaga Ayedaade ni tiẹ sọ pe, idibo ọdun 2022 lo gbe awọn wọle, sugbọn nigba ti ijọba miran de ni ile ẹjọ giga sọ wi pe, awọn ko lẹtọ si ofiisi alaga ijọba Ibilẹ ti wọn si fi ọwọ osi juwe ile fun awọn.
Ọgbẹni Toyosi ni eyi lo mu ki awọn gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ, abọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lo si mu ki oun ko pada si ofiisi.
O wa rọ gbogbo awọn osisẹ ijọba ibilẹ Ayedaade ki wọn ko pada si ofiisi kowa wọn. Toyosi ni ẹnikeni to ba kọ eti ikun yoo padanu isẹ rẹ.
''APC ti gba ijọba ibilẹ mọkandinlogun bayii ninu ọgbọn to wa l'Osun''
Ninu awọn ijọba ibilẹ ọgbọn to wa nipinlẹ Ọsun ni ati gbọ wi pe, awọn ẹgbẹ oselu APC ti gba ijọba Mọkandinlogun bayii.
Ẹwẹ, Hashim Abioye to jẹ Alaga fun eto idibo ijọba ibilẹ l'osun ti sọ pe idunkoko lasan ni eyi ti awọn ọmọ ẹgbẹ alatako APC n ṣe.
O ni idibo awọn alaga ati kasilọ ijọba ibilẹ yoo waye ni ọjọ Kejilelogun osu Keji yii.
Hashim tun tesiwaju wi pe, ẹgbẹ oselu mejidinlogun ni yoo ko pa ninu eto idibo ijọba ibilẹ to bọ ni ọjọ Kejilelogun osu Keji yii.
Ọgbẹni Hashim ni awọn ti mura silẹ tan fun eto idibo naa ti gbogbo ohun elo eto idibo si ti wa nilẹ sẹpe bayi.
O wa rọ gbogbo awọn agbofinro pe ki wọn ko wa ni oju ni alakan n fi sọri ni saaju ati ni ọjọ idibo.
Ọgbẹni Hashim wa fi da gbogbo olugbe ipinlẹ ọsun loju wi pe ki wọn ko jade dibo ki wọn ko mọ ṣe bẹru rara.
Ìró ìbọn ń dún lákọ lákọ láwọn ìjọba ìbílẹ̀ l'Osun torí fàákájáa láàrin PDP àti APC lórí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn
Ibẹru bojo gbalẹ kan nipinlẹ Osun lẹyin ti iro ibọn n dun lakọ lakọ lawọn ijọba ibilẹ kan latari aawọ tọ bẹ silẹ laarin ẹgbẹ oṣelu PDP to wa nijọba ati ẹgbẹ oṣelu alatako APC lori idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun.
Awọn fọnran kan to wa lori itakun ayelujara ṣafihan bi awọn olugbe agbegbe tawọn ijọba ibilẹ wa nipinlẹ Osun ṣe n sa asala fun ẹmi wọn tawọn ontaja lagbegbe naa si n gbe ṣọọbu tipa.
Lara awọn ijọba ibilẹ tawọn janduku kan gbiyanju lati ya wọ ni ijọba ibilẹ Boripe, Iwo, Ifelodun, Odo-Otin, Osogbo ati Olorunda.
Ninu fidio kan to wa lori itakun ayelujara tawọn eeyan kan ṣe ni ijọba ibilẹ Ifelodun, Ikirun ni awọn kan ti n dunkoko wi pe ẹnikẹni ko ni wọle si ijọba ibilẹ naa.
Bakan naa awọn eeyan kan duro siwaju ijọba ibilẹ Iwo ti wọn si sọ pe awọn ko ni jẹ ki ẹnikẹni lati inu ẹgbẹ oṣelu APC wọle.
Lanaa ọjọ Aiku ọjọ kẹrindinlogun ni Gomina Ademola Adeleke ke gbajare to si fẹsun kan Gboyege Oyetola to jẹ gomina ipinlẹ Osun tẹlẹ pe o fẹ fi ipa dawọn alaga ati kansilọ ti ile ẹjọ yọ nipo pada si ọfiisi.
Amọ, Oyetola ti sọ fun Adeleke wi pe ko bọwọ fun idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Akure to paṣẹ idapadasipo awọn alaga ati kansilọ naa ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ osẹlu APC.
Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ láti yọjú sí ibi iṣẹ́ lórí ìfaǹfà tó ń wáyélórí àkóso ìjọba ìbílẹ̀ l'Osun
Níṣe ni gbogbo àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Osun dá paróparó bí áwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà ṣe kọ̀ láti yọjú sí ibiṣẹ́ lẹ́yìn tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àwọn ìjọba ìbílẹ̀, ìyẹn , NULGE ṣe darí àwọn òṣìṣẹ́ láti má lọ sí ibi iṣẹ́.
Èyí kò ṣẹ̀yìn ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC àti Peoples Democratic Party, PDP lórí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lórí ọ̀rọ̀ àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ ìpinlẹ̀ náà.
Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Kejì, ọdún 2025 ni ẹgbẹ́ NULGE fi àtẹ̀jáde síta pé àwọn òṣìṣẹ́ kò gbọdọ̀ lọ sí ibiṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtàdínlógún.
Àtẹ̀jáde tí ààrẹ NULGE tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Osun, Nathaniel Kehinde Ogungbangbe fi síta ní àwọn ti ń gbọ́ nípa àwọn ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti PDP tó sì ti ń dá inú fu àyà fu sọ́kàn àwọn òṣìṣẹ́.
Ogungbangbe ní ẹgbẹ́ NULGE kìí dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú àmọ́ àwọn kò ní fi ààyè gba àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn láti ṣiṣẹ́ níbi tí kò sí ààbò.
NULGE wá rọ gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú láti tẹ̀lé ìlànà òfin, kí wọ́n yé sọ àwọn ìjọba ìbílẹ̀ di pápá ìjà, kí wọ́n yé fi àwọn òṣìṣẹ́ sínú ewu.
Àtẹ̀jáde náà ní ìbámu pẹ̀lú ìdarí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, NLC, àwọn òṣìṣẹ́ kò gbọdọ̀ lọ sí ibiṣẹ́ títí tí ààbò tó péye yóò fi wà fún wọn.
Bákan náà ni wọ́n rọ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti ri dájú pé wọ́n pèsè ààbò tó péye fún ẹ̀mí àti dúkìá àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀.