Ọlọ́pàá Sharia gbé àwọn ṣọ́ọ̀bù táwọn olólùfẹ́ eré bọ́ọ̀lù ti ń ta tẹ́tẹ́ tìpa

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ọlọpaa Sharia ti bẹrẹ si ni gbe awọn ṣọọbu t'awọn ololufẹ ere bọọlu ti n ta tẹtẹ tipa.

Awọn ọlọpaa naa ni tẹtẹ títa lodi si ẹṣin musulumi.

Igbakeji ọga ọlọpaa Sharia, Mujahid Aminudeen, sọ fun BBC wi pe eewọ ni tẹtẹ títa ninu ẹsin Islam.

Bi awọn ọlọpaa Hisbah naa ṣe bẹrẹ si ni yabo awọn ṣọọbu ti wọn ti n ta tẹtẹ naa ko ṣẹyin bi awọn olori awujọ, at'awọn obi ti n kọminu lori bi ọpọ awọn ọdọ ṣe n ta tẹtẹ bayii.

Ọgbẹni Aminudeen to jẹ igbakeji ọlọpaa Hisbah ni awọn obi gan an ni wọn f'ọrọ naa to awọn leti.

O ni ṣọọbu ọgbọn ti wọn ti n ta tẹtẹ ni ọlọpaa Hisbah gbe tipa lọjọ kan ṣoṣo ti wọn si ṣe ìkìlọ fáwọn to ni ṣọọbu ọhun.

Amọ, Ọgbẹni Aminudeen ti wa sọ pe ni bayii tawọn eeyan ti mọ pe ẹsin islamu ko f'aye gba tẹtẹ títa, awọn yoo bẹrẹ si ni maa fọwọ ofin mu ẹnikẹni to ba tun n hu iru iwa bẹẹ.

Ilu Kano to jẹ olu ilu ipinle Kano wa lara awọn ipinlẹ to n lo ofin Sharia ati ofin orilẹede Naijiria bakan naa.

Ijọba faye gba ile ọtí l'awọn agbegbe t'awọn Kristẹni pọ si niluu Kano.

Amọ, awọn to ni awọn ile ọtí yii naa le foju wina ofin t'awọn ọlọpaa Sharia ba ri pe awọn musulumi n lọ mu ọti nibẹ.

Ṣugbọn agbegbe awọn musulumi ni awọn ọlọpaa Sharia ti n ṣiṣẹ lọwọ yii.

Ọgbẹni Aminudeen ṣalaye pe ọpọ to n fi ṣọọbu wọn ta tẹtẹ ni wọn gba iwe ẹri lati maa lo tẹlẹfisan fun wiwo ere idaraya fidio ki wọn to sọ awọn ṣọọbu naa ile tẹtẹ.

Bi ọrọaje Naijiria ṣe dẹnukọlẹ ti jẹ ki ọpọ eeyan maa fi iyekiye ti wọn ba ni ta tẹtẹ ni ireti pe awọn yoo jẹ owo gọbọi.

Amọ, eyi lo ti sọ ọpọ ọdọ di initẹtẹ tawọn mii tiẹ n fi ile ẹkọ silẹ gan an tori tẹtẹ títa.

Aminudeen ni ẹkọ ni ọrọaje Naijiria to dẹnukọlẹ n kọ araalu wi pe ki wọn yipada pẹlu ẹṣẹ ti wọn n ṣẹ.

Igbakeji ọlọpaa Hisbah wa rọ gbogbo ẹni to ba ni ṣọọbu tẹtẹ wi pe ki wọn tete kogba wọle, bi bẹẹ kọọ, Hisbah yoo fọwọ ofin mu wọn.

Ni ọdun 2000 ni ijọba ṣe agbekalẹ ofin Sharia nipinlẹ Kano, gẹgẹ bi ofin naa ṣe wa ni ipinlẹ mọkanla mii lapa ariwa Naijiria.

Ofin Sharia lodi si tẹtẹ títa, ṣiṣe aṣẹwo ati ọti mimu.