You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ifon àti Ilobu tún bẹ̀rẹ̀ ìjà míì, ìjọba Osun fọnmú pẹ̀lú ìkéde kónílé gbélé
Akọtun ija min tun ti bẹ silẹ laarin ilu Ilobu ati Ifon-Orolu, tii se ilu meji ti wọn dijọ paala pẹlu ara wọn.
Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọmọbibi ilu Ifon-Orolu lo figbe ta pe awọn agbebọn kan lo ya bo ilu awọn Ilobu, ti wọn si da ibọn bolẹ ni adugbo Apiponroro.
Isẹlẹ naa lo da ibẹru bojo sọkan awọn olugbe ilu naa, ti wọn si sa asala fun ẹmi wọn.
Awọn eeyan ilu Ifon-Orolu ati Ilobu n naka aleebu sira wọn lori aktun ija to bẹ silẹ
Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ naa, Alaga ẹgbẹ to n wa ilọsiwaju ilu Ifon, Jide Akinyooye naa fidi isẹlẹ ọhun mulẹ eyi to ni o bẹrẹ ni aarọ ọjọ Isẹgun.
O ni ọpọ eeyan lo ti fi ile wọn silẹ nilu Ion lati sa asala fun ẹmi wọn.
Amọ nigba to n ba iwe iroyin Punch sọrọ, Otun Jagun tilu Ilobu, Oloye Goke Ogunsola salaye pe awọn agbebọn ilu Ifon lo kọkọ kọju ija sawọn eeyan to wa ni agbegbe kan nilu Ilobu.
"Mo gba ipe lọdọ awọn eeyan wa to wa lẹba aala ilẹ pẹlu ilu Ilobu, ti wọn si figbe bọnu pe awọn agbebọn kan lati ilu Ifon ti kọlu awọn.
Awọn eeyan wa to n gbe ni agbegbe Ganga ati Apinroro ni se lawọn agbebọna naa dena de awọn, o si di dandan ki awọn naa gbe ara awọn nija lọna kan tabi omiran.
Wọn pe ipade alaafia lọjọ Aje, nibi ipade naa si ni Olufon ti n dunkooko mọ wa."
O wa rọ ijọba ipinlẹ Osun lati gbe igbesẹ to yẹ lati daabo bo awọn nitori ololufẹ alaafia ni awọn, awọn eeyan ilu Ifon si lo n kọlu awọn.
Agbọn n sẹ, oyin n sẹ sugbọn oju oloko lo wu bọọku-bọọku yii.
Ijba ipinlẹ Osun kede asẹ konile-gbele
Wayi o, ijọba ipinlẹ Osun ti kede konile-ogbele ni ilu mejeeji naa, ti wọn si ni esinsin ko gbọdọ ta firi laarin awọn ilu naa.
Nigba to n gbe asẹ naa kalẹ, Atẹjade kan ti Kọmisana feto iroyin, Kolapo Alimi, fisita lọjọbọ ni aago meje aarọ si aago meje alẹ ni isede naa yoo fi maa waye.
"Gbogbo awọn ti isẹlẹ yii gberu si la gba niyan lati fọwọ sowọpọ pẹlu ijọba ki isẹlẹ ọhun le di afiẹyin ti eegun fi asọ.
A ti wa da ikọ awọn agbofinro sawọn ilu mejeeji naa ninu eyi ti awọn osisẹ ologun, ọlọpaa ati aabo ara ẹni, laabo ilu wa, lọna ati da alaafia pada sawọn agbegbe naa.
Ẹnikẹni ti ọwọ ba wa tẹ pe o n da omi alaafia ru lagbegbe naa yoo fimu ko ata ofin."