Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọmọ Naijiria mẹ́fà tó gba àmì ẹ̀yẹ Ààrẹ Joe Biden lórí ìmọ̀ sáyẹ́nsì

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba ilẹ Amẹrika ti fun awọn ọmọ Naijiria mẹfa ti wọn jẹ onimọ ijinlẹ sayẹnsi ni ami ẹyẹ fun akitiyan wọn lori itẹsiwaju imọ lagbaye.

Awọn ọmọ Naijiria naa lo wa ninu irinwo eeyan ti Aarẹ Joe Biden fun ni ami ẹyẹ ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Presidential Early Career Award for Scientists and Engineers (PECASE).

Biden fun wọn ni ami ẹyẹ naa latari ipa ribiribi ti wọn ko lati mu ki imọ ijinlẹ tẹsiwaju si.

Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa awọn ọmọ Naijiria to gba ami ẹyẹ naa ree.

Tomi Akindele

Tomi Akindele jẹ oluwadii imọ ijinlẹ ni Lawrence Livermore National Laboratory.

O kẹkọọ gboye Ọmọwe nipa imọ 'Nuclear Engineering' ni fasiti ilu California, o si ti kọkọ kẹkọọ ni fasiti Texas A&M ṣaaju asiko yii.

O ti gba oniruru ami ẹyẹ ṣaaju ami ẹyẹ ti Biden n fun yii, lara awọn ami ẹyẹ naa ni ti Nuclear Science and Security Consortium Fellowship.

Azeez Butali

Ọjọgbọn nipa imọ Oral Pathology, Radiology, & Medicine ni Azeez Butali ni fasiti ilu Iowa.

O kekọọ jade ni fasti ijọba apapọ to wa niluu Eko, Unilag lọdun 2000 to ko lọ kẹkọọ gboye nipa imọ 'genetics epidemology' lọdun 2010, lati ibẹ lo ti lọ si fasiti Iowa.

Lọdun 2016 o gba iwe ẹri imọ 'genetics' ni fasiti Stanford.

Oniruru ami ẹyẹ ni ọkunrin naa ti gba ṣaaju akoko yii; lara rẹ ni NIH Pathway to Independence Award lati ọwọ ajọ National Institute of Dental and Craniofacial Research (NIDCR).

Ijeoma Opara

Yale School of Public Health ni Opara ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bii Ọjọgbọn.

Oun naa tun ni oludasilẹ ati adari ajọ Substance Abuse & Sexual Health Lab.

Lara awọn nnkan to n ṣe iwadii ijinlẹ le lori ni arun kogboogun atawọn arunibalopọ mii laarin awọn ọdọ.

Opara ti gba ọpọ ami fun awọn iwadii ijinlẹ to n ṣe lati ọwọ ajọ American Public Health Association ati National Council on Family Relations, and Academy.

Oluwasanmi Koyejo

Olukọ ni Koyejo ni ẹka imọ ẹrọ kọmputa ni fasiti Stanford, nilẹ Amẹrika.

Ohun ti imọ rẹ da le lori ni imọ nipa 'machine learning'.

Ṣaaju asiko yii, o ti gba ami ẹyẹ Skip Ellis Early Career Award ati Sloan Fellowship.

Ọdun 2013 lo gba oye Ọmọwe ni fasiti Texas, to wa ni Austin, TX, nilẹ Amẹrika.

Lọwọ yii, o wa lara awọn adari ajọ Black in AI organization.

Abidemi Ajiboye

Case School of Engineering ni Ajiboye ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bii Ọjọgbọn.

Oun naa ti gba oniruru ami ẹyẹ ṣaaju ami ẹyẹ ti Aarẹ Biden n fun yii.

Ọjọgbọn naa kẹkọọ gboye nigba meji ọtọtọ ninu imọ Biochemical ati Electrical Engineering.

Bẹẹ naa lo tun kẹkọo nipa imọ kọmputa ni Duke, to wa ni Durham, North Carolina, lọdun 2000.

Eno Ebong

Ọdun 1999 ni Eno kẹkọọ gboye Mechanical Engineering ni Massachusetts Institute of Technology niluu Boston, o tun tẹsiwaju lati kawe si lọdun 2001 titi to fi gboye Ọmọwe lọdun 2006.

Lara awọn ami ẹyẹ to lamilaaka to ti gba ni NSF CAREER Award.