Olóòtú ìjọba Canada, Justin Tradeau kọ̀wé fipò sílẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Olootu ijọba orilẹede Canada, Justin Tradeau ti kede pe oun ti kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii olootu ijọba orilẹede naa.

Ọdun 2015 ni Tradeau di olootu ijọba orilẹede Canada.

Lasiko to n dahun ibeere lati ọdọ àwọn akọroyin niluu Ottawa, lo ti sọ pe asiko ti to fun atunto lagbo oṣelu,paapaa nile aṣofin.

Trudeau to n lo saa kẹta lọwọ sọ pe, atunto ọhun yoo pin si abala meji - dida ijoko àwọn aṣofin duro titi di oṣu Kẹta, ati ikọwe fipo silẹ rẹ to ni igbagbọ pe, yoo mu adinku ba aisi iṣọkan to wa lagbo oṣelu orilẹede Canada.

Tradeau ni, ojujumọ ti oun ba ji gẹgẹ bi olootu ijọba ni oun ni iwuri si i lati mu igbeaye rọrun lọrilẹede naa.

O ni oun gbagbọ pe oun ti ja fun orilẹede Canada ati awọn eeyan rẹ.

Ṣaaju ikede rẹ yii, ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ, ati awọn eeyan mii ti n kesi i pe, ko kọwe fi ipo silẹ.

Kete ti ẹgbẹ oṣelu Liberal ti Tradeau wa ba ti yan olori ẹgbẹ oṣelu ati olootu ijọba mii ni yoo kuro lori ipo gẹgẹ bii olootu ijọba orilẹede naa.

O ni oun gbe igbesẹ naa lẹyin ọpọlọpọ ijiroro pẹlu mọlẹbi oun, nitori pe atilẹyin wọn lo sun oun de ibi ti oun wa bayii.

Tradeau ni "orilẹede Canada nilo ẹni to koju oṣuwọn lati bori eto idibo to n bọ".