You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ta ni Nathaniel Bassey, akọrin ẹ̀mí tí Donald Trump pè láti kọrin níbi ètò ìbúra Ààrẹ Amẹ́ríkà tuntun?
Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe gbajugbaja onkọrin igbagbọ ọmọ orileede Naijiria nni, Nathaniel Bassey yoo kọrin nibi eto ibura fun Donald Trump, aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nilẹ Amẹrika.
Ogunjọ, oṣu Kinni, ọdun ti a wa yii ni eto ibura ọhun yoo waye ni Waldorf Astoria Presidential Ballroom, Washington DC.
Nathaniel Bassey yoo kọrin laarọ kutu nibi eto adura akọkọ fun ibura aarẹ ati igbakeji rẹ.
Nigba to n kede loju opo Instagram rẹ, Pastor Nathaniel ni;
"Ẹ jẹ ka gbe ohun dide ni Amẹrika. Ki Ọba Ogo si wọle wa. Maa rii yin logunjọ, oṣu Kinni, ọdun 2025.
"Ipade oruọ ti aarẹ jẹ eyi kii ṣe tijọba tabi ti aladani. O jẹ tagbekalẹ ti igbagbọ nibi ti wọn ti n fi adura ati orin iyin jirẹbẹ si Ọlọrun fun ijọba ati ileeṣẹ aarẹ lorileede.
"Ẹẹkan ṣoṣo laarin ọdun ni eto naa maa n waye gẹgẹ bi ounjẹ adura aarọ kutu ṣaaju gbogbo iṣakoso tuntun. Ati pe lati ọpọ ọdun ni awọn eeyan jankanjankan ati adari lagbaye ti maa n darapọ mọ wọn."
Ẹni ọwọ Merrie Turner ni alakoso agba fun eto adura aarọ akọkọ naa, ti yoo si tukọ rẹ.
Lara awọn ti yoo tun kopa nibi eto naa ni Pasitọ Mario Bramnick, Ajihinrere Rebecca Macchi ati Ọmọwe Dominiquae Bierman.
Ọjọ naa ni wọn yoo bura fun Donald Trump, gẹgẹ bi aarẹ Amẹrika ati JD Vance, gẹgẹ bi igbakeji aarẹ ilẹ Amẹrika.
Nathaniel Bassey nikan ni onkọrin lati orileede Naijiria ati ilẹ Afrika lapapọ ti wọn yoo pe sibi eto ibura naa, gẹgẹ bo ṣe ṣalaye loju opo Instagram rẹ lọjọ Aiku to kọja.
Eto ọhun to n waye lẹẹkan laarin ọdun mẹrin ni awọn alakoso ilẹ Amẹrika maa n ṣe lati fi gbadura fun iṣakoso tuntun nilẹ Amẹrika, ati atilẹyin fun awọn adari tuntun forileede naa.
Ta ni Nathaniel Bassey?
Odu ni Nathaniel Bassey, kii ṣaimọ foloko lagboole orin kikọ lorileede Naijiria, paapaa lagbaye.
Gbogbo igba lo si maa n ṣe eto orin kikọ to pe ni "Hallelujah Challenge", eyi to maa fi n so awọn Kristẹẹni kaakiri agbaye papọ.
Eto ọhun ti lọ kaakiri agbaye, to si ti di ohun ijiroro agbaye.
Lọdun 2024 to kọja ni Mayor ti ilu Albany to wa ni New York, Kathy Sheehan bu ọla nla fun Bassey, to si kede gbogbo ọjọ kẹfa ninu oṣu Kẹwaa, ọdọọdun gẹgẹ bi ọdun Bassey lagbaye, iyẹn "Pastor Nathaniel Bassey Day".
Pasitọ ni Nathaniel Bassey pe ara rẹ, to si gbajumọ daadaa lorileede Naijiria ati agbaye
Ọmọ bibi ipinlẹ Akwa Ibom ni Bassey
Bo ṣe jẹ agbe-orin jade, lo n fun duuru, lo n kọrin, naa lo tun jẹ alagbekalẹ orin. Oniruuru ara lo n fi orin da, ko si iru orin ti ko lee kọ to ba ti jẹ nipa igbagbọ, iyẹn Kristẹẹni.
Pasitọ fawọn ọdọ ni Bassey jẹ ninu ijọ Ridiimu, ti ẹkun The King's Court to wa nipinlẹ Eko.
Ko to di pe Nathaniel Bassey bẹrẹ mimu iṣẹ orin kikọ gẹgẹ bi iṣẹ oojọ, o wa lara awọn ọmọ ẹgbẹ akọrin Steve Rhodes Jazz – koda, ohun ni olori wọn.
Bakan naa lo tun wa lara ikọ Spectrum 4 jazz quintet, ati awọn miran.
Lọdun 2017 ni Bassey bẹrẹ eto orin kikọ rẹ to pe ni 'Hallelujah Challenge', eyi to fi n kọrin iyin, ati adura, to n ṣe lori ikanni ayelujara.
Ọpọ awọn eeyan ni wọn maa n darapọ mọ eto naa to maa n waye lọwọ aṣalẹ.
Bassey ti fẹ iyawo, Ọlọrun si ti yọnda ọmọ meji fun igbeyawo rẹ
Ọpọ orin ni Nathaniel Bassey ti gbe jade, to si tun ti kọrin papọ pẹlu awọn agba onkọrin ni Naijiria ati loke-okun.
Awọn onkọrin Naijiria to ti kopa nibi eto ibura awọn adari lagbaye
Burna Boy
Lọdun 2021, Damini Ebunoluwa Ogulu tọpọ awọn eeyan mọ si Burna Boy kopa nibi eto ibura Aarẹ Joe Biden ti iṣakoso rẹ fẹẹ kogba wọle l'Amẹrika.
Burna Boy pẹlu awọn gbajugbaja olorin mẹrindinlaadọta lagbaye ni wọn pe lati wa kọrin lọdun naa.
Awọn olorin bii Dua Lipa, Tame Impala, ati Kygo ni ọmọkunrin naa ba kọrin papọ.
Tiwa Savage
Ọdun 2023 ni Tiwatope Omolara Savage, ẹni tọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Tiwa Savage naa fitan tuntun balẹ gẹgẹ bi olorin akọkọ lorileede Naijiria lati kopa nibi eto ibura fun Ọba ilẹ Gẹẹsi.
Ọdun naa ni Ọba Charles kẹta gbade ni Winsdor Castle, England.