You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mo wà láyé nítorí ẹ̀bùn tí ìyàwó mi fún mi - Eedris Abdulkareem
Gbajugbaja olorin takasufe, Eedris Abdulkareem ti kan sanra si iyawo rẹ, Yetunde fun ipa ribiribi to ko ni igbesi aye rẹ nigba to n ṣe ayẹyẹ ọdun kejidinlogun ti wọn ṣe igbeyawo.
Lori opo ayelujara rẹ, Eedris dupẹ lọwọ iyawo rẹ fun anfani to fun oun lati wa laye rẹ ati lati ni anfani lati maa gbe igbesi aye to ni itumọ.
O tẹsiwaju lati dupẹ lọwọ Ọlọrun to mu opo igbeyawo wọn duro lẹyin gbogbo rogbodiyan to waye laarin wọn.
Ninu oṣu keje ọdun 2022, Eedris kede pe oun koju aisan kidinrin, eleyii ti awọn oloyinbo n pe ni ‘kidney failure.’
Iyawo rẹ lo gba lati fun un ni kidinrin tiẹ nigba ti wọn de ile wosan.
O ni:
“Yetunde Sekinat AbdulKareem, mo wa laye nitori pe o fun mi ẹbun to ju ẹbun lọ. Jọọ, mo fẹ koo mọ pe mo mọ riri ẹbun naa.
“N ko ro pe mo le sọ bi mo ṣe roo lọkan sugbọn mo fẹ koo mọ pe mo mọ riri ore too ṣe fun mi lati wa laye.
“Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o duro ti mọlẹbi wa lati ọdun mejidinlogun ti a ṣe igbeyawo, to si mu wa bori gbogbo laasigbo to doju kọ wa. Mo ki ẹ ku ayẹyẹ ọdun kejidinlogun ti a ṣe igbeyawo.”