You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ayefele ṣé ayẹyẹ ọdún 25 tó móríbọ́ nínú ìjàmbá ọkọ̀
Gbajugbaja olorin ẹmi, Yinka Ayefele ṣe ayẹyẹ ọdun Kẹẹdọgbọn to moribọ kuro ninu ijamba ọkọ to gba ẹsẹ rẹ mejeeji lọwọ rẹ.
Ayefele bọ sori opo ayelujara rẹ lọjọ Aiku lati ṣe afihan awọn aworan ọkọ ọhun ninu eyi ti ẹsẹ rẹ mejeji ti lọ nigba naa lọhun, to si n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun wiwa laye rẹ.
O ni: “Oni lo pe ọjọ Kẹẹdọgbọn. Ẹ ba mi dupẹ lọwọ Ọlọrun. Ọjọ Kejila, Oṣu Kejila ọdun 1997, ọdun iyipada mi, titi ayereye ni maa ma dupẹ lọwọ Ọlọrun.”
Ohun to yẹ koo mọ bipa Olayinka Joel Ayefele
Olayinka Joel Ayefele jẹ akọrin, agbohunsafẹfẹ ati oludasilẹ ileesẹ Rẹdio kaakiri ilẹ Yoruba.
Ọmọ bibi ilu Ipoti Ekiti nipinlẹ Ekiti ni, to si dele aye ni Ọjọ Kinni Oṣu Keji ọdun 1968, eyiun ọdun Mẹrinlelaadọta sẹyin.
Ọdun 1997 lo ni ijamba ọkọ to kan eegun ẹyin rẹ, ti ko si le fi ẹsẹ mejeeji rin mọ, eyi to mu ko maa lo kẹkẹ.
Yinka Ayefele, ẹni ti ijọba apapọ fi ami ẹyẹ MON da lọla lo ti gbe ọpọ awo orin jade, o ni iyawo, o si ti bi ọmọ ibẹẹta.