Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá sàfihàn akẹ́kọ̀ọ́ obìnrin Poly méjì tó ṣekúpa ọ̀gá ilé ijó nílùú Abuja

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ akẹkọọ obinrin ilẹ ẹkọ gbogbo niṣe Poly meji kan fun ẹsun pe wọn lọwọ ninu iku oludasilẹ ile igbafẹ alẹ kan lẹyin ibalopọ.

Olu ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Abuja sọ pe awọn afurasi naa, Joseph Joy Adanma ati Vandora Oreluwa Favour ni ibasepọ ẹlẹni meje ti wọn si de arakunrin naa, Adeniyi Ojo mọ ibusun pẹlu okun lasiko ibalopọ ọhun.

Awọn ọlọpaa ni awọn afurasi naa tun ji foonu ati awọn dukia rẹ mii, ki wọn to ṣekupa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn tọpasẹ foonu naa de ilu Mowe nipinlẹ Ogun, ni bi ti ọwọ ti tẹ awọn afurasi naa.

Lasiko to n safihan awọn afurasi naa, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaalorilẹede Naijiria , Olumuyiwa Adejobi si ọwọ tẹ awọn afurasi meji to jẹ akẹkọọ Ile ẹkọ gbogbo niṣe ti ipinlẹ Kwara.

“Lẹyin ọpọlọpọ iwadii ati ifimufinlẹ, Ileeṣẹ ọlọpaa ri awọn afurasi naa mu ni Mowe-Ibafo, nipinlẹ Ogun.

“Awọn afurasi mejeeji so oloogbe mọlẹ mọ ibusun lori pe wọn jọ fẹ ni ibasepọ lati fi gba owo lọwọ rẹ. Sugbọn nigba ti oloogbe kọ lati fun wọn lowo, wọn fun lọrunpa, to si jade laaye.

Ọkan lara awọn afurasi to ba ileeṣẹ ọlọpaa sọrọ, Adanma ni ọpọ igba ni oun ti ba oloogbe ni ibaṣepọ sugbọn lọjọ to jade laaye, awọn lọ si ọdọ rẹ pẹlu erongba lati gba owo lọwọ rẹ, ti wọn si fin ogun oloro simu, ti wọn kuro lọdọ rẹ pẹlu awọn dukia rẹ, ki wọn to gbọ pe o ti jade laye .