You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn dókítà bù ọdún méje péré fún wọn ṣùgbọ́n àwọn ìbejì yí tí pé 18 báyìí
Riro ni t'eniyan , ṣiṣe si ni ti Oluwa.
Ibi ti ẹda a maa fi ọkan si lọpọ igba ,ọrọ kii gba ibẹ lọ.
Awọn ọrọ ọlọgbọn yi ṣe rẹgi pẹlu itan awọn ibeji Sam ati Alex Bolton ti awọn onimọ iṣegun ni wn ko le lo ju ọdun meje laye lọ.
Lowurọ toni to mọ, awọn ọdọkunrin mejeeji yi ti ṣe ọjọ ibi ọdun mejidinlogun.
Ni ilẹ Gẹẹsi lawọn mejeeji wa ti wọn si n koju ipenija aisan abimọ kan to n ko ipalara ba eegun ẹyin wọn.
Eyi a si maa mu ki o nira fun wọn lati da apa ati ẹsẹ gbe.
Iya wọn Sarah Wilson sọ pe igba ti wọn pe oṣu mejidinlogun lawọn mọ nipa aisan yi.
Ni bayii Sam ati Alex ni inu awọn dun lati wọ abala mii ninu igbesi aye wọn.
Arabinrin Wilson sọ pe ''orire nla ni fun enikẹni pe o ribi pe ọdun mejidinlogun laye ṣugbọn ti mo ba boju wẹyin nigba ti wọn s pe iru aisan to n ṣe awọn ọmọ mi ree,mi o lero pe Alex ati Sam yoo bori de ipo yi''
O ni awọn ibeji yi ti wọn lo keke ologere lati fi maa rin ko nilo iranwọ lati da jẹ akara eebo, cake, ti wọn gbe fun wọn.
O ni inu wọn dun gidi gaan an.
Iya wọn sọ pe "Wọn kii saba rojọ nipa aisan wọn.''
''Lọpọ igbga nkan ti wọn ba le ṣe la maa n gbajumọ dipo ka maa daamu lori eleyi ti wọn ko le ṣe''
Lọjọ Aiku ni awọn ibeji yi ṣe ọjọ ibi wọn ti ẹbi ati ọrẹ to fẹ ẹ to ọgọta si peju sibi ayẹyẹ naa.
Lọwọlọwọ wọn n palẹmọ lati pari eto ẹkọ ọlọdun meji kan ni ile ẹkọ Derby College ti wọn si gbero lati kẹkọ nipa iṣẹ iroyin ni fasity Derby loṣu Kẹsan an.
Ero ọkan wọn ni lati jẹ atọkun lori amohunmaworan.
Sam sọ pe ''nigba ti wọn kọkọ kede aisan to n ṣe wa, wọn ni a o le lo ju ọdun meje laye lọ ti eyi si dẹru ba iya wa''
''Manigbagbe leleyi jẹ ni igbesi aaye wa bẹẹ naa si ni yoo maa ri titi lọkan wa''
Alex lo fesi bẹẹ.
O ni ''ibẹrẹ abala mii ree ni igbesi aye wa ti inu wa si dun pupọ ''