"Ìrònú ti fẹ́ pa wá, owóyàá orí fóònù là ń gbà jẹun"

Ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria, NARD, ti sọ pe iyanṣẹlodi oun ṣi n tẹsiwaju.

Aarẹ NARD, Innocent Orji, lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Channels.

Orji ni “Lootọ ni a ti wọgile ifẹhonuhan to yẹ ko waye laarọ Ọjọru, amọ iyanṣelodi wa ṣi n tẹsiwaju.”

Bakan naa, Orji n tara poro lori ọpọ ipenija to n bawọn dokita orilẹede yii finra ati ọpọ iya to n jẹ wọn.

“A o tun gbe ọrọ naa yẹwo lẹyin wakati méjíléláàdọ́rin, ohun ti awọn adari ẹgbẹ wa fẹnuko si niyẹn.”

Aarẹ NARD ṣalaye pe ohun mẹjọ pataki lawọn akẹgbẹ oun n bere fun lọwọ ijọba Naijiria, lara rẹ si ni pe ki ijọba gba awọn dokita mii siṣẹ dipo awọn to ti lọ si oke okun.

O ni “Awọn ọmọ ẹgbẹ wa n jiya, awọn ọmọ Naijiria naa n jiya.”

“Ti ko ba si iye dokita to yẹ ko wa nile iwosan, yoo ṣe ipalara fun eto ilera, ko sẹni to le sọ pe irọ ni ọrọ yii.”

“Ijọba gbe igbimọ kan dide ti wọn si ṣe awọn alakalẹ kan amọ titi di akoko yii ijọba ko tii pin ohun to wa ninu alakalẹ naa ki a foju ri.”

Gẹgẹ bii ohun to sọ, alakalẹ naa yoo mu adinku ba bi awọn dokita Naijiria ṣe n salọ silẹ okeere.

Orji sọ siwaju si pe ijọba ko fi ọwọ pataki mu awọn ohun ti awọn n bere fun.

NARD wọgile ifẹhonuhan wọn to yẹ ko waye lẹyin ipade awọn adari rẹ pẹlu Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio.

Ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2023 ni NARD kede iyanṣelodi alailọjọ lẹyin ti ijọba ko ṣe awọn ohun ti wọn n bere fun ṣaaju.

"Ọpẹlọpẹ pe a n ri owo ya lati ori foonu wa, ironu ko ba ti pa wa"

Wayi o, Ẹgbẹ awọn dokita nile ẹkọsẹ isegun ti fasiti ilẹ wa to wa nilu Nzukka,ti wa koro oju si ofin ko sisẹ, ko si owo osu ti ijọba n lo lori awọn osisẹ to n yansẹlodi.

Awọn dokita ile iwosan naa ni isoro to n bawn finra kọja eyi to ba gbogbo awọn dokita lapapọ.

Wọn ni ọpọ awọn ni ijba gbagbe sipo dokita to n gboye kun oye lati ọdun meji sẹyin, ti suuru awọn si ti fẹ pin.

Awọn dokita naa si lo n fi ika hanu lori ipo ti awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ naa to le ni ọgọrun wa, nitori owo osu tasọrẹ ti wọn n gba.

Koda, wọn ni ironu ti fẹ pa awọn onisẹ ilera naa nitori isoro ti wọn n la kọja lati gbọ bukata wọn.

Wọn fikun pe ọpẹlọpẹ anfaani ti wọn ni lati ya owo lati ẹrọ ibaraẹnisọrọ wọn, bi bẹẹ kọ, o ni ironu atijẹ ati atimu ko ba ti ran ọpọ wọn sọrun.