You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Baba Ijesha ti gba ìtúsílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n? Àlàyé rèé
Lati bi ọjọ meloo kan bayii ni fidio kan lori ayelujara ti n ṣafihan pe gbajugbaja oṣere Olanrewwaju James ti ọpọ mọ si Baba Ijesha ti gba itusilẹ ni ọgba ẹwọn.
Ni ọdun 2022 ni ile ẹjọ kan niluu Eko dajọ pe o jẹbi ẹsun ifipabanilopọ pẹlu ọmọdebinrin kan, ti ile ẹjọ naa si ran an lẹwọn ọdun mẹrindinlogun.
Amọ, nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ, ajafẹtọọ to tun jẹ oludasilẹ ẹgbẹ ijafẹtọ ọmọniyan ti wọn ni Vanguard Liberation, Kọmureedi Aghedo kehinde Stephen sọ pe Baba Ijesha ko tii gba itusilẹ.
O ni iroyin ofege lasan l'awọn eeyan kan n gbe kaakiri.
Ọgbẹni Stephen ni "Baba Ijesha ko tii gba itusilẹ, amọ a n wo ohun to maa ṣẹlẹ pẹlu ẹjọ kotemilorun ti o pe.
Fidio táwon eeyan kan n gbe kiri lori ayelujara jẹ fidio igba ti wọn kọkọ fi Baba Ijesha silẹ ni ahamọ nigba ti igbẹjọ rẹ fi n lọ lọwọ.
Ti Baba Ijesha ba ti gba ominira, gbogbo awọn akọroyin lo maa gbọ, oun gan an maa ti ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn oniroyin.
A o mọ awọn to wa nidii fidio ti wọn n gbe kiri lori ayelujara."
Kọmureedi Stephen wa lara awọn to duro lati rii pe idajọ ododo waye lori ọrọ Baba Ijesha.
Baba Ijesha rí ẹ̀wọ̀n he lórí ẹ̀sún ìfipábá ọmọdé lọ̀pọ̀
Ile-ẹjọ pataki kan ti Ikeja niluu Eko dájọ́ pe gbajugbaja oṣere Olanrewaju James, ti a n pe ni Baba Ijesha jẹbí esun ifipa banilopo ọmọ ọdun merinla kan.
Adajo Oluwatoyin Taiwo, ninu idajo wakati meji lojo òní , da Baba Ijesha lebi fun iwa aisedede si omo kan, ilokulo ibalopo, ati igbidanwo ifipabanilopo ibalopo.
Adajo Taiwo ni awọn olupẹjọ fidi rẹ mulẹ pe lootọọ ni Baba Ijesha fi ipa ba ọmọdebinrin lopọ.
Odun 2021 ni igbẹjọ naa bẹrẹ lẹyin ti akẹgbẹ Baba ijesha, Princess wọ ọ lọ sile ẹjọ nitori pe ẹrọ ayaworan CCTV to wa ninu ile rẹ tu aṣiri bi Baba Ijesha ṣe n fi ọwọ riun ọmọdebinrin ti Princess jẹ alagbatọ fun lara ati ni kake gẹgẹ bi igbaradi lati baa ni ajọṣepọ.