Wo àwọn nǹkan tí kò ṣe é fẹnu sọ tó wáyé nínú ìjọ TB Joshua

    • Author, Charlie Northcott and Helen Spooner
    • Role, BBC News, Africa Eye

Ọpọ ẹri nípa eebu ati ifiyajẹni lati ọwọ Oludasilẹ ọkan lara ile ijọsin to tobi ju lagbaye ni iwadii ti BBC se yii tu asiri rẹ sita.

Ogunlọgọ awọn ọmọ ile ijọsin Synagogue Church of All Nations tẹlẹ rí - Ọmọ ilẹ Gẹẹsi marun un - fi awọn ẹsun bí ifipanilopọ ati fifi tipa tipa ṣẹ oyun kan Olusọ aguntan to ti di oloogbe TB Joshua lati orilẹ-ede Naijiria.

Ikilọ: Iwadiii yii ni awọn iroyin ifipabanilopọ, ifiyajẹni ati bẹẹ bẹẹ lọ

Awọn ẹsun eebu ati ifiyajẹni yii lo waye ni ọgba ikọkọ fun asiko to to ogun ọdun.

Ile ijọsin Synagogue Church of All Nations kọ lati fesi sì awọn ẹsun yii sugbọn salaye pe awọn ẹsun tẹlẹ ko ri ẹsẹ mọlẹ.

TB Joshua, ẹni to jade laye ni ọdun 2021, jẹ akinkanju, to jẹ oluwaasu to ṣe àṣeyọrí, to si ni awọn ọmọ ìjọ kaakiri agbaye.

Ohun tí Iwadii BBC to le ni ọdun meji safihan ni : Ohun tí awọn Osojumikoro to lugbadi eebu yìí lọwọ Joshua la kọja pẹlu itan fífi iya jẹ ọmọde ati dide awọn eeyan mọlẹ lati na wọn ní ẹgba.

Ọpọ awọn obinrin ti wọn ni Joshua fi tipatipa ba awọn ni ajọsepọ ni aimọye igba salaye pe ọpọ igba ni wọn fi ipa ba wọn lopọ fun ọpọlọpọ ọdun ninu ọgba naa.

Bakan naa ni ẹsun nípa fífi tipatipa yọ oyun sọnu ninu ile ijọsin naa lati ọwọ Joshua lẹyin ifipanilopọ ati pe obinrin kan sọ iriri rẹ pe igba marun un ọtọọtọ ni oun sẹ oyun

Iwadii wa lati ẹnu awọn ti ọrọ kan salaye bí Joshua ṣe n ṣe "ayederu isẹ ìyanu", eyi to n gbe sori afẹfẹ fun ọpọ milọnu eeyan kaakiri agbaye.

Ọkan lara awọn to la awọn nnkan yii kọja, ọmọ ilẹ Gẹẹsi ti orukọ rẹ n jẹ Rae, jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun nigba to fi ẹkọ fasiti rẹ silẹ ni Fasiti Brighton lọdun 2002, to si darapọ mọ Ile ijọsin naa.

O lo ọdun mejila gẹgẹ bii ọkan lara awọn ọmọ lẹyin Joshua tí wọn n pe ni "disciples" ninu ọgba rẹ nipinlẹ Eko.

"Gbogbo wa ro pe ọrun la wa sugbọn ninu ina ni a wa ati pe ninu ina ni nnkan buruku maa n waye," o sọ fun BBC.

Rae ni ọpọ igba ni Joshua fipa ba oun lopọ, ti wọn si ti oun mọ inu yara kan fun ọdun meji.

Eebu naa pọ, to si ni oun gbiyanju lati ṣekupa ara oun ni ọpọ igba ninu ọgba naa.

Wo ohun to yẹ ki o mọ nipa ile Ijosin TB Joshua

Ile ijọsin Synagogue Church of All Nations [Scoan] ni awọn alatilẹyin kaakiri agbaye, to si n se kookari ileeṣẹ amohun-maworan Kristẹni ti orukọ n jẹ Emmanuel TV ati ọpọlọpọ opo lori ayelujara ti awọn ọpọ eeyan sì n wo wọn.

Lasiko ọdun 1990s ati saaju ọdun 2000s, ọpọ awọn eeyan lati orilẹ-ede kaakiri ni Europe, America, Guusu Asia ati Africa lo maa n rìn irinajo mimọ wa si ile ijọsin lati wa wo bi Joshua ṣe n ṣe ìsẹ ìyanu ati iwosan.

O to alejo aadọjọ ni ye to ba Joshua gbe gẹgẹ ọmọ lẹyin rẹ ninu ọgba rẹ nípinlẹ Eko fun ọpọ ọdun.

Kini awọn ọmọleyin TB Joshua sọ fun BBC?

O le ni eeyan mẹdọgbọn to jẹ ọmọ ìjọ tẹlẹri to ba BBC sọrọ - lati UK, Nigeria, America, South Africa, Ghana, Namibia ati Germany - ti wọn si sọ awọn iriri wọn nínu ọgba ile ijọsin naa, to jẹ pe eyi to waye laipẹ ni ti ọdun 2019.

Pupọ awọn eeyan ti iṣẹlẹ yii sẹlẹ si lo wa ni ọmọ ogun ọdun nigba ti wọn darapọ mọ ile ijọsin rẹ.

Nípa awọn kan to wa lati ilẹ UK, Joshua lo san owo irinajo wọn wa si ipinlẹ Eko pẹlu ajọsepọ awọn ile ijọsin yooku ni UK

Rae ati awọn yooku ti a ba ni ifọrọwerọ sapejuwe iriri wọn gẹgẹ bii ti ẹgbẹ okunkun.

Jessica Kaimu, lati Namibia, salaye pe o le ni ọdun marun-un ti oun fi wa nibẹ.

O ni ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni oun nigba ti Joshua kọkọ fipa ba oun lopọ fun igba akọkọ, eyi to tẹsiwaju, to si fi tipatipa yọ oyun marun-un lara rẹ lasiko ti oun fi wa ni ibẹ.

"Wọn ní awọn nnkan ilẹkun ẹyin... awọn itọju tí wọn n fun wa... o le ṣekupa wa," o sọ fun BBC.

Kini awọn mii tun sọ nipa TB Joshua?

Awọn yooku to ba wa sọrọ ni wọn yoo ja awọn si ihoho, ti wọn yoo si maa fi waya ina fun wọn ní ẹgba, ti wọn ko si fun wọn ní anfani lati sun.

Irinajo iyalẹnu sinu eebu, iwa ipa ati ifiyajẹni lati ọwọ ọkan gboogi alagbara nípa ti ẹṣin, to jẹ ilumọóka ni eyi jẹ laye 21st century.

Ki o to ku lọdun 2001, TB Joshua jẹ ọkan lara ilumọọka wolii ninu itan Africa.

Ẹni to dìde lati inu talaka ati ailowo lọwọ, to si da ile ijọsin nla ti awọn eeyan bí oloṣelu, olorin, agbabọọlu ati awọn eeyan jankanjankan mii wa lara awọn eeyan to n wa si ile ijọsin rẹ.

Nigba aye rẹ, ọpọlọpọ awuyewuye lo waye paapaa nigba ti ile ìtura rẹ fun awọn to wa lati irinajo si ile ijọsin naa da wo ni ọdun 2014, ti eeyan to le ni ọgọrun un si padanu ẹmi wọn.

Iwadii BBC, to waye pẹlu International Media Platform Open Democracy jẹ igba akọkọ tí awọn olujọsin ile ijọsin yoo jade sita lati wa wi tẹnu wọn.

Wọn ní ọpọ igba ni awọn ti gbiyanju lati sọrọ sita sugbọn pabo lo maa n ja si.

Ọpọ awọn eeyan lati orilẹede Naijiria to wa lara awọn to lugbadi iṣẹlẹ naa ni awọn koju ọpọ idojukọ, paapaa tí iṣẹlẹ to waye ti wọn yinbọn fun eeyan kan nitori pe o fọhun nípa eebu ati ifiyajẹni to gbe sori ayelujara YouTube.

Ikọ BBC to gbinyanju lati ya fọnran ile ijọsin làti agbegbe kan ninu oṣu kẹta ọdun 2022 ni pe awọn to n sọ ile ijọsin sina bolẹ fun, to si wa ni ahamọ fun ọpọlọpọ wakati.

Kini alase ijọ Scoan sọ fun BBC?

BBC kan si ijọ Scoan fun awọn ẹsun wọnyi to wa ninu iwadii wa sugbọn wọn kọ lati sọrọ lori awọn ẹsun naa sugbọn wọn tako awọn ẹsun tẹlẹ nípa TB Joshua.

"Fífi ẹsun tí ko lẹsẹ nilẹ kan Wolli TB Joshua ko jẹ tuntun...

Ko si nnkan ninu awọn ẹsun wọnyi to ni ẹsẹ nílẹ," Wọn sọrọ.

Awọn mẹrin ninu awọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi to ba BBC sọrọ ni awọn fi awọn ẹsun yii to ìjọba Gẹẹsi leti lẹyin ti wọn sa asala kuro ni ile ijọsin naa.

Ṣugbọn awọn ijọba ko gbe igbesẹ kankan.

Ní afikun, ọmọ ilẹ Gẹẹsi kan ati iyawo rẹ fi atẹjisẹ gbogbo ohun ti awọn eeyan la kọja lọwọ Joshua sinu fọnran gẹgẹ bii ẹri ransẹ -

Paapaa fọnran ibi tí awọn eeyan ti wọn sapejuwe gẹgẹ bii Ọlọpaa tí awọn naa jẹ ọmọ ile ijọsin ṣe yọ ìbọn sì wọn ní Scoan- si aṣoju ijọba UK ni orilẹede Naijiria ni ọdun 2010 lẹyin ti wọn sa kuro ni ile ijọsin naa

Ninu atẹjisẹ rẹ, ọkùnrin naa salaye pe Joshua fipa ba iyawo oun lopọ ni ọpọ igba.

Ó si ṣe ikilọ fun ajọ aṣoju ìjọba UK pe awọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi míì wa ninu ọgba TB Joshua.

O ni wọn ko gbe igbesẹ kankan.

Ẹka ìjọba UK to n risi ọ̀rọ̀ oke okun kọ lati fesi si awọn ẹsun yii sugbọn wọn sọ fun BBC pe awọn maa mu ẹsun tí awọn eeyan mu wa lọkunkun dun paapaa ẹsun ifipanilopọ.

Ipa wo ni aya Oloogbe TB Joshua, Evelyn n ko bayii?

Scoan si n tẹsiwaju lati gbooro sì loni labẹ adari tuntun to jẹ iyawo T B Joshua, iyẹn arabinrinEvelyn.

Ní oṣu keje, ọdun 2023, o lewaju irinajo lọ si orilẹ-ede Spain.

Anneka, ẹni to kuro ni Derby ni UK lati darapọ mọ Scoan ni ẹni ọdun mẹtadinlogun, sọ fun BBC pe oun gbagbọ pe ọpọ awọn eeyan ni ko ti sọrọ sita lori ohun wọn la kọja lọwọ Joshua.

O lero pe awọn igbesẹ kan yoo waye lati tu asiri iwa TB Joshua síta.

"Mo gbagbọ pe o yẹ ki iwadii waye lori ile ijọsin Synagogue Church of All Nations lati mọ bí ọkùnrin naa ṣe n se awọn nnkan wọnyii fun ọjọ pipẹ," o salaye.

Ọpọ awọn ti BBC fi ọrọ wa lẹnu wo lo yọnda agbara wọn pe sugbọn awọn ko fẹ ki oju awón han sita ati pe ki a ma lo orukọ wọn gangan nitori ẹru.

Wọn gbagbọ pe TB Joshua kii ṣe eeyan lasan ninu itan wolii ile Adulawó ko to 'saa deede ku ni oṣu kéfa, ọdun 2021 ni kete lẹyin ti a gba akọsilẹ iṣe iwadii ifọtọwanilẹnuwo wa akọkọ lẹnu awọn omọlẹyin rẹ.

Esẹ ko gba ero lasiko ti wọn n sinku TB Joshua lati Eko titi de Arigidi ilu rẹ ni ero pupọ n daro wolii naa.

Bisola to jẹ ọmọ Naijiria ṣalaye nipa ọdun merinla to ṣe pẹlu rẹ ati bi awọn ijọ ilé okeere ṣe n ba TB Joshua ran awọn olujọsin sii ki o to maa gba owo sii lẹyin ti ijọ rẹ di nla.

O ni pe awọn alawọ funfun ni TB Joshua fi n ta ọja rẹ

Bisola ṣalaye pe oun ni oun maa n ba TB Joshua wa ọmọge gẹgẹ bii ọmọleyin tootọ.

O ni pe awọn ti ko tii mọ ọkunrin ri ni oun si maa n baa wa julọ ti ọpọ awọn ómoge naa koi tii pe ẹni ọdun mejidinlogun, eyi to le ja si iku labẹ ofin Naijiria.

Ki wọn mu wọ agbo igbala fun igbadun wolii. Oun naa sọ pe ọpọ igab ni TB Joshua ti fi ipa ba oun lo pọ

Elomii, Agomoh Paul sọ pé o jẹ ọkan apataki lara awọn ọmọlẹyin TB Joshua to yapa kuro lẹyin rẹ lẹyin ọdun mẹwaa.

Agomah ni pe : Eto ati igbiyanju ógbón ni ọgbọn agba ni gbogbo rẹ

O ni pe ọpọ igba ni awọn n sanwo fun awón eeyan lati dọgbọn si iṣẹ iyanu ti wọn n ṣe nibẹ.

Ati pe igba mii awọn a fun awon alaisan ni oogun oloro tabi oogun to maa mu ilera ba won nipa aisan wọn ṣugbọn ti wọn ko ni mọ rara.

A maa awa sọ pe ki wọn wa jẹri nipa iṣẹ iyanu ti Oluwa ṣe fun wọn

Maggie Anderson, Yemisi Adegoke ati Ines Ward lo ṣe afikun iwadii.

Fun Iranlọwọ ati iroyin nípa fífi tipatipa ba ni lopọ, ẹ dakun ẹ kan BBC Actionline ni UK.

Fun iroyin nípa ẹgbẹ okunkun, ẹ kan si The Family Survival Trust.