Àwọn kan gbọ̀nà ẹ̀bùrú jáwọ ojú òpó X tí wọ́n ń pè ní "Twitter" tẹ́lẹ̀ láti fa ojú Musk mọ́ra

Agbarijọpọ awọn agbọnaẹburu wọ oju opo ayelujara ti oloyinbo n pe ni ‘hacker’ kan ti ja oju opo X ti wọn n pe ni Twitter tẹlẹ balẹ lawọn orilẹede to ju mejila lọ lọjọ Iṣẹgun lona ati tubọ mu ki Elon Musk da ileeṣẹ ibanisọrọ Starlink silẹ lorilẹede wọn.
Awọn agbọnaẹburu wọ oju opo ayelujara ti oloyinbo n pe ni ‘hacker’ naa ti wọn pe orukọ ara wọn ni ‘Annonymous Sudan’ fi si oju opo Telegram wọn pe awọn n fẹ ki Elon Musk ṣi “Starlink lorilẹede Sudan”.
Fun wakati meji ni oju opo X ko fi ṣiṣẹ, ti ọpọlọpọ awọn eeyan to n lo o lawọn orilẹede tọrọ kan ko si lee rii lo.
Ọkan lara awon agbọnaẹburu wọ oju opo ayelujara ti oloyinbo n pe ni ‘hacker’ naa to pe ara rẹ ni Crush ṣalaye fun BBC lọjọ Iṣẹgun pe awọn fi ọpọ atẹranṣẹ soju opo naa lati jaa balẹ.

Oju opo Downdetector to n tọpinpi awọn ajideta sọ pe o le ni ẹgbẹrun lọna igba iroyin ti wọn gba lati ọdọ awọn eeyan to n lo oju opo X lorilẹede Amerika ati ilé Gẹẹsi.
Ẹgbẹ awọn agbọnaẹburu wọ oju opo ayelujara ti oloyinbo n pe ni ‘hacker’ miran to pe ara rẹ ni Hofa sọ pe awọn n fi irufẹ ikọlu bayii pe akiyesi si ogun abẹle to n waye ni Sudan ni.
X ko tii sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ ikọlu oju opo rẹ yii.
Itẹdo wọn ni Sudan

Awọn kan ti fi ẹsun kan ẹgbẹ naa pe ikọ agbofinro imọẹrọ ayelujara ti ileeṣẹ ọmọ ogun Russia ni wọn, ati pe wọn kan n fi orukọ ilẹ okeere boju lati da wahala silẹ fun idunnu awon alaṣẹ ijọba Russia.
Awọn to n sọ eyi ko sai sọ bẹẹ tori atilẹyin ti ẹgbẹ awọn agbọnaẹburu wọ oju opo ayelujara ti oloyinbo n pe ni ‘hacker’ n ṣe fun ijọba Russia lori oju opo ayelujara wọn.
Crush salaye pe Sudan lawọn wa ati pe irọ leyii, koda Crush ati Hofa fi aworan iwe irinna silẹ okeere won han to fihan pe ọmọ orilẹede Sudan ni won












