You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àmì àrùn jẹjẹrẹ mẹ́wàá tí èèyàn le è tètè sé àkíyèsí nínú ara
Bi ọpọ eeyan ba gbọ aarun jẹjẹrẹ, ohun to maa n wa sọkan wọn ni pe ẹnikẹni to ba lugbadi arun naa ti gba ọjọ iku ni.
Amọ lati bii ọdun 1970 lawọn to ni arun jẹjẹrẹ to ba tete mọ ti n ri iwosan.
Koda oniruuru arun jẹjẹrẹ lo ti gboogun bayii papaa ti awọn to ba larun naa ba tete mọ.
Fun apẹẹrẹ, iwadii kan ti ajọ to n ri si ọrọ ati gbogun ti arun jẹjẹrẹ ni UK sọ pe o le ni idaji awọn eeyan ilẹ Gẹẹsi ti wọn ti ṣakiyesi ami arun jẹjẹrẹ nigba kan tabi omiiran.
Ṣugbọn ida kan meji pere ninu ọgọrun lo gbagbọ pe awọn le ni arun jẹjẹrẹ nigba ti idakan ninu ida mẹta kọ eti ikun si awọn ami arun naa ti wọn ko si bikita lati lọ si ile iwosan.
Akọroyin BBC ṣalaye ami arun jẹjẹrẹ mẹwaa ti eeyan ni lati ṣakiyesi gẹgẹ bi ajọ to n ri si ọrọ arun jẹjẹrẹ ṣe sọ.
Ami jẹjẹrẹ mẹwa to le foju han ninu agọ ara
Ki eeyan maa ru
Ọpọ eeyan to ba ni arun jẹjẹrẹ lo maa n ru nigba kan tabi omiiran.
Nigba ti eeyan ba ṣa deedee ru lai ro tẹlẹ, iru ohun to saaba maa n ṣẹlẹ niyii.
Ti eeyan ba ru pẹlu iwọn kilo marun un le jẹ ami arun jẹjẹrẹ.
Eleyii maa n saaba ṣẹlẹ pẹlu arun jẹjẹrẹ inu, ọna ọfun tabi arun jẹjẹrẹ fuku.
Arun Iba
Arun iba jẹ ọkan lara awọn arun to wọpọ to maa n ṣe awọn to ba ni jẹjẹrẹ.
Eleyii maa n saaba ṣẹlẹ ti arun yii ba ti tan kaakiri lati ibi to ti bẹrẹ.
Gbogbo eeyan to ba ni arun jẹjẹrẹ lo maa n ni iba papaa julọ ti arun jẹjẹrẹ ba ti n ṣakoba fun awọn sọja to wa ninu ẹjẹ.
Iba le jẹ ami pe eeyan ti lugbadi arun jẹjẹ papaa julọ arun jẹjẹrẹ inu ẹjẹ.
Ki o maa rẹ eeyan
Ki o maa rẹ eeyan ni gbogbo igba wa lara awọn ami arun jẹjẹrẹ.
Koda ki eeyan sinmi ko ni ki rirẹ yii lọ to ba jẹ ẹni naa ti larun jẹjẹrẹ.
Rirẹ eeyan lẹ ami pe arun jẹjẹrẹ ti n gbilẹ sii ni ara ẹni naa.
Awọn to ba ni arun jẹjẹrẹ inu ẹjẹ maa n saaba ni iriri yii ti wọn ba ṣẹṣẹ lugbadi arun naa.
Ki iyatọ ba awọ ara
Arun jẹjẹrẹ awọ ara atawọn irufẹ arun jẹjẹrẹ mii naa maa n jẹ ki awọ eeyan yipada.
Iru rẹ lo maa n jẹ ki awọn eyan to ba pupa di dudu.
Awọ ara eeyan to ba dudu yoo di olomi ọsan, ẹni naa si tun le ni ọka.
Awọ ara eeyan tun le maa pupa.
Ara yunyun ati ki irun eeyan maa tete kun naa wa lara ami yii.
Ki iyatọ ba iye igba t’eeyan n lọ si tọlẹẹti
Iyatọ maa n ba iye igba ti eeyan n lo tọlẹẹti lati yagbẹ tabi lati lọ tọ.
Inu ẹlomiiran maa n kun, iyatọ tun maa n de ba iwọ igbẹ ti ẹni naa ba ya.
Ki oju ara maa dun eeyan to ba fẹ tọ, tabi ki ẹjẹ maa jade ti eeyan ba ntọ le jẹ ami arun jẹjẹrẹ apola tabi koropọn.
Egbo ti ko san
Oju egbo to ba wa lara eeyan to kọ ti ko san le jẹ ami arun jẹjẹrẹ.
Eeyan ni lati ṣakiyesi egbo to wa lara ti ko si san lẹyin bi ọsẹ mẹrin.
Egbo to ba wa lẹnu ti ko lọ le jẹ ami arun jẹjẹrẹ ẹnu.
O yẹ ki eeyan tete lọ fun ayẹwo nile iwosan ti o ba ti ṣe akiyesi iyatọ kankan lẹnu.
Egbo to ba wa loju ara le jẹ ami arun jẹjẹrẹ to ṣẹṣẹ bẹrẹ.
Iru eeyan bẹẹ ni lati lọ ri dọkita ni kiakia.
Ki ara maa ṣẹjẹ
Ara ẹni to ba ṣẹṣẹ ni arun jẹjẹrẹ le kan maa ṣadeedee ṣẹjẹ.
Ti eeyan ba n wukọ ẹjẹ le jẹ ami arun jẹjẹrẹ fuku.
Ti eeyan ba n ri ẹjẹ ninu igbẹ naa le jẹ ami arun jẹjẹ inu.
Arun jẹjẹrẹ oju ara obinrin naa le jẹ ki ẹjẹ maa jade lati oju ara.
Ẹjẹ ninu itọ naa le jẹ ami arun jẹjẹrẹ kindinrin tabi apola.
Ti ẹjẹ ba n jade lori ọmu le jẹ ami arun jẹjẹrẹ ọmu.
Ki koko wa kaakiri ara
Ti koko ba n wa kaakiri lara eeyan le jẹ ami arun jẹjẹrẹ.
Koko ni gbogbo ara saaba maa n jẹ ami arun jẹjẹrẹ ọmu, koropọn tabi arun jẹjẹrẹ ọna ọfun.
Koko tabi ki ara ṣadeedee maa le jẹ ami arun jẹjẹrẹ to ṣẹṣẹ bẹrẹ.
Inira lati gbe ounjẹ mi
Ti ounjẹ ko ba da ninu eeyan tabi ti eeyan ba n ni inira lati gbe ounjẹ mi le jẹ ami arun jẹjẹrẹ ọna ọfun tabi ikun.
Amọ, gẹgẹ bi ọpọ ami mii, o tun le ma jẹ ami arun jẹjẹrẹ.
Ti eeyan ba n wu ikọ lera lera tabi ki ohun eeyan ha
Ti eeyan ba n wu ikọ lera lera le jẹ ami arun jẹjẹrẹ fuku.
O ṣe pataki ki ẹnikẹni to ba n wu ikọ to ba ti ju ọsẹ mẹta lọ kan si ile iwosan fun ayẹwo.
Ẹwẹ, ohun hiha le jẹ ami arun jẹjẹrẹ ọna ọfun