Láàrin ọdún kan, àyípadà ńlá yóò wáyé ní Nàìjíríà - Shettima

Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Kashim Shettima ti sọ pe ayipada gidi yoo de ba orilẹede Naijiria laarin oṣu mẹsan an si ọdun kan isẹjọba Aarẹ Bola Ahmed Tinubu.

Shettima ṣo eyi di mimọ niluu St Petersburg lasiko to n se ipade pọ pẹlu awọn ọmọ orilẹede Naijiria to n gbe ni Russia.

O wa fi awọn ọmọ Naijria lọkan balẹ, paapa awọn to n gbe ni Russia pe isẹjọba Tinubu yoo se isẹ takuntakun lati mu orilẹede Naijiria tẹsiwaju.

"Mo n fi dayin loju pe laarin oṣu mẹsan si ọdun kan, iyatọ nla yoo waye lorilẹede Naijiria.

"Mo n sọ eleyi nitori mo gbagbọ ninu isẹjọba Aarẹ Tinubu."

Shettima ni ijọba to wa lode bayii n sa apa rẹ lati mu ayipada nla ba ọrọ ajẹ, eyi to ni yoo fun awọn ileeṣẹ olokun lati wa si orilẹede Naijria.

Bakan Igbakeji aarẹ ni oun lero lati pese eto ẹko fun awọn Naijria toto milọnu kan lori Ayelujara.