You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ni Ààrẹ Tinubu, Peter Obi àti Kayode Fayemi bá ara wọn sọ nígbà tí wọ́n pàdé nibi ayẹyẹ Poopu ni Rome?
Ni ana ọjọ Aiku, ọjọ kejidinlogun oṣu Karun-un ọdun 2025, Aarẹ Bola Tinubu, Peter Obi to dupo aarẹ ninu ẹgbẹ Labour ati gomina Ekiti tẹlẹ, Kayode Fayemi; pade niluu Rome, nibi ayẹyẹ ifinijoye Poopu Leo XIV.
Iroyin sọ pe bi Fayemi ṣe ri Aarẹ nibi to jokoo si pẹlu awọn olori orilẹede mi-in, o sọ fun Peter Obi pe ko jẹ k'awọn lọọ fi ọla fun ẹni to tọ si, kawọn lọọ ki aarẹ Naijiria.
Fayemi lo kọkọ sọrọ bi wọn ṣe debẹ, o ni: "Aarẹ, ẹ kaabọ si ṣọọṣi wa, ẹ si ṣeun ti ẹ waa pọn Poopu naa le."
"Emi lo yẹ ki n maa ki iwọ ati Peter kaabọ. Emi ni olori ikọ̀ Naijiria".
Bẹẹ ni Aarẹ Tinubu fesi ti awọn eeyan n gbe kiri pe o fi ajulọ han Obi ati Fayemi.
Ṣugbọn niṣe lawọn mejeeji bu sẹrin, wọn gba pe bo ṣe ri gan-an ni aarẹ sọ.
Nigba to n da Tinubu loun, obi sọ pe: "Bẹẹ ni o, ara ikọ̀ yin ni awa naa".
Gẹgẹ bi a ṣe mọ, ọmọ ijọ Aguda pọnbele ni Peter Obi ati Kayode Fayemi, wọn si joye pataki ninu ijọ Katoliiki naa.